Kí ni pàtàkì ọdún Aje? Ọọni Ogunwusi ṣàlàyé oun tó wà nínú bíbọ Òrìṣà Aje

Aje jẹ oun ko ṣe e ma ni, ṣugbọn ki i ṣe oun ti eeyan ma n gba ọna ẹburu wa.
Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọọni ti Ile-Ife lo ṣalaye pataki oun ti o wa ninu ọdun Aje ati bibọ oriṣa Aje.
Kabiyesi ni Aje kii ṣe oun ti eeyan maa n fi tipa tipa wa tabi fi ẹmi ọmọlakeji wa ki eeyan ko to ri.
Ooniriṣa tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe oun kii fi ọdun aje tabi oriṣa aje ṣere rara.
Ọba Ogunwusi ni oun maa n ri agbaayanu ore kaakiri gbogbo agbaye lẹyin ayẹyẹ ọdun Aje.
''Alaje ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu''
Kabiyesi Adeyeye Enitan Ogunwusi ni alaje ni aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu. Ooni ṣalaye pe nigba ti Ọlọrun gbe Tinubu dori ipo aarẹ, ni gbogbo nnkan di ẹrọ.
''Gbogbo nnkan ti bajẹ tan lorilẹede Naijiria ki aarẹ Tinubu to gba ijọba.
Ti ọmọ orilẹede Naijiria ba le ni suuru fun aarẹ, orilẹede Naijiria yoo dara nitori pe, ọmọ aje ni aarẹ wa.
Gbogbo atunṣe ti Tinubu n ṣe lọwọ yoo jẹ ki orilẹ-ede Naijiria ko dara si i, papaa julọ bi awọn ọmọ orilẹede Naijiria ba le tun bọ fọwọ sowọ pọ pẹlu aarẹ wa,'' Ooni lo sọ bẹẹ.
Kabiyesi wa rọ gbogbo awọn ọdọ lati ma fi tipa tipa wa aje mọ, amọ, ki wọn pada sọdọ oriṣa abalaye tii ṣe oriṣa Aje lati maa bọ ọ.
''Ilu Ile Ife ni oriṣa Aje wọlẹ si nigba iwasẹ''

Arabinrin Ajetoyin Omilani, iyalaje ti ilu Ile-Ifẹ, ṣalaye bi oriṣa Aje ṣe jẹ ati bo ṣe bẹrẹ ni ilu naa.
O ni aje jẹ nkan pataki ninu aye gbogbo eeyan, ati pe, aje ni wọn n pe ni yeye oke-ọja.
Gẹgẹ bi Arabinrin Omilani ṣe ṣalaye, Aje ki ṣe aje olokun rara, Aje onire ni.
Iyalaje ilu Ile Ife sọ pe Olokun ati Aje onire jẹ ọmọ iya kan naa ti wọn kii yara wọn ṣugbọn oriṣa wọn yatọ si ara wọn.
''Ilu Ile-Ifẹ ni Aje ti bẹrẹ, ibi ti oriṣa wọlẹ si ni wọn n pe ni ọja ojigbo mẹkun ni Ile Ife.
Nítorí Aje jẹ eeyan bi ti wa ni igba iwasẹ.''
Arabinrin Ajetoyin, tun tẹsiwaju pe Aje jẹ olulana fun gbogbo awọn oriṣa to ku.
Eleyi lo mu ki wọn kọkọ maa bọ oriṣa Aje ṣaaju awọn oriṣa to ku.
O wa rọ awọn ọdọ ati gbogbo ọmọ Yoruba lati pada sidi oriṣa ile baba wọn.
Arabinrin naa sọ pe eleyii ni yoo mu ki awọn ajalu toun ṣẹlẹ ko dopin.
''Ko si nnkan ti ẹda eeyan le ṣe, ti ko ba si Aje''

Awodotun Aworeni, Araba Awo agbaye naa ṣalaye pe ko si nnkan ti ẹda eeyan le ṣe ti ko ba si aje ninu aye eeyan.
Araba Awp Agbaye ni Aje jẹ oun pataki ninu aye ọmọ eeyan.
''A ko gbọdọ sọrọ odi wi pe aṣa wa n jo ajo rẹyin nitori ọlaju to de ti fẹ gba aṣa wa danu. Loootọ ni ọlaju dara ṣugbọn ko gbọdọ gba aṣa wa lọwọ wa.''
Awodotun wa rọ gbogbo awọn Oriade ati awọn ijọba lati mojuto aṣa Yoruba.
Bakan naa lo tun rọ awọn ọdọ wi pe ki wọn maa ṣe kanju wa owo.
Arabinrin Toyin Kolade, iyalaje Oodua ni tiẹ sọ pe bibọ oriṣa Aje tabi ṣiṣe ayẹyẹ ọdun oriṣa Aje maa n jẹ ki ọna ọpọlọpọ la si i.
O ni ti Kabiyesi Ọọni ba ti wure tan lakoko ọdun oriṣa Aje ni gbogbo nnkan maa n rọrun.
Arabinrin Toyin wa rọ gbogbo awọn gomina to wa ni ilẹ Yoruba lati mojuto aṣa Yoruba ki o maa ba parun.
O tun rọ gbogbo awọn ọdọ lati jawọ ninu iwa ibajẹ nipa fifi agbara wa owo kaakiri.
Ọna ko gbẹsẹ ni aafin Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi nibi ayẹyẹ ọdun oriṣa Aje ti ọdun yii.
Orisirisi ẹbun ni kabiyesi fun awọn eeyan to peju pesẹ si bi ayẹyẹ naa.



























