Wo bàbá àgbà tó ń gun ọ̀kadà polongo bí a ṣe lè tọ́ ọmọkùnrin yanjú lágbàáyé

Àkọlé fídíò, Wo agbalagba to n gun ọkada lati oke okun wa si Naijiria
Wo bàbá àgbà tó ń gun ọ̀kadà polongo bí a ṣe lè tọ́ ọmọkùnrin yanjú lágbàáyé

Ibi Sofekun jẹ ọkunrin to igbagbọ pe obi, alagbatọ ati mọlẹbi ni lati mojuto ọmọkunrin.

Sofekun gun ọkada lati oke okun de Naijiria lati se ipolongo fun bi a ti le ṣe tọ ọmọkurin lati fi le yanju lagbaye.

"O ni idi ti mo fi la eewu kọja nitori ife ti mo ni fun ọmọkurin, bi a ti le ṣe tọ wọn."

O fikun pe asiko ti to lati ma mojuto bi a ṣe n ṣe mojuto ọmọ ọkunrin lati le ni ọjọ ọla rere, ki wọn le jẹ akinkanju ọmọkunrin ni awujọ.

Bakan naa ni ko fi oju tẹmbẹlu itọju ọmọ obinrin ṣugbọn o gbagbọ pe ọdọmọbinrin nilo itọju to peye.

Ọrọ pọ lẹnu Ibi Sofekun lasiko to ba BBC News Yoruba sọrọ.

Aworan