Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí obìnrin tó ní ọkùnrin kan fipá bá òun lò pọ̀ nítorí òun kọ̀ láti fẹ́ ẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Pẹlu omije loju ati ibẹru ọkan ni arabinrin kan to pe orukọ rẹ ni Mirabel fi ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nigba ti ọkunrin ojoji kan wa ka mọle, to si fipa ba lopọ.

Ninu fidio kan ti Mirabel gbe sori ayelujara Tiktok, o ṣalaye pẹlu omije, to si ni iṣẹlẹ ọhun waye ni ọjọ Kẹdogun oṣu Keji ọdun 2025.

O tẹsiwaju pe iṣẹlẹ ọhun ti fa ọpọ aisan si ago ara rẹ, ti oun si nilo lati mu ọti tabi lo oogun ko to le ri orun ṣun.

Mirabel ni owurọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ko ko ko ni ẹnu ọna oun lo ji oun , ti oun si ro pe awọn ti awọn jọ n gbe papọ ni.

O ni ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti oun ri pe ojoji ni eeyan naa, to si fi tipatipa ja ilẹkun wọ ile oun.

Mirabel ni oun dakun nigba ti arakunrin naa ti oun ṣubu, to si jẹ pe nigba to pada laju, ọkunrin naa wa ni ọna lati fipa ba oun lopọ.

O ni lẹyin iṣẹlẹ naa ni ẹjẹ bẹrẹ si ni ya sita ni ara oun, ti oun si kọkọ ro pe nnkan oṣu lo de.

Ọdọmọbinrin ni oun gba atẹjisẹ kan lati ori opo ayelujara Instagram pẹlu orukọ kan to n jẹ "Priston".

Priston yii lo ni o jẹwọ pe oun lo fipa ba lopọ nitori o gbiyanju lati bẹ ọdọmọbirin naa ni ọpọ igba ṣugbọn o kọ jalẹ, eyi lo si fa a to fi gbe igbesẹ naa.

Afurasi ni Mirable tun sọ pe o sọrọ pẹlu igboya pe oun wa lati idile olowo, ti oun si le dabaru iwadii ileeṣẹ ọlọpaa.

Mirabel tun gbe fọnran mii sita nibi to ti ṣalaye pe oun gbinyaju lati gba ẹmi ara oun pẹlu majele.

O ni ọrẹ oun kan lo doola ẹmi oun, to si gbe oun lọ si ile iwosan.

"O rẹmi, n ko fesi si atẹjisẹ. Mo ma fesi nigba ti ara mi ba ya , mo dupẹ," o kọ sita.

Fidio yii lo ti lọ kaakiri oju opo ayelujara, ti ọpọ si ti kan awọn ileeṣẹ ọlọpaa lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

N jẹ iwadii ti bẹrẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ọrọ rẹ to gbe soju opo ayelujara X, ẹka to n gbe ogun ti iwa ipa nipinlẹ Eko, Lagos DSVA, ni awọn ti bẹrẹ iwadii naa, ti wọn si ti n gbiyanju lati ṣawari ọdọmọbinrin naa.

"Ẹka Lagos DSVA ti ri gbogbo atẹjisẹ yin nipa fidio ọdọmọbinrin to n lọ kaakiri lori ayelujara nipa fifi ipa banilopọ.

"Ti ẹnikẹni ba iroyin to le ran wa lọwọ nipa riri obinrin naa, ko kan si wa loju opo ayelujara wa."

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abimbola Adebisi, ninu ọrọ to gbe sita ni oun ri anfani lati ba ẹni to wa pẹlu ọdọmọbinrin naa sọrọ.

Adebisi ni agbegbe kan nipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti waye, ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun si ṣetan lati tẹsiwaju ninu iwadii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Oluseyi Babaseyi ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ba ọdọmọbinrin naa sọrọ, ti Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa ti si palaṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni kiakia.

Ọpọ eeyan loju opo ayelujara lo bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ naa, paapa awọn gbajumọ ni awujọ.

Simisola Kosoko, olorin takasufe ni ẹnikẹni ti wọn ba mu pe n fipa ba obinrin lopọ lo yẹ ki wọn dana sun lẹsẹkẹsẹ.

"Eyi ti sumi. Ẹ ye fipa ba obinrin lopọ. A ni lati ma fọ koropọn, ka si tun dana sun ẹnik]eni to ba fipa ba eeyan lopọ."