DR Congo Ebola: Òṣìṣẹ́ ìlera méje kú torí ibínú àwọn èèyàn nípa Ebola

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Awọn eniyan ro pe arun Ebola kii ṣe otitọ."
Eyi ni ọrọ Dokita Pascal Vahwere, ọkan lara awọn dokita to n gbogun ti arun naa ni orilẹede Democratic Republic of Congo, DRC.
"Ikọ̀ mi n f'oju wina ikọlu, nitori pe a n ṣe iṣẹ́ wa."
Ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ eto ilera lo ti ku nitori pe wọn n tọju tabi polongo igbogun ti aarun Ebola ni orilẹede Democratic Republic of Congo.
Ọkan lara awọn dokita to n ṣiṣẹ lati gbogun ti arun naa, Pascal Vahwere sọ iriri rẹ fun BBC lasiko ti awọn ara abule kan ni Ariwa ẹkùn Kivu deede yi oun ati ikọ rẹ ka lasiko ti wọn fẹ fun awọn ara abule naa ni abẹrẹ ajẹsara.
"Lojiji ni awọn ero to ko ada ati ibọn dani yi wa ka. A ko mọ idi ti wọn fi fẹ ẹ ṣe ijamba fun wa. Ẹru ba wa. Nipasẹ awọn olori ilu la fi ba awọn ara ilu sọrọ, a si pẹtu si awọn ero naa l'ọkan."
Bo ti lẹ jẹ pe itankalẹ arun Ebola n pa ọpọ eniyan si, sibẹ awọn oṣiṣẹ eto ilera n la ewu ibinu awọn ajijagbara ati eniyan miran kọja nitori awọn ayederu iroyin to n tan kalẹ bi ina inu ẹẹrun, paapa lori ayelujara Whatsapp.
Ko din ni oṣiṣẹ eto ilera meje ti wọn ti pa ni ọdun yii nikan. BBC ba diẹ lara awọn to n gbogun ti Ebola sọrọ, lori idi ti eyi fi n ṣẹlẹ si wọn.
Ayederu Iroyin
"Awọn ayederu iroyin naa n mu ki awọn eniyan o ni igbagbọ pe, awọn oloṣelu n fi aarun Ebola pa owo si apo ara wọn."
Dokita Vahwere, to sọ eyi fun BBC tun sọ pe "awọn miran tiẹ maa n sọ pe iwosan ti wọn n fun awọn to ni aarun naa gan an lo n pa wọn."
Awọn ikọlu to ti waye:
Awọn ayederu iroyin ti fa awọn ikọlu to l'agbara.
Ọga agba ni ẹka ibanisọrọ ninu ajọ eleto ilera lagbaye WHO, sọ fun BBC pe:
"laarin ọjọ kinni, oṣu Kinni si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2019, ikọlu igba din meji ti ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, ṣe akọsilẹ rẹ, fa iku oṣiṣẹ eto ilera meje, ti awọn mejidinlọgọta si fi ara pa ni orilẹede DRC."
Itankalẹ aarun Ebola
Bi awọn ikọlu naa ṣe n waye, to si n fa iku ọpọlọpọ ti mu ki adinku ba bi awọn oṣiṣẹ eto ilera ṣe n dena itankalẹ aarun naa ni DR Congo.
Lai ti i pe ọdun kan, awọn to ti ni aarun naa ti pe ẹgbẹrun meji.
Abẹrẹ Ajẹsara
Wọn ti n fun awọn eniyan ni abẹrẹ ajẹsara kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe jade lati dena itankalẹ aarun Ebola.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eniyan bi ẹgbẹrun lọna aadọsan to ti sunmọ awọn to ni aarun Ebola lo ti gba abẹrẹ ajẹsara naa.
Ṣugbọn bi wọn ṣe n kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera ti fa idiwọ fun pinpin abẹrẹ naa, eyi si ti mu ki aarun naa tan kalẹ si.
Ijọba orilẹede DR Congo n di ẹbi awọn ikọlu naa ru awọn oriṣiriṣi ikọ ajijagbara to wa ni orilẹede naa.
Ṣugbọn kii ṣe awọn ajijagbara yii nikan lo n ṣe ikọlu, awọn araalu naa n kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apẹẹrẹ iru iṣẹlẹ bẹẹ ni bi mọlẹbi ẹnikan ti arun naa pa, ṣe kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera to n bawọn mojuto isinku ẹbi wọn naa.
Amọ ṣa, ijọba ti n fi awọn ọmọ ogun ṣọ diẹ lara awọn ile iwosan ti wọn ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ.
Dokita Vahwere ti ẹ sọ pe, awọn eniyan kan ti n gbagbọ pe lootọ ni arun Ebola wa. "Ibẹru si ti n lọ lara awọn oṣiṣẹ eto ilera naa."













