Alaafin: Wo arẹwà mẹ́jọ̀ tó ń ṣìkẹ́ Ọba Adeyemi

Awọn orekelẹwa ayaba Alaafin tilu Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Lamidi Adeyemi III

Alaafin tilu Ọyọ, ọba Lamidi Ọlayiwola Adeyemi kẹta ni awọn ọpọ ayaba ni iyẹwu, ti wọn rẹwa pupọ, ti wọn si wu oju ri.

Ta ba ni ka ka wọn mi meni, meji, awọn ayaba naa le ni mẹẹdogun , ti awọn to ti dagba laarin wọn si ti ni ọmọ-ọmọ ati arọmọdọmọ pẹlu.

Amọ lara awọn ayaba naa la ti ri awọn olo, ẹlẹjẹ tutu, apọnbeporẹ, orekelẹwa, ẹlẹyinju ẹgẹ, eyinfunjowo ati Ibadi aran, ti wọn jẹ mẹjọ, ti wọn maa n se idije lawọn oju opo ayelujara wọn, lati jẹ ki araye mọ pe ọla Alaafin ni awọn fi n yan.

Bakan naa ni awọn ayaba olo, ẹlẹjẹ tutu yii tun maa n se idije laarin ara wọn pe, ta ni afẹfẹ (Oxygen) ti Alaafin fi n mi laarin awọn?

Ọpọ awọn orukọ si ni wọn maa n pe ara wọn bii 'Ẹlẹ Daddy' abi 'Oxygen' Alaafin, ti ariyanjiyan si tun maa n wa lati mọ ẹni ti oriki naa tọ si.

Sugbọn iwadi BBC Yoruba fihan pe, ni aafin Ọyọ, awọn ayaba orekelẹwa yii le ni mẹjọ to jẹ afẹfẹ ti alaafin fi n mi, ta a si tun le pe wọn ni Ẹlẹ Daddy, gẹgẹ bi wọn se n pe ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Diẹ nipa iroyin ọkọọkan wọn ree:

Olori Rukayat Abiodun Ajoke Adeyemi:

Ọba Lamidi Adeyemi ati Olori rẹ, Abiodun pẹlu ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Abbey Adeyemi Facebook

Olori Abiodun yii la lee pe ni iya awọn ewe ni aafin Ọyọ, eyi tums si alakoso awọn ayaba kekere to wa lẹyin rẹ.

Lati ori obinrin yii si ni awọn apọnbeporẹ wa, yatọ si awọn agbaagba olori to siwaju rẹ

Bi o tilẹ jẹ pe Olori Abiodun kii fi bẹẹ na oju opo ayelujara bii ti awọn olori to de lẹyin rẹ, sibẹ ara awọn olo, ẹlẹjẹ tutu ti Alaafin fi n gbe ẹmi ro ni.

Olori Aishat Folasade Adeyemi:

Alaafin ati olori Folashade Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Ayaba Folashade Adeyemi

Ayaba Folasade lo tẹle Olori Abiodun, ti oun naa si wa lara awọn ẹlẹ ẹlẹjẹ tutu, ti Alaafin fi n se afẹfẹ gbẹmiro ni Aafin Ọyọ.

Olori naa si jẹ ara awọn apọnbeporẹ Alaafin to gbajumọ ni aafin Ọyọ, paa paa nitori pe o tun bi ibẹta fun ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta.

Ọpọ eeyan lo tun maa n pe olori Folasade ni Iya Mẹta abi yeye Iṣẹṣe, to si mọ oriki awọn Alaafin to ti jẹ sẹyin ati ti ọkọ rẹ pẹlu.

Lasiko ti Alaafin ba n se ayẹyẹ, ni yeye iṣẹṣe maa n ki oriki naa lati da awọn alejo laraya.

Olori Badrat Olaitan Ajoke Adeyemi:

Olori Badrat Olaitan ati Oba Lamidi Adeyemi n sọrọ

Oríṣun àwòrán, queenola2 Instagram

Olori Badirat lo kọkọ pe ara rẹ ni afẹfẹ ti Alaafin n mi sinu, ti oloyinbo n pe ni Oxygen, oun naa si lo tun pe ara rẹ ni ẹlẹ Daddy .

