Ìbẹ̀rùbojo àti ìpayà ni àdó olóró Trump tó ṣèṣì balẹ̀ sínú Offa kó sí wa lọ́kàn - Aráàlú

Àkọlé fídíò, Ìbẹ̀rùbojo àti ìpayà ni àdó olóró Trump tó ṣèṣì balẹ̀ sínú Offa kó sí wa lọ́kàn - Aráàlú
Ìbẹ̀rùbojo àti ìpayà ni àdó olóró Trump tó ṣèṣì balẹ̀ sínú Offa kó sí wa lọ́kàn - Aráàlú

Ni oṣu kejila ọdun 2025 ni ibugbamu kan gbilẹ ni agbegbe Offa nipinlẹ Kwara.

Ibugbamu yii wa lo waye lati ọwọ ijọba Amẹrika lati gbe ogun ti awọn agbesunami to n da eto alaafia ilu laamu.

Ilu Babanla ti ijinigbe ti peleke ni agbegbe naa ni ado naa n lọ ko to sina balẹ̀ silu Offa.

Ṣugbọn bi ọpọ ṣe kan sara si igbesẹ ijọba Amẹrika ni awọn araalu kerora lori bi ibugbamu naa ṣeeṣe akoba fun okoowo ati gbingbin ibẹrubojo si ọkan wọn.

BBC ba awọn araalu sọ lori akoba ti ibugbamu naa ṣe fun wọn,

Suraj Bello, Alamojuto Ile Itura ni ọpọ awọn onibaara wọn ni ko wa mọ nitori ibẹru pe o ṣeeṣe ki ibugbamu mii tun waye.

"Fun apẹẹrẹ, ẹni to wa ninu yara lọjọ yẹn ti kini ọhun waye, dajudaju wọn ko ni wa mọ, nitori wọn ko mọ boya ijọba mọmọ ni."

Emmanuel Okasabo ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lasiko ibugbamu naa.

"Mo kan gbọ pe kini kan ṣe gbi. O jabọ silẹ, o ba mi gan to jẹ pe mo daku, ile iwosan ni mo ti ba ara mi.

"Ẹyin ga ẹ wo ori mi nsinyi, ori yẹn o n yọ mi lẹnu di isinyi.

"Ti nnkan ba ṣe gbi bayii, ori yẹni bi i pe o fẹ ge jabọ lo ṣe ma n ṣe mi."

Aworan wọn araalu Offa

Oríṣun àwòrán, Others