Ariwo ayọ̀ ní ààfin Ooni ti Ile Ife bí Olori Mariam ṣe bí ìbejì ọkùnrin

Oríṣun àwòrán, Ooniadimulaife/Instagram
Ariwo ayọ̀ ní ààfin Ooni ti Ile Ife bí Olori Mariam ṣe bí ìbejì ọkùnrin
Idunnu ti ṣubú lu ayọ̀ báyìí ní ààfin Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi.
Ìdí ni pé olórí àgbà, Mariam Ajibola ti bí ìbejì, ọkùnrin méjì lanti lanti fún oríadé náà.
Kabiyesi Arole Oodua fúnra rẹ lo fi ìròyìn náà léde lójú òpó ayélujára Instagram rẹ ní ìdajì oni ọjọ́ Ẹtì.
"A kì gbogbo Ààfin àti ìdílé Arole Oodua kú oriire bí Olori àgbà, Mariam Ajibola ṣe bí ọmọọba ọkùnrin méjì sórí ìtẹ́ Oduduwa"
Ọba Ogunwusi ni “Ògo ni fún Ọlọ́run fún àwọn iṣẹ́ ìyanu àti ìbùkún rẹ lẹ́ẹ̀kan si.
A kì gbogbo Ààfin àti ìdílé Arole Oodua kú oriire bí Olori àgbà, Mariam Ajibola ṣe bí ọmọọba ọkùnrin méjì sórí ìtẹ́ Oduduwa.
A dúpẹ́ pé ìyá àtàwọn ìbejì náà wà ní àlàáfíà.”
Bi ẹ kò ba gbagbe, ó to ọjọ́ mẹta tí Olórí Mariam Ajibola ti jáde síta fún ojú rí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn si lo maa n beere pe nibo ni olórí náà wà.

Oríṣun àwòrán, Ooniadimulaife/Instagram
Bẹẹ ba gbagbe, ayaba mẹrin lo wọnu aafin Ọọni Ile Ife laarin osu meji, to si se iyawo alarinrin fun ikọọkan wọn.
Orukọ awọn olori naa ni Ayaba Mariam Ajibola Anako Ogunwusi, Olori Elizabeth Ogunwusi, Olori Tobi Phillips Ogunwusi ati Ayaba Ashley Ogunwusi.
Ta ni olórí Mariam Ajibola Ogunwusi?
Gbajumọ oniṣowo epo ni arabinrin Mariam Anako, ọmọ ẹya Ebira ni ipinlẹ Kogi si ni.
Ilu Ilorin ni a gbọ pe awọn obi rẹ wa.
Bakan naa la gbọ pe Mariam padanu baba rẹ lati igba ewe rẹ, ile ọga ọlọpaa patapata ri lorilẹede Naijiria, Mohammed Dikko Abubakar ni wọn si ti tọọ dagba.
Iya rẹ pẹlu jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti.
Mariam Anakọ ni obinrin kẹrin ti yoo jẹ olori Ọba Ogunwusi lẹyin to pinya pẹlu Woli Naomi ni ọdun to kọja.

























