Òṣìṣẹ́ ‘Civil Defence’ gbá mí létí, ẹ̀jẹ̀ ń yọ lẹ́nu mi - Ayefele

Ayefele: Òṣìṣẹ́ NSCDC ga ìbọn láti pa mi, ọ̀pẹ́ Ọlọ́run

Yinka Ayefele

Gbajumọ akọrin Tungba nni, Oloye Yinka Ayefele ni iroyin gbode lori rẹ laarọ ọjọru pe osisẹ agbofinro kan na a.

Bakan naa ni iroyin naa ni ọkunrin agbofinro naa tun ga ibọn lati pa oun.

Ọna lati fidi otitọ iroyin naa mulẹ lo mu ka kan si ẹni ti ọrọ naa kan, Yinka Ayefele.

Nigba to n ṣalaye fun BBC News Yoruba bi isẹlẹ naa se waye, Ayefele ni lootọ ni isẹlẹ naa waye..

O si sọ bi oṣiṣẹ agbofinro NSCDC naa ṣe gba oun ni ẹ̀ṣẹ́, lasiko toun lọ si ode ere ni ilu Iloro-Ekiti, nipinlẹ Ekiti.

Yinka Ayefẹlẹ ṣalaye pe isẹlẹ naa waye bi oun ṣe pari ere tan, ti oun fẹ maa lọ, ni oun wa, gẹgẹ bi iṣe oun, lati fun awọn eeyan ni owo, paapaajulọ awọn agbofinro.

‘Osisẹ Civil Defence tọwọ bọ ferese ọkọ mi lati ja owo gba, o si sọ ẹsẹ si mi lẹnu’

“Mo ti fun gbogbo awọn olori awọn osisẹ alaabo to wa nibẹ lowo tan, titi kan awọn ẹṣọ ‘bouncers’ ati awọn ọmọ ita area boys.

Bi mo ṣe fẹ maa jade, ẹ si mọ pe ko si bi ẹ ṣe fun awọn areas boys yẹn lowo , to lee kari.

Se ni mo ma n sọ owo soke ki ẹnikẹni to ba le rii mu, ko muu."

Ayefele ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira toun fẹ da soke yii, ni oun ko dani lasiko ti oun fẹ jade nibi ode ere naa.

Ayefẹlẹ ni bi oun ṣe tẹ gilaasi ọkọ oun wa silẹ bayii, ni agbofinro Civil Defence naa ṣadede ki ọwọ bọ inu ọkọ oun, lati ja owo naa gba mọ oun lọwọ.

“Bi mo ṣe sọ pe ki lo fẹ fa gbogbo iyẹn? Ṣebi emi funra mi ni mo duro, lo ba sọ ẹṣẹ si mi lẹnu.

Mo wa sọ fun awọn ọmọ mi to wa ninu mọto pe wọn ko gbọdọ jẹ ko lọ.

A gbọdọ mọ ọfiisi wọn. Bo ṣe kẹ ibọn niyẹn to bọ siwaju mọto pe oun yoo yinbọn fun ẹnikẹni to ba sun mọ oun.”

Yinka Ayefele

Oríṣun àwòrán, Yinka Ayefele

‘Ọga Civil Defence ti wa bẹ mi, mo ti jami lori ọrọ naa’

Ayefẹlẹ ni gbogbo ẹnu oun n ṣẹjẹ pẹlu ẹṣẹ ti oṣiṣẹ sifu difẹnsi naa fun oun, to bẹẹ gẹ ti oun fi nilo lati lọ si ile iwosan lalẹ ọjọ naa, nigba ti oun de ilu Ado Ekiti.

Amọ ṣa, gbajumọ olorin naa ni ọga agba ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ekiti ti wa ba oun ni owurọ ọjọ keji ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lati bẹ oun.

O ni oun si ti jami lori sisọrọ naa sita fun ẹnikẹni, ki o to di pe awọn akọroyin to wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye gbe iroyin naa sita.

O ni wọn se bẹẹ nitori pe inu wọn ko dun si iṣẹlẹ naa.

“Mi o sọ fun ẹnikẹni nitori mi o fẹ ki awọn eeyan maa wo pe ṣe Ayefẹlẹ nikan naa ni nigba gbogbo.

Mi o jẹ ki wọn gbọ nile gan. Koda gbogbo awọn ọmọ mi ti wọn gbọ iroyin naa lori ayelujara ni wọn n beere pe Ọga, nnkan bayii ṣẹlẹ mo dẹ dakẹ.

Ọtọ ni eti ti ẹlomiran yoo fi gbọ ọ. Wọn le maa sọ pe Ayefẹlẹ fẹ salọ, ko fẹ fun wọn lowo ni. Eyi lo jẹ ki n fa a si kootu Ọlọrun.”

N ko tii fa ọrọ naa lọ sile ẹjọ bayii ṣugbọn mo ti fi to agbẹjọro mi leti – Yinka Ayefẹlẹ

Yinka Ayefele

Oríṣun àwòrán, Yinka Ayefele

Oludasilẹ ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ naa ṣalaye pe, oun ti fi ọrọ naa to agbẹjọro oun leti nitori ọjọ iwaju.

O fi kun un pe oun si jẹ ko di mimọ fun un pe, bi ohunkohun ba jẹyọ lọjọ iwaju, oun yoo maa mọ ohun to kan ni igbesẹ lati gbe.

“Ko nilo ki eeyan maa gbe ẹnikẹni lọ sile ẹjọ lori rẹ. Osisẹ naa nikan lo da ṣe nnkan yii.

Ẹru kan lo maa n mu ni bu igba ẹru. Awọn ọga rẹ ko ran an ni iṣẹ to jẹ yẹn. Awọn akẹgbẹ rẹ gan ko mọ pe o hu iwa yii.”