Wo ọ̀nà mẹ́ta tí o lè gbà láti dènà sísọ ìjíròrò di àríyànjiyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Jessica Robles
- Role, The Conversation*
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní a rẹ́ má jà kan kò sí láyé àti pé ahọ́n àti eyín, bí wọ́n ṣe súnmọ̀ ara wọn tó, wọ́n máa ń jà.
Àdámọ́ ẹ̀dá ni láti ní ìfaǹfà, gbogbo wa kò rí bákan náà.
Bó ṣe jẹ́ pé a lè mú àríyànjiyàn ní ohun ẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ló lè di ohun tó le di ìjà ńlá bí a kò fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ara wa lò.
Ìfaǹfà sábà máa ń wáyé lọ́pọ̀ ìgbà tí èèyàn jọ ń wà pọ̀ fún ìgbà pípẹ́ tó sì jẹ́ pé onírúurú nǹkan ló lè ṣokùnfà rẹ̀. Ó le jẹ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú, ìgbé ayé tàbí nǹkan tí èèyàn bá rí lórí ayélujára.
Tí èèyàn bá sì ṣe fojú wo nǹkan ni ó ṣeéṣe kí ìfaǹfà wáyé lórí rẹ̀ sí.
Àwọn nǹkan wo ni èèyàn lè ṣe láti dènà sísọ ìjíròrò di ohun tó le dìjà mọ́ èèyàn lọ́wọ́ yálà lórí tàbí ojú ayé gangan.
Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lórí ayélujára, mo ní ìgbàgbọ́ pé ó ṣe pàtàkì láti kíyèsí ọ̀rọ̀ tí a bá ń sọ fún ẹnìkẹnì àtàwọn ọ̀nà tí à ń gbà sọ wọ́n àti láti yàgò fún àwọn èsì tó lè fa wàhálà.
Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé lára ìgbé ayé náà ni ìfaǹfà àti àìgbọ́raẹniyé wà.
Àwọn nǹkan mẹ́ta tó le dènà sísọ ọ̀rọ̀ kékeré di ohun ńlá:
1. Ṣe àmójútó ríru ọkàn sókè
Tí o ò bá gbàgbọ́ nínú nǹkan tí èèyàn kan bá sọ, má gbìyànjú láti bú èébú tàbí fi ẹ̀sùn kan onítọ̀hún. Jìnà sí fífi ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí sọ̀rọ̀ tó le bí ọnítọ̀hún nínú.
A máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ọ̀rọ̀ bá dá lé lórí àti pàápàá ohun tí ẹni tí tó ń sọ̀rọ̀ ń rò lọ́kàn.
Kí ni ó dá lé lórí? Ṣé àìgbọ́raẹniyé lásán ni àbí ìkùnsínú? Àbí èrò kan wà lábẹ́ tí a kò mọ̀ sí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A máa ń fi pàtàkì sí bóyá èèyàn kan ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n ń sọ. Ìwádìí ti ṣàfihàn rẹ̀ pé ó máa ń jẹ́ ohun ìkọnilóminù fún èèyàn nígbà tí èèyàn kan bá ń hùwà bíi "ìránṣẹ́ èṣù" nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan.
Ṣùgbọ́n ó ṣòro láti lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹlòmíràn nítorí náà, ohun tó dára ni yàgò fún ríronú nípa ohun tó burú tí wọ́n lè ṣe.
Bíbẹ́ẹ̀kọ́, ó ṣeéṣe kí èèyàn sọ̀rọ̀ òdì bíi pé ẹni náà le ṣe èèyàn ní ìjàmbá
2. Ṣí ọkàn rẹ sílẹ̀
Nígbà mìíràn, ohun tí èèyàn kan bá sọ le jọ́ pé kò dára rárá. Tí irúfẹ́ èyí bá ṣẹlẹ̀, nǹkan méjì ni èèyàn lè ṣe.
