Wo ìgbésẹ̀ tí iléeṣẹ́ Civil Defence ń gbé lórí ìkọlù sí Yinka Ayefele

Oríṣun àwòrán, yinkaayefele/Instagram
Ajọ alaabo Civil Defence (NSCDC) tí n gbe igbesẹ lori ikọlu ti ọkan lara awọn osisẹ ajọ naa se si gbajumọ akọrin Tungba nni, Yinka Ayefele.
Ileesẹ Civil Defence naa lo ti wa tọrọ aforijin lọwọ akọrin Tungba nni, Yinka Ayefele
Bakan naa nileesẹ NSCDC tun kede pe oun ti bẹrẹ iwadi lori bi ọkan lara awọn osisẹ ajọ naa se kọlu gbajugbaja akọrin naa.
Saaju la ti mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin nipa bi isẹlẹ naa se waye lati ẹnu Yinka Ayefẹlẹ funra rẹ.
Isẹlẹ naa si ni Ayefele sọ pe o waye nilu Iloro Ekiti lasiko to lọ sere fun alariya kan.
A ti tọrọ aforijin, ta si ti ransẹ pe awọn afurasi naa lati wa ba wa ni Abuja
Ajọ NSCDC tí wa bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, to si salaye pe oun tí bẹrẹ iwadi lori osisẹ rẹ to lọwọ ninu ikọlu naa.
Ninu atẹjade tí agbẹnusọ fajọ NSCDC, Olusola Odumosu, fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọbọ, o ní irufẹ iwa naa ni ajọ ọhun lodi si pupọ.
O ni ajọ naa ko ni fi aye silẹ fun osisẹ kankan lati se awọn araalu ni ìṣekúṣe.
Odumosu wa ni ajọ NSCDC tọrọ aforijin lọwọ Dokita Yinka Ayefele ati awọn alátilẹyin wọn ati pe awọn ti bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa.
O ni Ọga agba ajọ NSCDC tí pa lasẹ pe ki awọn ṣe awari osisẹ agbofinro naa, kí wọn si fi ransẹ sì ìlu Abuja fun ijiya to tọ.
"Ajọ NSCDC labẹ alaga Dokita Ahmed Abubakar Audi lodi si irufẹ iwa ọdaran to lese ijamba sì ẹmi ati dukia awọn ọmọ Orilẹede Naijiria.
"A ko fi aye silẹ fun irufẹ iwa yíi nítorí ko ba ofin mu."
Ọga agba NSCDC tí palasẹ kí wọn ṣe afihan awọn osisẹ agbofinro to lọwọ ninu ikọlu naa, kí wọn si wọn si wa silu Abuja fun ijiya to tọ."

Oríṣun àwòrán, OFFICIAL_NSCDC
Bawo ni isẹlẹ naa se waye?
Yinka Ayefẹlẹ ṣalaye fun BBC Yoruba pe isẹlẹ naa waye bi oun ṣe pari ere tan, ti oun fẹ maa lọ.
O ni gẹgẹ bi iṣe oun, oun duro lati fun awọn eeyan ni owo, paapaajulọ awọn agbofinro.
Ayefele ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira toun fẹ da soke yii, ni oun ko dani lasiko ti oun fẹ jade nibi ode ere naa.
Ayefẹlẹ ni bi oun ṣe tẹ gilaasi ọkọ oun wa silẹ bayii, ni agbofinro Civil Defence naa ṣadede ki ọwọ bọ inu ọkọ oun, lati ja owo naa gba mọ oun lọwọ.
“Bi mo ṣe sọ pe ki lo fẹ fa gbogbo iyẹn? Ṣebi emi funra mi ni mo duro, lo ba sọ ẹṣẹ si mi lẹnu.
Mo wa sọ fun awọn ọmọ mi to wa ninu mọto pe wọn ko gbọdọ jẹ ko lọ.A gbọdọ mọ ọfiisi wọn.
Bo ṣe kẹ ibọn niyẹn to bọ siwaju mọto pe oun yoo yinbọn fun ẹnikẹni to ba sun mọ oun.”
Ọpọ ọmọ Naijiria si lo ti n fi apa janu lori isẹlẹ yii.















