Sunday Igboho kéde ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn ìdájọ́ iléẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_Igboho1/Instagram

Eekan ajafẹtọ ọmọ Yoruba to tun jẹ aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti sọ pe oun yoo gba ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun.

Igbesẹ naa lo da lori idajọ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ eyi to fi wọgile ogun billiọnu naira tile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo pasẹ fun ileesẹ agbofinro DSS lati san fun.

Owo ọhun ni owo gba ma binu lori awọn dukia Sunday Igboho, ti awọn osisẹ DSS to ya bo ile rẹ nilu Ibadan bajẹ.

Adajọ Muslim Hassan, lo ka idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lọjọ Isẹgun lori ẹjọ ti DSS ati agbẹjọro agba Naijiria pe tako idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ naa.

Idajọ ẹlẹyamẹya ni ile ẹjọ kotẹmilọrun da fun Sunday Igboho - Alliyu

Onidajọ Hassan ni lootọ loun gba pe wọn ba ile Sunday Igboho jẹ, ti wọn si pa eniyan.

Amọṣa, o ni ko si odiwọn ti ile ẹjọ naa lo lati fi bu iye owo naa fun un.

Bẹẹ lo ni ko si ẹri iwadi ayewo oku lati sọ pe awọn agbofinro DSS lo pa awọn meji ti wọn pa nibẹ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro fun Sunday Igboho, amofin agba, Yomi Alliyu SAN woye pe idajọ ẹlẹyamẹya ti ko lorukọ miran ju idajọ beriberi lọ.

Aworan ile Sunday Igboho lẹyin ikọlu
Àkọlé àwòrán, Aworan ile Sunday Igboho lẹyin ikọlu

Amofin agba Yọmi Alliyu ṣalaye pe adajọ sọ pe “lootọ oun rii pe wọn ba nnkan jẹ nile Sunday ṣugbọn ko lẹtọ si owo kankan.

Ṣe ori bibẹ logun ori fifọ ni? Bi awọn ọlọpaa ba fẹ mu eeyan, ṣe agogo kan oru ni wọn maa n mu u?

Adajọ naa tun ni Sunday Igboho ko mu ẹri ayẹwo oku wọn wa nipa awọn eeyan ti wọn pa nibẹ.

Se ayẹwo oku ti wọn ti gbe lọ. Ta lo fẹ ṣe ayẹwo oku nigba ti oku yẹn ṣi wa lọwọ DSS di aarọ yii?

DSS ko si ṣẹ pe awọn ko gbe awọn oku naa lọ.”

Amofin agba naa ṣalaye pe idajọ ‘o gbẹjọ apa kan, dakan si ni’.

“Idajọ ẹlẹyamẹya ni. Emi o sọ nipa ede tabi ẹya, bi ko ṣe idẹyẹsi.”

‘Idajọ naa ko ba Sunday Igboho lojiji’

Aworan Sunday Igboho ati ọta ibọn to ni wọn yin lasiko ikọlu si ile oun
Àkọlé àwòrán, Ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ko si idi fun ile ẹjọ giga lati ni ki DSS san owo itanran ogun biliọnu naira fun Sunday Igboho

Amofin agba Yọmi Alliyu SAN ṣalaye pe idajọ naa ko ba Oloye Sunday Igboho lojiji rara.

O ni o ti pẹ ti igun agbẹjọro fun Igboho ti n ri iha ti awọn adajọ to gbọ ẹjọ naa kọ sii.

“Adajọ naa ni oun faramọ koko ipẹjọ kotẹmilọrun ti wọn pe, amọ nigba to si n sọrọ, ohun ti awọn wọnyẹn sọ, ni oun naa n sọ sita, ko ka esi tiwa.

Afi bi pe awa gan ko tilẹ sọrọ nibẹ rara. Ṣe awa o wa sile ẹjọ ni?"

Yomi Alliyu ni idajọ naa ko jọ awọn loju, oun si ti ṣe sọ fun adajọ naa pe tiẹ lo sọ yẹn.

O wa sọ yanya pe Sunday Igboho yoo tun gbe ẹjọ naa lọ sọdọ awọn adajọ to tun ga ju u lọ fun idajọ ododo.

 Mo ti sọ fun awọn alatilẹyin ipe fun idasilẹ Oodua Nation lati maṣe da omi alaafia ru nitori idajọ naa

Sunday Igboho nibi iwọde ita gbangba Yoruba nation nipinlẹ Ọṣun
Àkọlé àwòrán, Sunday Igboho nibi iwọde ita gbangba Yoruba nation nipinlẹ Ọṣun

Amofin Alliyu tun sọrọ lori awọn ọmọlẹyin ẹgbẹ to n pe fun Yoruba Nation kan, ti wọn n kọkọ fẹ wọde lati fi ẹhonu han lori idajọ naa lọjọ Iṣẹgun.

Agba amofin naa ṣalaye pe oun ti ba amofin wọn sọrọ pe ko ko wọn ni ijanu nitori pe Yoruba kii ṣe onijagidijagan.

O ni ko si igba kankan ti Sunday Igboho fi ọrọ jagidjagan tabi rogbodiyan ṣeto ipe to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Nitori naa, o ni ko si ẹnikẹni to gbọdọ fi rogbodiyan kun ọrọ rẹ.

Oloye Yomi Alliyu SAN nibi igbẹjọ ori ayelujara

“Gbogbo ibọn ti wọn ni awọn ri ni ile rẹ, a fi to ile ẹjọ leti nigba naa pe ibọn yii wọn ti lo o lọdun marun un sẹyin ni.

DSS ko dẹ jiyan rẹ pe ibọn yii, awọn lọ kaa nibi kan ni, kii ṣe ile Sunday Igboho lawọn ti rii.”

O ni iran Yoruba kii pa ara wọn tabi ṣa ara wọn lọgbẹ nitori iran ọlọpọlọ pipe ni Yoruba jẹ.

Sunday Igboho ko si lo ilana rogbodiyan tabi yọ ada- y’ọbẹ lati fi yanju ọrọ tire.