Akẹ́kọ̀ọ́ Ilé ẹ̀kọ́ fásítì LAUTECH mẹ́fà tó ń lọ ṣèdánwò àṣekágbá pàdánù ẹ̀mi wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ ‎

Ọkọ to ni ijamba nibi tawọn akẹkọọ ile ẹkọ LAUTECH ti ku

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

‎Ko din ni mẹfa ninu awọn akẹkọọ fasiti Ladoke Akintola, LAUTECH, ti Ilu Ogbomoso to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to waye ni opopona marosẹ Suleja-Abuja si Ilorin ni ọjọ isinmi to kọja.

‎Awọn akẹkọọ yii ti wọn n kẹkọọ nipa eto iwosan lo se alabapade iku ojiji nigba ti wọn n rin irinajo lo si ile-iwe giga naa lati lọ se idanwo saa to kẹyin nipa eto ẹkọ wọn.

‎Orukọ awọn akẹkọọ naa ni Nana Firdausi Shehu Utene, Elizabeth Owoicho, Blessing Kevwe, Maimunah Abdulraheem Hamza, Jamila Idris Sarkinbaka ati, Victoria Aroke Ozavize.

Ninu ọrọ ti wọn fi sita, ẹgbẹ awọn nọọsi ni Ilẹ Afirika fi idi isẹlẹ naa mulẹ.

Awọn igbimọ lati ile ẹkọ LAUTECH naa tẹkọ leti lọ si ile igbokusi to wa ni ile iwosan fasiti Ilorin ti wọn oku awọn akẹkọọ naa si.

‎Awọn alakoso ẹka ikẹkọọ naa ninu ọrọ wọn salaye wi pe awọn ẹbi Jamila Idris Sarkinbaka ati Maimunah Abdulraheem Hamza ti se abẹwo lati gba oku awọn ọmọ wọn.

Ohun ti a gbọ ni pe oku awọn mẹrin yooku si wa ni ile igbokusi to wa ni ile iwosan ti fasiti Ilorin.