Eji Gbadero: Ó pa Raji Oba nítorí ilẹ̀ nìjọba bá yẹgi fún un

Eji Gbadero

Oríṣun àwòrán, Others

Yoruba ni aye ko tọ lọ bii orere, igba ko si tọ lọ bii ọpa ìbọn, gbogbo alagbara aye si lo yẹ ko rọra ṣe nitori ilẹ n yọ.

Ni ojumọ toni to mọ yii, ọpọ alagbara aye lo wa, ti wọn n jẹ aye familete ki n tutọ, wọn ni awọn lo ni oni, lai mọ ẹni ti yoo ni ọla, ti wọn si n jẹ aye ọlọba.

Boya ọlọkọ ero ni ẹ ni, abi ọmọ onilẹ, baba isalẹ oloselu ni ẹ ni abi agba janduku, ẹ ko ṣe fi igbe aye awọn alagbara aye to ti kọja lọ kọgbọn ati atubọtan wọn.

Ọkan lara awọn ajunilọ, tii fi ọwọ ọla gba ni loju ni ọkunrin kan nilu Eko, ti ọpọ eeyan mọ si Eji Gbadero.

O lowo, o lọla, to si gbajumọ ni saa ọdun 1970 wa soke, bi igbe aye ati iku rẹ si ṣe lọ ree, gẹgẹ bi a ṣe ka a ninu awọn oniruuru akọsilẹ to wa lawọn oju opo itakun agbaye.

Àwọn ìtàn Mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibẹrẹ aye Eji Gbadero, Kiniun Mushin baba Moradewun:

Jimoh Isola Adeyemi ni orukọ abisọ ọkunrin ta n sọrọ rẹ yii, ti awọn inagijẹ rẹ si n jẹ Eji Gbadero, Kiniun baba Moradewun ati Kiniun Mushin, ṣe orukọ to ba wu ọmọ nii jẹ lẹyin odi.

Adugbo Ọja Ọba nilu Ibadan, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo tii se Eji Gbadero ti wa silu Eko, ọdọmọde si lo ti tẹle aburo baba rẹ wa gbe ni Eko, o kọ iṣẹ ọwọ, to si da Ileesẹ tiẹ naa silẹ to n ṣe èsó.

Eji Gbadero lowo lọwọ, o gbajumọ, ọmọ jaye-jaye ni, laarin ọdun 1960 si 1970 ni okiki rẹ lọ soke.

Eko kan, Gbadero kan ni, lọtun losi si ni awọn olorin maa n ki i, koda, Ebenezer Obey ati Yusuf Olatunji gan wa lara awọn olorin to kii.

Gbogbo eleyi si lo n fidi rẹ mulẹ nipa bi Ejigbadero ṣe jẹ ilumọọka si laye igba naa.

Niwọn igba to jẹ pe ọna kan ko wọ ọja, owo to n ri nidi èsó tita ko to na mọ fun Eji Gbadero, ó bẹrẹ si ta ilẹ, ra ilẹ, o n ta ile, ra ile.

Ko si si ẹni to lee gbe ina wo oju Kiniun baba Moradewun, ko ma ge ika jẹ ni igbẹyin.

Eji Gbadero ni olugbeja ẹni ti wọn ba gba ilẹ rẹ, tabi ẹni to fẹ fi tipa gba ilẹ lọwọ ẹlomiran, to fi mọ ipese aabo to peye fun awọn ilẹ ti ẹnikẹni ko le e gba, to si di ọrẹ ọlọpaa.

Koda, gbogbo ẹka agbofinro, awọn adajọ ati awọn Agbẹjọro ni ọrẹ Eji Gbadero nitori ojoojumọ ni wọn n gbe lọ sile ẹjọ.

Awọn eeyan yii si lo n se iranwọ fun Ejigbadero lati mọ ẹsẹ ofin ti yoo sọ fun Agbẹjọro rẹ pe ko fi daabo bo oun nile ẹjọ, lai jẹ pe o lọ sile ẹkọ nipa ofin.

Kiniun baba Moradewun n jaye ọlọba, kii ba ẹbi bọ nile ẹjọ afi are, ọrọ ti owo ba ṣe ti ni ọrọ Gbadero, ilẹ ni yoo gbe, koda, a le e pe Gbadero ni ofin funra rẹ.

