Saudi Arabia: Ìjọba ti fàyé gba òbinrin lati rìnrinajo lọ orilẹ̀-èdè to wù wọ́n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣe mo le lọ?
Ìjọba Saudi Arabia ti kéde òfin tuntun tó fààyè gba obìnrin láti rìnrìn ajò lọ orílẹ̀-èdè tó ba wù wọ́n láì gba ìwé àṣẹ tàbi kí wọ́n de ẹ̀rọ ayawòrán mọ́ wọn lára
Ìgbésẹ̀ yìí ní àwọn ènìyàn rí bi àyípàdà túntun ti ọmọ ọba Saudi Mohammad Salman ń ṣe ni orílẹ̀-èdè náà.
Òfin túntun yiìí ni wọ́n kéde ní ago mẹ́jìlà ọ̀sán ọjọ ajé ní Jiddah, ó ni ki wọ́n fi ààyè gbà àwọn ọmọ obinrin ti ọjọ́ ori wọn kò jú mọkánlélogun lọ láti gba forúkọsilẹ̀ láti gba ìwé ìrìnà kí wọ́n lọ sí òkè òkun.
O ní ìgbésẹ̀ yìí yóò fún wọ́n ni ànfàni láti ṣe gbogbo ǹkan ti àwọn akẹgbẹ́ wọ́n ọkunrin ń ṣe, bákan náà ni òfin yìí yóo jẹ́ ki wọ́n yẹ láti rí iṣẹ́ ìgbàlóde lái si ìdẹ́yẹ si.
Ẹ̀wẹ̀, kí obinrin to lọ gba ìwé àṣẹ ìrìnà ó gbọ̀dọ̀ gbàṣẹ lọ́wọ́ ìyá, Baba tàbí ọmọ ẹgbọ́n tàbí àbúrò ìyá tàbi babarẹ̀ okùnrin kó to rìnrìn àjò lọ sí òkè-òkun.
Ìgbésẹ̀ yìí kò sàì so mọ́ bi àwọn ajàfẹ́tọ ọmọniyàn ṣe ń fún ogun mọ ìjọba lóri ẹ̀tọ́ obìnrin.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ní ìhà ìwọ̀-òòrun rí i pé ìtẹ̀síwájú ni èyí jẹ́ fún òbìnrín Saudi, síbẹ̀ àwùjọ àwọn musùlùmí kan nínú àtí lẹ́yìn odi Saudi rí i gẹ́gẹ́ bi ǹkan ti ko tọ̀nà.












