Mariam Anako: Ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa ìyàwó Ọọni tuntun

Ooni Adewusi ati Olori tuntun

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iyawo ti Ọọni ti Ile Ife, Oba Enitan Ogunwusi, Ojaja II ṣẹṣẹ fẹ, Mariam Anakọ ni awọn eniyan n sọrọ nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara.

Laipẹ ni iroyin jade ninu fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara pe Ọọni ti fẹ iyawo tuntun, ti awọn oloye laafin to fi mọ Ọọni fun ara rẹ si n gbadura fun lasiko to kunlẹ niwaju ọba naa.

Mariam Anakọ ni obinrin kẹrin ti yoo jẹ olori Ọba Ogunwusi lẹyin to pinya pẹlu Woli Naomi ni ọdun to kọja.

Awọn ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa iyawo tuntun Mariam Anako

Ki o to di olori ni aafin, gbajumọ oniṣowo epo ni arabinrin Mariam Anako, ọmọ ẹya Ebira ni ipinlẹ Kogi si ni.

Ilu Ilorin ni a gbọ pe awọn obi rẹ wa.

Bakan naa la gbọ pe Mariam padanu baba rẹ lati igba ewe rẹ, ile ọga ọlọpaa patapata ri lorilẹede Naijiria, Mohammed Dikko Abubakar ni wọn si ti tọọ dagba.

Iya rẹ pẹlu jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, olorì tuntun wọ ààfin Ooni Ife

Kabiyesi Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti fẹ olori tuntun.

Orukọ olori tuntun naa ni Mariam Anako.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko kede igbeyawo naa ṣaaju fun gbogbo agbaye, ọpọ awọn ẹbi, oloye, ọtọkulu atawọn ladelade lati ipinlẹ Kwara lo peju sibi igbeyawo ọhun.

Fidio kan ti Yera Moses Olafare, tii se akọwe feto iroyin fun Ooni Ife, fi soju opo Facebook rẹ lo se afihan bi ayẹyẹ igbeyawo naa se lọ.

Lara awọn ladelade to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọhun ni aṣoju Olofin Adimula, Owa Ajero, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Igbeyawo tuntun yii lo n waye lẹyin ti igbeyawo Ooni pẹlu wolii obinrin, Naomi Silekunola tuka.

Ooni

Oríṣun àwòrán, Kilarigbo Live

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kejila, ọdun 2021 ni Naomi kede loju opo Instagram rẹ pe oun ati Ooni ti pinya.

Lẹyin naa lo tun kede pe oun fẹ yọ akọle ‘Olori’ kuro lara orukọ oun.

Ṣaaju igbeyawo rẹ pẹlu Ooni, Naomi ni adari ijọ kan, En-Herald Ministries, to wa nilu Akure, ni ipinlẹ Ondo.

Awọn obinrin ile n bu omi si iyawo tuntun lẹsẹ

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Nibi ayẹyẹ igbeyawo ti ko la ariwo lọ, ni wn mu olori tuntun Mariam wọnu aafin Ife lọ.

Saaju si ni awọn obinrin ile ti bu omi si iyawo tuntun naa lẹsẹ, ti ọpọ eeyan si n se adura fun.

Bakan naa ninu fidio igbeyawo ọhun to jade soti ayelujara, la ti ri Olori Mariam Anako to kunlẹ siwaju ọpọ eeyan, plu ilẹkẹ olori lọrun rẹ.

Ta ni Mariam Anako ti Ooni ṣẹṣẹ fẹ?

Gbajumọ oniṣowo epo ni arabinrin Mariam Anako, ọmọ ẹya Ebira ni ipinlẹ Kogi si ni.

Ilu Ilorin ni a gbọ pe awọn obi rẹ wa.

Bakan naa la gbọ pe Mariam padanu baba rẹ lati igba ewe rẹ, ile ọga ọlọpaa patapata ri lorilẹede Naijiria, Mohammed Dikko Abubakar ni wọn si ti tọọ dagba.

Iya rẹ pẹlu jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti.

Awọn igbeyawo ti Ooni ti ṣe ṣaaju olori tuntun yii

Ooni

Oríṣun àwòrán, Ile Oodua

Eyi ni yoo jẹ igba kẹrin ti Ọọni Ile Ifẹ yoo maa ṣe igbeyawo arede.

Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe apọn ni Ọoniriṣa pada si lẹyin ti Olori rẹ ana, Ṣilẹkunnọla Naomi fi silẹ ni oṣu kejila ọdun 2021.

Igbeyawo wọn so eso kan ṣoṣo, ọmọ okunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Tadenikawo; oṣu kọkanla ọdun yii si ni ọmọdekunrin ọhun yoo pe ọmọ ọdun meji.

Ooni

Oríṣun àwòrán, Ile Oodua

Ṣaaju Naomi, Kabiyesi Ọọni Ogunwusi ti kọkọ fẹ Adebukola Bombata ki o to de ori oye ṣugbọn ituka waye lẹyin iwuye rẹ.

Lẹyin rẹ, o fẹ Olori Wuraọla ki igbeyawo naa to foriṣanpọn loṣu keje ọdun 2017.

Lẹyin rẹ lo fẹ Olori Naomi lọdun 2018 ki onitọun pẹlu to gba ori ayelujara Instagram lọ lati kede ituka igbeyawo oun ati ọbalaye naa.