Opopona Raji Oba

Oríṣun àwòrán, Others

Eji Gbadero fioa gba ilẹ onilẹ, wahala de:

Ni ọjọ kan lọdun 1975, Eji Gbadero ati awọn ọmọ ẹyin rẹ lọ san ilẹ nla kan to gbooro ni agbegbe Alumoso, ibẹ ko si tii laju nigba naa, inu abule ni. Ilẹ ti wọn san ọhun wa, o si kun fun koko ati obi.

Ni kete ti awọn ara abule naa si ri pe ọrọ aje awọn ni awọn kan n bajẹ yii, wọn ba kọju si Gbadero lati beere pe ki lo de, ti oun naa si da wọn lohun pe lati ọdun 1970 ni oun ti ra ilẹ naa pamọ.

Ṣe ni awọn ara abule yii la ẹnu sílẹ lai lee pa de mọ, nitori o han daju pe irọ ni Gbadero n pa.

Bẹẹ ni wọn n beere lọwọ rẹ pe, eelo lo ra ilẹ ọhun, lọwọ ta lo ti ra a, awọn eeyan wo ni ẹlẹri rẹ, ta si lo san owo ilẹ naa fun?

Ṣugbọn kaka ki Eji fun wọn lesi, yiyan lo n yan kiri lori ilẹ naa, ti awọn ara abule naa ko si jẹ ki wọn tẹsiwaju lati san ilẹ ọhun mọ,

Bẹẹ ni Gbadero ati awọn ọmọ ẹyin rẹ yi ẹsẹ pada, wọn kuro nibẹ, ti awọn ara abule si n pariwo le lori, bo ṣe n lọ.

Ṣugbọn agbo to fi ẹyin rin lọ, agbara lo lọ mu wa ni ọrọ Eji Gbadero, bẹẹ ni ko si igi kigi ti igbin rẹ tẹnu mọ, ti ko ni mu gun, ko si si ilẹ ti Gbadero ba nifẹ si, ti ko ni gba ni tipatipa.

Àkọlé fídíò, Pains and Pleasure Band: Ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tó ní ìpèníjà ojú ló jẹ́ Ẹnjiníà, atagìtá

Iku Raji Oba se okunfa isubu Eji Gbadero:

Awọn ara abule yii mọ pe Gbadero yoo pada wa, kiakia ni wọn si lọ fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Agege.

Bi wọn si de n de ibẹ, naa ni Gbadero yọ lẹyin wọn, ti oun naa wa fi ẹjọ sun ọlọpaa.

Amọ gbogbo igbiyanju awọn agbofinro lati yanju ọrọ yii ni pẹlẹ putu lo ja si pabo.

Ọkan lara awọn ara abule naa ni arakunrin kan ti wọn n pe ni Raji Oba, o mọ ọrọ sọ, to si laya bii Kinihun, ko bẹru Eji Gbadero rara, to si sọ bẹẹ loju rẹ.

Lọjọ kan ni Ejigbadero lọ si abule naa, to si wa ile Raji Oba kan amọ aya onitọun, to n jẹ Sabitu, lo kọkọ ri nigba to n bọ.

Sabitu sare lọ sọ fun ọkọ rẹ pe oun ma kofiri Gbadero ni aarin abule ni alẹ yii, ti ẹnu si ya onitọhun pe ki lo n wa nibẹ lọwọ alẹ.

Amọ bi wọn ṣe dakẹ, ti Sabitu wọle lọ, ni Gbadero yọ si Raji, to si da ìbọn bo o ni orí, bi iyawo Raji si ṣe sare bọ sita, lo ri akọyinsi Eji Gbadero ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ti wọn n sa wọnu igbo lọ.

Sabitu ri pe Gbadero wọ sokoto ati ẹwu oloyinbo, to si mu ìbọn dani.

Oun si lo kẹyin awọn eeyan to n sa lọ naa, ti Sabitu si n pariwo pe "Eji Gbadero mo ri ẹ o, ara abule, Eji Gbadero ti pa mi lọkọ ó."

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́

Ni ọjọ ti isẹlẹ yii waye gan ni Ejigbadero n se ikomọ ọmọ rẹ kan, eyi to fi ile pọn ọti, fi ọna ro ọka fun.

