Wo ọmọ Naijiria mẹ́jọ tí Amẹrika gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá wọn lórí ẹ̀sùn ṣíṣe agbátẹrù fún Boko Haram àti ISIL

Donald Trump nawọ soke ninu aṣọ kootu to wọ pẹlu tai lọrun rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orilẹede Amẹrika ti gbẹsẹ le dukia ọmọ Naijiria mẹjọ lori ẹsun pe wọn n ṣagbatẹru fun ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ati ISIL.

Igbesẹ yii wa ninu atẹjade kan ti ajọ OFAC to n ri si ọrọ dukia nilẹ okeere fi sita laipẹ yii.

Atẹjade naa tun sọ nipa awọn eeyan ti wọn ti gba ijiya kan tabi omiran lori ẹsun lilu jibiti lori ayelujara.

Eyi waye lẹyin ti ile aṣofin agba Amẹrika sọ fun ijọba wi pe ko gbeṣe le fisa ati dukia awọn ti wọn fẹsun kan wi pe wọn n ṣe inunibini sawọn kristẹni ni Naijiria.

Lara awọn ti Amẹrika fofin de fisa wọn lati ma le rinrin ajo lọ si Amẹrika mọ ni Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Kwankwaso, ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria ati ẹgbẹ Miyetti Allah Kautal.

Ẹsun ti wọn fi kawọn eeyan ati ẹgbẹ yii ni pe wọn n siṣẹ pọ pẹlu awọn agbesunmọmi.

Imọran ile aṣofin agba Amẹrika naa wa ninu atẹjade ti ajọ OFAC fi sita, atẹjade naa ṣafihan awọn eeyan atawọn ẹgbẹ ti orilẹede Amẹrika ti gbẹsẹ le dukia wọn.

Wọnyi ni awọn ọmọ Naijiria ti Amẹrika ti gbẹsẹ le dukia wọn

Ọgbẹni Babestan Oluwole Ademulero jẹ ọkan lara awọn eeyan ti ijọba Amẹrika ti gbẹsẹ le dukia wọn lori ẹsun pe wọn n ṣagbatẹru awọn agbesunmọmi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ademulero ẹni ọdun mẹtalelọgọta ti inagijẹ rẹ n jẹ Wole A.Babastan lo wa ni isọri SDNTK fifi ofin de awọn afurasi.

Ẹlomiran to tun wa lara awọn ti Amẹrika ti fofin de ni Olatunde Irewole Shofeso.

Salih Yusuf Adamu naa wa lara awọn eeyan ti Amẹrika ti fofin de dukia wọn.

Adamu ti wọn bi ni ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ ọdun 1990 ni Amẹrika sọ pe o n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram.

Adamu wa lara awọn ọmọ Naijiria mẹfa ti wọn jẹbi ẹsun kiko owo jọ fun Boko Haram ni orilẹede UAE ki wọn le maa ba iṣẹ wọn lọ ni Naijiria.

Awọn ẹgbẹ naa gbiyanju lati fi $782,000 ranṣẹ si Naijiria lati Dubai.

Awọn mii ti wọn tun wa ninu awọn ti ijọba gbẹsẹ le dukia wọn ni Abu Abdullah ibn Umar Al-Barnawi (tawọn eeyan tun mọ si Ba Idrisa), Abu Musab Al-Barnawi (Habib Yusuf), Khaled (Khalid) Al-Barnawi, Ibrahim Ali Alhassan, ati Abu Bakr ibn Muhammad ibn Ali Al-Mainuki.

Gbogbo wọn ni wọn fẹsun kan wi pe wọn ni ibasẹpọ pẹlu Boko Haram tabi ISIL.

Nnamdi Orson Benson, ti wọn bi lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹta ọdun 1987 naa wa lara awọn ti Amẹrika gbẹsẹ le dukia wọn.

Ẹsun jibiti ori ayelujara ni wọn fi kan oun.

Ki ni igbesẹ Amẹrika yii tumọ si?

Nnkan ti igbesẹ Amẹrika to gbẹsẹ le dukia awọn eeyan yii tumọ si ni pe wọn o le lanfaani sawọn dukia wọn to wa lorilẹede Amẹrika ati ibi gbogbo ti Amẹrika ti laṣẹ le lori mọ.

Awọn ọmọ Amẹrika naa ko le bawọn ni nnkankan ṣe papọ mọ niwọn igba ti ijọba ti gbẹsẹ le dukia wọn.

Labẹ ofin ijọba Amẹrika 13224 ni ijọba ti gbẹsẹ le dukia awọn eeyan naa.

Lọdun 2013 ni Amẹrika kede Boko Haram gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi nilẹ okeere.

Amẹrika ni Boko Haram ti ṣe oniruuru ikọlu lapa ariwa orilẹede Naijiria papaa julọ lẹkun ila oorun ariwa Naijiria to fi de agbegbe Lake Chad lati ọdun 2009.

Ni oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni Aarẹ Donald Trump kede fun igba keji pe orilẹede Naijiria ti wa lara awọn orilẹede ti Amẹrika n kọminu le lori latari bawọn eeyan kan ṣe n tẹ ẹtọ awọn olujọsin mọlẹ nibẹ.

Lọdun 2020 ni Trump kọkọ fi Naijiria sara awọn orilẹede bẹẹ, amọ, Aarẹ Joe Biden yo ọ kuro lẹyin to di aarẹ Aarẹ Amẹrika.