Wo bí wọ́n ṣe sọdún Ohori Ije láti sàmì bí wọ́n ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Oduduwa ni Republic of Benin

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ Oduduwa ní Benin Republic ṣe ọdún Ohori Ije`
Wo bí wọ́n ṣe sọdún Ohori Ije láti sàmì bí wọ́n ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Oduduwa ni Republic of Benin

Àwọn ọmọ Oduduwa ní Benin Republic ṣe ọdún Ohori Ije

Awon eeyan Benin Republic nibi ajodun

Wọn ti ṣe ọdun Ohori Ije ni orilẹ-ede Olominira Benin.

Ilu Ohori Ije ti ọdun naa ti waye jẹ ọkan lara awọn ilu ti ọmọ Oduduwa tẹdo si lati igba iwasẹ ni orilẹede naa.

Iroyin ko to afojuba nibi ọdun naa, kọda odidi ọjọ mẹta gbako ni wọn fi ṣe ṣe ọdun ọhun.

Lara awọn nnkan ti awọn ọmọ Ohori fi ṣajọdun ti ọdun yii ni oriṣiriṣi awọn ounjẹ ibilẹ, ijo ibilẹ ati awọn oniruru ere idaraya.

Ọba Solomon Awelede, to jẹ Ọba Ohori Ije ṣlaye fun BBC Yoruba nibi ayẹyẹ naa pe ki awọn ọmọ ilu naa le mọ ara wọn, ati ki wọn ma baa sọnu ni wọn ṣe gbe ọun ọhun kalẹ.

O ni lasiko ọdun naa ni gbogbo ọmọ ilu yoo gbiyanju lati pada wa sile fun ọdun ọdun.

Ẹkunrẹrẹ ohun ti a ba bọ lati Benin wa ninu fidio yii.

Kini itan sọ nipa Iran Ohori?

Awọn ọmọ ilu Ohori nile loko lẹyin ko ara wọn jọ pọ lati ṣe ajọdun wọn ni orilẹ-ede Benin Republic.

Ilu yii ni itan sọ pe lati Ile Ife to jẹ orirun ẹya Yoruba ni ilu naa ti ṣẹ wa.

Itan tun fidi rẹ mulẹ pe ilu Oyo ni wọn kọkọ sẹ lọ ki wọn to lọ sí Benin Republic.

Kini o ṣẹlẹ nibẹ?

Ijo ibilẹ, afihan ounjẹ awọn Ohori at'awọn nkan mii yoo waye nibi ajọdun yii.

Fun apẹẹrẹ, awọn ọmọ Ohori gbagbọ pe Iran awọn lo kọkọ se ẹkọ àgbàdo.

Awọn ọmọ Ohori ṣetan lati ṣe afihan bi wọn ṣe n kọla at'awọn nkan mii nibi ajọdun yii.

Ilu Ohori Ije wa labẹ aṣẹ ijọba ibilẹ Ikpobe ni Benin Republic.