Ọdẹ alẹ tu asiri Ejigbadero ati bo se lọ sisẹ ibi:

Eji Gbadero wa loju agbo ayẹyẹ ikomọ rẹ, to si n ba ọpọ eeyan ya fọto loju agbo, asiko yii si ni awọn ara abule lọ sọ fun awọn ọlọpaa Alimoso pe Eji Gbadero ti pa Raji Oba.

Oju agbo si ni awọn ọlọpaa ti lọ mu pe ko yọju si agọ awọn, ti gbogbo alejo to wa nibi ikomọ naa si n gba ẹri Gbadero jẹ pe ko jade lọ sibi kankan lọjọ naa.

Igbẹjọ bẹrẹ, awọn ẹlẹri bii orisi mẹta jade lati abule Alimoso, ti wọn si jẹri pe gbangba ni awọn ri Gbadero lọjọ naa ni abule wọn pẹlu ọkọ Pijo 504 rẹ.

Koda wọn ni oun ati awọn gende to ko so sẹyin wa sibẹ ni, ti meji ninu wọn si ni awọn ri ìbọn lọwọ rẹ.

Ṣugbọn awọn ẹlẹrii Eji Gbadero naa tako wọn pe inu ile ni olujẹjọ naa wa, to n tọju awọn alejo rẹ níbi ayẹyẹ ikomọ jade rẹ.

Amọ bi irọ ba lọ titi fun ogun ọdun, ọjọ kan ṣoṣo ni otitọ yoo ba a.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ẹjọ Eji Gbadero. Ọpẹlọpẹ ọdẹ alẹ kan ni Ileesẹ Gbadero, to wa lara awọn ẹlẹrii, to tan imọlẹ si idi ọrọ yii.

Àkọlé fídíò, Badagry ní ogún àjogúnbá tó pọ̀ yàtọ̀ sí òwò ẹrú

Kehinde Yekini ni orúkọ ọdẹ alẹ naa, to si jẹri pe Eji Gbadero wa si Ileesẹ rẹ ni alẹ ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 1975 naa.

Lẹyin naa lo morile Alimoso pẹlu Modina, Osadebey, Isiaka, Bakare, Wahab Oduntan ati Lukman, ti wọn si tun pada si Ileesẹ naa ni aago mẹsan alẹ.

Yekini fikun pe nigba ti wọn pada de lati Alimoso, Gbadero fa ìbọn yọ lati abẹ sokoto rẹ, to sì sọ fun oun pe oun Eji Gbadero ti pa ọkùnrin ti Kehinde kọ lati pa.

Adajọ ni ki wọn lọ yẹgi fun Ejigbadero, ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ:

Adajọ ri idi okodoro ọrọ, to si dajọ pe Eji Gbadero jẹbi ẹsun iditẹ lati pa eniyan ati ipaniyan, to si ni ki wọn lọ yẹgi fun, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

Gbadero pe ẹjọ kotẹmilọrun, ti awọn adajọ mẹta to gbọ ẹjọ naa si gba pe ko jẹbi ẹsun iditẹ lati pa eeyan amọ o jẹbi ẹsun ipaniyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbadero tun gba ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọ lọdun 1977, ti wọn si fa ẹjọ ọhun wọ ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹwa ọdun 1978, nigba ti idajọ waye pe lootọ ni Eji Gbadero jẹbi ẹsun ipaniyan.

Nigba to di ọdun 1979, eyiun ọdun mẹrin lẹyin ti Gbadero pa Raji Oba, ijoba yẹ igi fun oun naa, ti Kiniun baba Moradewun si dagbere fun aye pe o digbose.

Àkọlé fídíò, Toyin Ibietan: Àlòkù táyà ọkọ̀ ló mú mi rí nǹkan ṣe lásìkò ìgbélé COVID-19

Ẹkọ ti itan igbe aye Eji Gbadero kọ wa:

  • Ẹkọ akọkọ kọ wa pe ti aye ba yẹ wa tan, ka ma ṣe hu iwa ibajẹ.
  • Ẹkọ kejì ni pe ka ma gbe ara wa ga kọja ofin orilẹ ede wa nitori ọwọ palaba le segi ni ọjọ kan.
  • Itan aye Eji Gbadero tun kọ wa pe asegbe kankan ko si, aṣepamọ lo wa, nitori naa, ko yẹ ka maa gbe inu okunkun ṣe iwa ibi.