Wo àwọn ọkùnrin tó ń tọ́ ìrora nǹkan oṣù obìnrin wò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan oṣu obìnrin jẹ ìrora kan tí awọn obinrin maa n dojukọ losoosu, amọ to si jẹ pe eewọ ni eyi lawọn apa ibi kan lorilẹede India.
Ṣugbọn ìpolongo kan ti bẹrẹ ni Kerala, lapa guusu Orilẹede India lati yii igbagbọ awọn eeyan pada nipa nnkan osu awọn obinrin.
Awọn to n ṣe agbatẹru ipolongo tako aṣa yii ti n lọ kaakiri awọn sọọbu ati ile ẹkọ ni agbegbe Ernakulam.
Nibẹ ni wọn ti n ṣe ayẹwo bí ìrora nkan oṣu obìnrin ṣe rí lara awọn ọkunrin gẹgẹ bi ara awọn ọna lati mu ki ọgọọrọ eeyan nibẹ ni itaniji nipa ọrọ yii.
Fidio kan ti awọn to n ṣagbatẹru ipolongo yii gbe jade laipẹ yii, ṣe afihan awọn ọkunrin ti wọn n kerora.
Se ni gbogbo awọn obinrin to n woran wọn si bẹrẹ si nii rẹrin.
‘Ọpọ ọkunrin lo n wo nnkan osu obinrin bii ohun idọti’
"Ìrora yii pọ, emi o fẹ rí iru ìrora bayi mọ," ni ọrọ ti arakunrin Sharan Nasir fi sẹnu lẹyin to kopa ninu ayẹwo ninu sọọbu kan.
Abala kan wa nibi ayẹwo naa ti wọn pe ni ife aye "Cup of life" , eyi tí wọn fi n wo orisirisi nnkan to yẹ.
Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin nilẹ India, Hibi Eden, lo gbe ìpolongo naa kalẹ pẹlu ajọsepọ ajọ eleto ìlera lorilẹede naa.
Ilera obìnrin, papajulọ ohun to jọ mọ nkan oṣu obìnrin lo jẹ nkan ti ko ni akiyesi
to yanranti lorilẹede India.
Ní awọn apa ibi kan, irí idọti tí ko lanfani lati wa ni awọn awujọ, ni wọn n ri awọn obìnrin to ba ṣe nkan oṣu.

Oríṣun àwòrán, others
‘O yẹ kawọn ọkunrin mọ nípa nnkan oṣu obìnrin ati idanilẹkọ nipa rẹ’
Ọlaju ti de awọn ibi kan sugbọn awọn obinrin ko ni anfani lati sọrọ lori ìrora tí wọn dojú kọ tí wọn ba n se nkan oṣu.
Awọn ileeṣẹ kan tí bẹrẹ lati ma fun awọn Osisẹ ni ìsinmi lẹnu iṣẹ lawọn ọjọ ti wọn ba n ṣe nnkan oṣu wọn nitori.
Igbagbọ wa ni pe ipolongo naa yoo mu iyipada wa niluu Kerala.
Agbẹjoro Sandra Sunny, to jẹ ọkan lara awọn to gbe ìpolongo naa kalẹ ni, ayẹwo naa yoo mu iyipada ba bí awọn eeyan ṣe n ronu si nipa nkan oṣu obìnrin.
"Ti ẹ ba beere lọwọ awọn ọkunrin ni ile ẹkọ gíga pe kini wọn mọ nípa nkan oṣu obìnrin, wọn ko le ri nkan sọ.
"Ṣugbọn tí ẹ ba bí wọn pe ṣe wọn ti sọrọ lori nkan oṣu obìnrin pẹlu ẹni kankan ati pe ki lo de tí wọn ko fẹ ba eeyan sọrọ nipa rẹ?
Lẹyin tí wọn kopa ninu ayẹwo yii, ẹ ri pe ọkan wọn balẹ "

Oríṣun àwòrán, others
‘Pẹlu ẹrọ ayẹwo, obinrin lo n jẹ irora nnkan osu obinrin'
Ẹrọ ayẹwo naa ni ẹnu meji, ti wọn maa n fi si ara ọkùnrin ati obinrin lẹkanna, tí obìnrin ko si ni jẹ ìrora kankan sugbọn ìrora yoo de ba ọkùnrin.
Ọgbẹni Nair ni igba ti awọn beere lọwọ awọn ọdọmọbinrin to ṣe ayẹwo boya wọn jẹ ìrora, wọn ni rara.
Sugbọn o ni awọn ọkunrin pariwo pe ìrora naa pọ fun awọn.
Ayẹwo yii lo tí fa ọpọlọpọ awuyewuye ni awọn ile ẹkọ ni Ernakulam.
Awọn ọkunrin to kopa ninu ayẹwo naa ni awọn ko lẹmi lati mu ara duro fun ayẹwo naa.
Ninu oṣu keje, ileeṣẹ kan lati orilẹede Amerika, ‘Somedays’, rọ awọn ọkunrin lati
ma lo awọn ẹrọ naa.
O ni eyi yoo jẹ kawọn ọkunrin le mọ nkan ti awọn obinrin n doju kọ tí wọn ba ti n ṣe nkan oṣu.
Ogunlọgọ eeyan si lo tí wo fọnran yii lori ayelujara.
Eden ni ó wu oun lori nigba ti oun kopa ninu ìpolongo naa, ti oun si ti ipasẹ bẹẹ bẹrẹ agbekalẹ ìpolongo fun awọn obinrin.
O ni abule kan tí orukọ rẹ jẹ Kumbalangi ni ipolongo naa ti waye.
Eden ni ìpolongo naa ni yoo ṣe iranwọ lati le yí ọkan awọn eeyan pada lori nkan
oṣu awọn obinrin.
Dokita Manuel ni pupọ lara awọn ọmọ ẹgbẹ aṣofin ati awọn ileeṣẹ nlala ni wọn ti fẹhonuhan ninu ìpolongo naa.
O ni awọn eeyan naa ti n beere pe ṣe awọn le gbe lọ sí agbegbe wọn.
Bakan naa lo ni isẹ sì wa lati ṣe ni awujọ wọn lati ripe awọn pese ilanilọyẹ to peye fun awọn eeyan lori anfani ìpolongo naa ati ọna ti wọn le gba lati fi ṣe.















