Ọmọ ‘Yahoo-Yahoo méjì ṣekúpa akẹẹgbẹ́ wọn tórí ó ń rí owó jù wọ́n lọ

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Okunrin meji ti jẹwọ bi wọn se gbinmọpọ lati sekupa ọrẹ wọn ni osu kẹjọ ọdun 2022.
Wahab Hammed, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Adegoke Ayobami, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn lo jẹwọ iwa ipaniyan naa fawọn ọlọpaa.
Awọn mejeeji ni wọn jẹwọ pe awọn pa Oguntade Wasiu nitori pe o ni owo ju awọn lọ.
Awọn ọrẹ naa sisọ loju ọrọ yii lasiko tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun n se afihan wọn fawọn akọroyin.
Hammed ni ọrẹ ni oun ati Ayobami jẹ si oloogbe naa, ti awọn si n jọ se isẹ lilu eeyan ni jibiti ta mọ si ‘YahooYahoo’.
Amọ o ni ọwọ Wasiu ji si owo, to si maa n ri owo gba ju awọn lọ.
‘Wasiu maa n sọ nipa aseyọri rẹ fun wa nigba gbogbo la se pa a’
“Iṣe aransọ ni mo n ṣe, ti mo si ni sọọbu sugbọn mo tun n wa ọkada.
Mo wa lati Modakeke in agboole Adesiyan. Mo dẹ tun ma n ṣe ‘YahooYahoo’ sugbọn n ko ri owo gba ri.
Wasiu jẹ ọrẹ si Ayobami. Mo mọ Wasiu lati ipasẹ Ayobami nitori wọn dijọ n ṣe isẹ yii ni.
O ti n ṣe isẹ naa ka to bẹrẹ ọrẹ wa nibi ọdun kan sẹyin.
“Emi ati Ayobami dijọ ṣekupa Wasiu nitori pe ni gbogbo igba, lo ma sọ fun wa awọn aṣeyori rẹ.
O maa n sọ iye owo to n gba nibi isẹ YahooYahoo fun wa, to si maa n fi awọn nnkan yii la wa loju.
Bakan naa la mọ bo se si sọọbu fun Iyawo rẹ, to si tun n ra goolu atawọn ẹsọ ara mii fun."
‘A tan Wasiu lọ sori ilẹ kan to fẹ ra, a yin lọrun, fi ada sa lori’
Wahab Hammed fikun pe “Gbogbo nnkan wọnyi lo ṣe okunfa idi ti a fi ṣeku pa Wasiu.
“Ọjọ kẹjọ, osu kẹjọ, ọdun 2023 ni a ṣekupa Wasiu. A tan lọ si ori ilẹ kan to fẹ ra ni Modakeke.
Lẹyin ti to wo ile naa, ti a n pada lọ sile, Wasiu lo wa niwaju, emi ni mo tẹle, ti Ayobami si wa lẹyin mi.
Kopẹ ni Ayobami fun ọrun Wasiu, nigba to bẹrẹ si pariwo, Ayobami fi ada sa ni ori."
Hammed fikun pe “Ko ki n ṣe pe a fẹ pa Wasiu, owo ọwọ rẹ ni a fẹ gba sugbọn Ayobami ṣeku pa.
Lẹyin ọjọ diẹ ni mo lọ si ilesṣẹ ọlọpaa lati fi ara mi han.
Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Olawale Olokode ni awọn yoo fi oju awọn afurasi naa bale ẹjọ, lẹyin ti iwadi ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Adigunjalè kọlu báńkì mẹ́tà ní Kogi, owó ńla pòórá

Oríṣun àwòrán, others
Ikọ adigunjale kan ṣe ikọlu si banki mẹta ni agbegbe Ankpa ni ipinlẹ Kogi, ti wọn si ko obitibiti owo lọ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe ikọlu naa waye ni awọn banki bii UBA, Zenith ati First Bank.
Bakan naa ni awọn adigunjale ọhun tun ṣe abẹwo si awọn onisowo abanigbowo lẹnu ẹrọ, POS to wa ni agbegbe naa.
Osojumikoro ni awọn adigunjale naa to ogun niye ti wọn balẹ si agbegbe naa ni deede aago meji ọsan pẹlu ọpọlọpọ ọkọ, bọọsi ati ọkada.
Ileeṣẹ ilefowopamọ UBA ni wọn ti bẹrẹ ki wọn to mori lẹ Zenith Bank ati FirstBank.
Osojumikoro ni odidi wakati kan ni awọn adigunjale naa fi sọsẹ, ki wọn to kuro ni ilu naa.
“Pẹlu ibọn yinyin ni wọn fi kuro ni agbegbe wa, ti wọn fi gba opopona Okpo salọ.
“Ko si ẹnikẹni to riran ri awọn adigunjale naa nitori wọn n yin ibọn lakọlakọ, ti gbogbo wa si sa pamọ.
“A ko ti le sọ boya ẹnikẹni sese tabi fara pa.”
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi ko ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ sugbọn Osojumikoro ni kete ti awọn adigunjale kuro ni agbegbe naa, ni awọn ọlọpaa ti balẹ.
Agbébọn jí èèyàn 18 l‘Ondo, ọlọ́pàá rí ọ̀kan gbà sílẹ̀ nínú wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn ti doola ọkan lara awọn eeyan mejidinlogun ti awọn agbebọn ji gbe lọjọ Satide.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Funmilayo Odunlami lo ṣalaye ọrọ naa fun BBC ninu ifọrọwerọ kan.
Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko le sọ ohunkohun nipa iroyin to gbode pe awọn ajinigbe naa n beere aadọrun miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi awọn eeyan naa,
Amọ Odunlami ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati doola awọn eeyan to ku.
Kọmisana l‘Ondo ni agbebọn n beere owo itusilẹ
Opin ọsẹ to kọja ni awọn ajinigbe naa ti kọkọ ji awọn eeyan naa gbe lasiko ti wọn n rinrinajo pada bọ lati ipinlẹ Edo, nibi ti iroyin ni wọn ti lọ ṣe ayẹyẹ kan.
Ṣaaju ni kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ Ondo, Bamidele Ademola-Olateju ti kọkọ sọ fun awọn akọroyin pe awọn ti doola lara awọn eeyan ọhun.
O ni mẹsan ninu awọn eeyan naa lo ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe ọhun.
Bamidele sọ pe “Lonii, awọn ajinigbe naa kan si awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe.
Wọn si n beere owo ti iye rẹ wa laarin miliọnu mẹta si miliọnu mẹwaa naira fun itusilẹ wọn.”
Iṣẹlẹ ijinigbe ni Naijiria
Iṣẹlẹ ijinigbe ti di tọrọ fọnkale ni Naijiria lati nnkan bii ọdun melo kan sẹyin ti ijọba Muhammadu Buhari ti gori oye.
Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n di ẹbi ọrọ naa le ijọba lori, naa ni ijọba n di ẹbi ọrọ ọhun le awọn agbesumọmi lori.
Awọn agbesumọmi naa ṣaba maa n gbe awọn arinrinajo, awọn ọdọ atawọn to n gbe ni igberiko.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2022 yii lawọn agbesumọmi kan ji awọn arinrinajo inu reluwe lọna oju irin Abuja si Kaduna gbe lọ.
Koda, wọn tun pa awọn kan lara wọn.
Ẹwẹ, ijọba apapọ ti ni ọrọ awọn ajinigbe yoo di ohun igbagbe titi ipari oṣu Kejila ọdun yii.














