Ọba Ido-Osun pàṣe kí wọ́n ti ilé ìjọsìn tí pásítọ̀ rẹ̀ lọ gbàdúrà lójúbọ Osun Osogbo pa

Àkọlé fídíò, Osun osogbo
Ọba Ido-Osun pàṣe kí wọ́n ti ilé ìjọsìn tí pásítọ̀ rẹ̀ lọ gbàdúrà lójúbọ Osun Osogbo pa

Ọba Olayinka Isola, to jẹ Olojudo ti ilu Ido-Osun, ti paṣẹ ki wọn ti ile ijọsin God of White Calling for all Souls Ministries to wa niluu naa pa titi ti iwadii yoo fi pari lori rẹ.

Ọba Isola lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

Ti ẹ ko ba gbagbe, pasitọ ilẹ ijọsin naa lo lọ si ojubọ Osun Osogbo lati lọ gbadura nibi to ti ni oun n le ẹmi inu oriṣa rẹ jade.

Kabiesi naa sọ pe ile ijọsin ọhun yoo wa ni titi pa titi ti ijoba yoo fi pari iwadii lori ohun ti pasitọ ọhun ati awọn ọmọlẹyin rẹ lọ ṣe ni ojubọ naa.

O ni awọn oniṣẹṣe, Musulumi ati ọmọlẹyin Kristi lo n gbe ni alaafia ninu ilu naa lai si ija kankan laarin wọn titi di asiko yii.

Ati pe ilu ọhun ko ni la oju rẹ silẹ ki pasitọ naa atawọn bii tirẹ da wahala ija ẹsin silẹ nibẹ.

O ni "Ẹnikankan ko gbọdọ lọ jọsin ninu ile ijọsin naa mọ.

"To ba ti lọ da ijọba lohun, to ba da aafin lohun, taa gbọ tẹnu rẹ, o ṣeeṣe ki ipinnu wa yi pada, ṣugbọn lọwọ lọwọ ti mo n sọrọ yii, ẹnikankan ko le jọsin ninu ile ijọsin naa."

Pásítọ̀ ní ìrìnàjò afẹ́ làwọn bá lọ sódò Osun, ẹ̀jẹ̀ adiyẹ tí wọ́n rí lójúbọ níbẹ̀ ló mú wọn gbàdúrà níbẹ̀, èyí tí Bàbá Ọ̀ṣun ní ó lè fa ìjà ẹ̀sìn

Lọṣẹ to kọja ni fidio kan bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara ninu eyii ti awọn ẹlẹsin abalaye kan ti lọ bẹ ori aja sinu ilu ijọsin alasọ funfun kan.

Wọn ni awọn ṣe bẹẹ lẹyin ti pasitọ ijọ naa kọkọ lọ si ojubọ Osun Osogbo lati gbadura sibẹ to si ni oun fẹ le ẹmi Eṣu to wa nibẹ kuro.

BBC Yoruba tẹkọ leti lọ ipinlẹ Osun lati ba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan sọrọ.

Ijọba lo ni ojubọ Osun Osogbo, ko wa fun ẹsin kan ṣoso – Pasitọ

Nigba ti pasitọ Odedoyin Ezekiel, to jẹ adari ijọ God of White Calling for all Souls Ministries niluu Ido Osun, ni ijọba ibilẹ Egbedore n ba BBC sọrọ, o ni kii ṣe aṣiṣẹ lawọn ọmọ ijọ oun fi lọ sibẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba lo ni ojubọ naa, o si jẹ ibudo igbafẹ ti gbogbo araalu le yọju si.

O ṣalaye pe irinajo afẹ lawọn ba lọ sibẹ, koda ra tikẹẹti owo iwọle ki wọn to ri ibikan ti awọn kan bẹ adiyẹ si, ti wọn si ta ẹjẹ rẹ sibẹ.

O ni aworan adiyẹ ti wọn ta ẹjẹ rẹ siẹ naa loun ri ti oun fi gbadura si ojubọ ọhun gẹgẹ bii ẹni ẹmi lati re ibi yoowu ti wọn ba ṣe sibẹ kuro.

Ezekiel ni "Kii ṣe pe a lọ le Eṣu wọn jade… ibudo igbafẹ to ba ti n gbalejo, kii ṣe pe o wa fun ẹsin kan."

Ikọja aye ni wọn lọ ṣe nibẹ - Baba orisa Osun Osogbo

Ifayemi Ifabode, to jẹ baba oriṣa Osun Osogbo sọ fun BBC pe ikọja aye lawọn pasitọ naa ba lọ sidi oriṣa awọn lati lọ maa le ẹmi Eṣu ibẹ jade.

O fi kun pe ohun ti pasitọ naa atawọn ọmọ ijọ rẹ ṣe le fa ija ẹsin, ko si bojumu.

Ẹwẹ, alukoro ẹgbẹ ọmọlẹyin Krisiti lagbegbe naa, Opadotun Samson sọ pe ohun to n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọlẹyin Kristi lasiko yii to abojuto, ko si yẹ ki wọn lọ maa tojubọ ẹsin ẹlomii.

Samson ni awọn gẹgẹ bii adari ẹgbẹ CAN ti ke si pasitọ naa ko wa sọ tẹnu rẹ lori ohun to ṣẹlẹ, amọ o kọ jalẹ lati yẹ ipe awọn si.

Wayi o, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodunn Ojelabi ti rọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ki maṣe dawọle ohun ti yoo fa ija ẹsin ki wọn si gba alaafia laaye.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.