El-Rufai bèèrè ₦1bn lọ́wọ́ ICPC nílé ẹjọ́, DSS ní àfi kó fojú ba ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ana nipinlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai, ti gbe ẹjọ to n le ₦1bn kalẹ eyi to pe tako ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ ICPC ati awọn ẹka ijọba mii pe wọn ja wọ ile rẹ niluu Abuja lai ni ojulowo aṣẹ lati ile ẹjọ.
El-Rufai, pẹlu awọn agbejọro rẹ gbe ẹjọ naa kalẹ pẹlu nọmba idanimọ FHC/ABJ/CS/345/2026 niwaju ile ẹjọ giga niluu Abuja.
Agbẹjọro El-Rufai, Oluwole Iyamu lo lewaju fun ẹjọ, ti wọn kede pe awọn n wọ ajọ ICPC, adajọ agba Magistrate, ile ẹjọ Maistrate, Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria ati awọn mii.
El-Rufai ni ki ile ẹjọ beere lọwọ awọn eeyan pe iwe aṣẹ wo ni wọn gba, to fun wọn ni aṣẹ lati wa tu ile rẹ ni to wa nu Aso Drive, niluu Abuja lọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun 2026.
El-Rufai ni ki ile ẹjọ wọgile ayederu iwe aṣẹ ti wọn mu wa lati wat u ile oun ni Aso Drive ni ago meji ọsan ni ọjọ kọkandinlogun oṣu Keji ọdun 2026.
O tẹsiwaju pe igbesẹ ajọ ICPC ati ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lo jẹ eyi to lodi di ofin ọmọ niyan labẹ iwe ofin orilẹede Naijiria.
Ninu iwe ẹjọ tun kọ, El-Rufai fẹsun kan ajọ ICPC pe wọn ko awọn ẹru oun, to fi awọn iwe, ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ti wọn ko si ti da pada.
El Rufai ni ki ile ẹjọ palaṣẹ fun olujẹjọ akọkọ ati ikẹta(ICPC ati IG) pe ki wọn da awọn dukia rẹ pada.
Bakan naa lo tun ni ki ile ẹjọ pasẹ pe awọn olujẹjọ san owo toto Bilọnu kan naira fun titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ, mimu dukia, dida alaafia ru ati awọn ẹsun mii.
Lọsẹ to kọja ni Malam Nasir El-Rufai dero ahamọ ajọ ICPC lẹyin to kuro ni atimọle ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu lanaa Ọjọru ọjọ kejidinlogun oṣu Keji yii.
Bakan naa ni ajọ DSS tun fẹsun iwa ọdaran kan gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ lori wi pe o tọwọ bọ foonu oludamọran aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu lọna aitọ.
Nigba to ya ni ajọ ICPC kede wi pe El-Rufai ti wa ni ahamọ awọn.
Ibẹrẹ oṣu yii ni ede-aid-yede bẹ silẹ ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe l'Abuja nigba ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo fẹ fọwọ ofin mu El-Rufai.
Lẹyin naa ni gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lori tẹlifisan Arise wi pe Ridadu lo ni ki ajọ DSS mu oun ni papakọ ofurufu l'Abuja.


























