NDLEA rí agbésùnmọ̀mí mẹ́jọ mú nínú ìgbó Akure lásìkò tí wọn ń wá àwọn tó ń gbé òògùn olóró

Oríṣun àwòrán, NDLEA/INSTAGRAM
Ọwọ ti tẹ arakunrin kan ẹni ọdun mẹtalelaadọta, Ehiarimwiam Osaromo Emmanuel, lasiko to n gbe oogun oloro lọ si orilẹede Italy.
Ọkunrin naa to jẹ akanda ẹda ni Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun, NDLEA ni ọwọ wọn tẹ ni papako ofurufu Murtala Muhammed Airport, ni ilu Eko to si n lọ si orilẹede Italy.
Ọjọ Isinmi ni ọwọ tẹ arakunrin naa to jẹ ara ilu Orhionmwon, ni ipinlẹ Edo.
‘5000 oogun oloro Tramadol la ba ninu ẹru akanda ẹda’
O le ni ẹgbẹrun marun un oogun oloro Tramadol ti wọn ba ni inu ẹru rẹ.
Iwadii fihan an pe igba akọkọ kọ ni yii to ti ma n rin irinajo bẹẹ, ti ọpọlọpọ ohun ipara, ounjẹ , irun ori ati ọti ẹlẹrindodo si ma n wa ninu ẹru rẹ.
Nkan yan fun akanda ẹda naa nigba to de papakọ ofururu, ti wọn si yẹ ẹru rẹ wo ni saa yii finifini, ti wọn si ba oogun oloro naa nibẹ.
Bakan naa ni igbogun ti oogun oloro yii n lọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, NDLEA?Instagram
A ko àwọn agbesunmọmi ninu igbo Akure lasiko ta n wa awọn to n gbe oogun oloro
Bakan naa, ni ipinlẹ Ondo , Ajọ NDLEA ni ọwọ awọn tẹ awọn agbesunmọmi ninu Igbo ni ilu Akure.
Isẹlẹ yii ni wọn lo waye lasiko ti wọn n wa ogbontagiri oloogun oloro ti wọn ti n wa fun ọjọ pipẹ.
Agbesunmọmi mẹjọ si ni ọwọ NDLEA tẹ ninu igbo naa pẹlu awn ohun ija oloro ati ado abugbẹmu lọwọ wọn.
Ajọ NDLEA ni ọwọ awọn ti tẹ awọn ologun oloro ni agbegbe Opic, nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti n gbe oogun oloro kaakiri Naijiria, ti ọwọ palaba wọn si segi.
Ni ipinlẹ Sokoto naa ni ajọ ọhun ti mu ọkọ akero to jẹ oogun oloro lo kun apoti orin wọn.
Bakan naa ni wọn ri awọn miran gbe ni ilu Gombe, Abuja nibi ti obinrin oniṣowo kan ti gbin igbo si inu Ile rẹ.
Alaga Ajo NDLEA naa wa dupe lowo awon osise naa fun ise ribiribi ti wọn ṣe, ti wọn si n fi ẹmi wọn we ewu.