Àkọ́kọ́, kò sí ọ̀rọ̀ tí èèyàn sọ tó ní ìtumọ̀ kan. A lè tú ọ̀rọ̀ sí ọ̀nà tó pọ̀ àti pé kò yẹ láti gbàgbọ́ nínú ìtumọ̀ tó bá kọ́kọ́ wá sí orí ẹni nígbà tí èèyàn bá wà nínú ìbínú lọ́wọ́.
Lásìkò tí ìjíròrò bá ń lọ lọ́wọ́, ó dára láti dákẹ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi ronú nípa àwọn ìtumọ̀ míì tí a lè fún àwọn ọ̀rọ̀ tó ń jáde. O lè bèèrè fún àkókò díẹ̀ láti ronú tàbí jáde kúrò láti ṣe nǹkan tó le gbé ìrònú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn díẹ̀.
Ìkejì, tí nǹkan tí èèyàn bá sọ bá ṣì ń jọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹni lẹ́yìn gbogbo ìgbìyàjú láti gbe kúrò lọ́kàn tàbí má kà á kún, ó dára láti sọ fún onítọ̀hún pé kó ṣàlàyé ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.
Ó ṣeéṣe kí èyí má rọrùn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fìdí ohun tí wọ́n bá ń sọ múlẹ̀ nígbà tí ẹ bá ní kí wọ́n ṣàlàyé.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Kọjú mọ́ ohun tó ṣe pàtàkì
Ọ̀nà méjì ni èyí pín sí: ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí èèyàn fẹ́ sọ dáadáa àti ríronú nípa bí o ṣe fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà rí.
Kò sí ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ṣàbámọ̀ lórí rẹ̀ lẹ́yìn àríyànjiyàn tó fi mọ́ ìwọ náà.
Ohun tí wọ́n ń pè ní "Metacommunication" – dídúrò láàárín ìjíròrò láti sọ̀rọ̀ nípa ìjíròrò náà àti ọ̀nà tí ìjíròrò náà ń gbà wáyé – nílò ìgbéléwọ̀n tó gbégẹ.
Tí o bá pinnu láti kojú ọ̀nà tí ìjíròrò ń gbà wáyé, ó lè ṣe pàtàkì láti tọrọ àforíjì tàbí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn ìrẹ̀lẹ̀ lójúnà àti dènà kí ẹnìkejì má ba à rò pé ò ń fi ẹ̀sùn kan òun pé òun sọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò tọ́.
Ó ṣòro díẹ̀ nítorí náà má bara jẹ́ tí o kò bá ri ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́.
Ṣé a ní àfojúsùn kan náà?
Èèyàn kìí kàn jiyàn lásá. Lára àwọn ìdí tí àríyànjiyàn fi máa ń wáyé ni láti ṣàfihàn ara ẹni sí ẹlòmíràn. Ṣé nǹkan kan náà ni a jọ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ àti pé kí làwọn ìjọra tí a ní?
Ìjíròrò máa sọ irú èèyàn tí èèyàn jẹ́. A mọ̀ pé ó ṣeéṣe kí wọ́n fi irú ọ̀rọ̀ tó bá ń jáde lẹ́nu ẹni láti máa fi wo irú èèyàn tí a jẹ́, tí a sì rò pé bẹ́ẹ̀ náà láwọn èèyàn ṣe ń rò pé à ń rí àwọn náà.
Èyí le bí ìfaǹfà kódà láì ṣe nígbà tí ìjíròrò bá ń wáyé nìkan ṣùgbọ́n nípa ìbáṣepọ̀ bákan náà.
Irú àwọn èèyàn tó máa ń fẹ́ láti dènà nǹkan báyìí máa ń rò ó pé gbígbé ìmọ̀lára wọn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti kojú òótọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí èyí.
*Jessica Robles jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ social psychology ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Loughborough University.
Lójú òpó ìtàkùn àgbáyé ilé ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n kọ́kọ́ fi àkọ́ọ́lẹ̀ yìí sí tí The Conversation àti àdàkọ rẹ̀ tí a ṣe yìí wà lábẹ́ Creative Commons license.