A si le ni orukọ yii mọ lara nitori arẹwa ati ọmọde ni laarin awọn ayaba lode Ọyọ, to si jẹ aayo Alaafin laarin awọn ayaba.

Okunrin kan ati ibeji ọkunrin meji ni awọn ọmọ ti olori badirat bi fun ọba Adeyemi, ọdun 2018 si lo bi awọn ibeji naa.

Laipẹ yii ni awuyewuye kan waye pe ọba Fuji, Wasiu Ayinde Mashal n lo ifẹ ikọkọ pẹlu olori naa, amọ ti ayaba Badirat ti sẹ pe ko si ohun to jọ eyi rara.

Olori Memunat Omowunmi Adeyemi:

Oba Adeyemi ati Olori Memunat Omowunmi

Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one

Olori Memunat yii wa lara awọn ayaba ọba Adeyemi to gbafẹ, o lọyaya, to si ko ni mọra.

Ọrẹ timọ timọ ni olori Memunat ati olori Badirat, ki wọn to wọ aafin Ọyọ, ati lẹyin ti awọn mejeeji di ayaba tan.

Asọ ẹgbẹjọda si ni awọn mejeeji maa n wọ lasiko kan, eyi ti ko yọ awọn ayaba yoku silẹ nigba miran.

Olori Memunat ati Bairat Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Olori Memunat Adeyemi Facebook

Ọrẹ awọn olori mejeeji yii wọ debi pe wọn maa n ki ara wọn ni mẹsan-mẹwa ni lori ayelujara, ti wọn si tun dijọ n ta asọ ni.

Bakan naa, wọn tun se ọrẹ debi pe ọdun 2018 ni Badirat ati Memunat dijọ bi ibeji, tawọn ibeji Memunat si jẹ obinrin, ti oun naa ti bi ọkunrin fun Alaafin saaju awọn ibeji.

Olori Ganiyat Gloria Mojisola Adeyemi:

Oba Adeyemi ati Olori Mojisola pẹlu awọn ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, queenmoji_gloo Instagram

Mojisola naa wa lara awọn ẹlẹ daddy, atupa palọ ati 'oxygen' ti Alaafin fi n mi lode Ọyọ.

Mojisola bi ọmọbinrin kan ati ọmọkunrin fun ọba Adeyemi, to si tun daju yoo bi si.

Osu kẹta ọdun 2019 lo bi ọmọkunrin kan ti wọn sọ orukọ rẹ ni Khalid, ti ayaba yii kii si na oju opo ayelujara to bẹẹ.

Olori Mariam Adeyemi:

Oba Adeyemi ati olori Mariam

Oríṣun àwòrán, Mariam Jola Adeyemi Facebook

Ọpọ eeyan ni ko fi bẹẹ mọ nipa Ayaba yii nitori ko si lara awọn ayaba to saba maa n ta kangbọn lori ayelujara.

Sugbọn losu kẹta ọdun 2019, olori Mariam naa bi ọmọkunrin kan lẹyin ọsẹ mẹta ti olori Mojisola bimọ

Olori Anuoluwapo Adeyemi:

Oba Adeyemi ati Olori Mojisola

Oríṣun àwòrán, queenmoji_gloo Instagram

Ẹgan ni hẹẹ, olori Anuoluwapo naa rẹwa lobinrin, ti ko si se fi ọwọ rọ sẹyin laarin awọn ẹlẹ Daddy to wa ni aafin Ọyọ.

Anuoluwapo si ni aayo ati ẹyinju Alaafin ko to gbe iyawo le e.

Asiko kan tiẹ wa to se ọjọ ibi, ti oun ati Alaafin dijọ n gbe ife ọti si ara wọn lẹnu, to si fesi loju opo ayelujara pe "Ta ni ẹlẹ daddy ati oxygen ti Alaafin fi n mi bayii?"

Oba Adeyemi ati Olori Aanu

Oríṣun àwòrán, queen_aanu

Ọrọ yii si lo daju pe o fi n fesi pada fun Olori Badirat, to kọkọ pe ara rẹ ni ẹlẹ Daddy ati oxygen ti ọba Adeyemi fi n mi, eyi to kọ bi akọle sabẹ aworan kan ti oun ati sba naa dijọ ya.

Ọmọkunrin kan ati ọmọbinrin kan si ni olori Anuoluwapo bi fun Alaafin lọwọ lọwọ bayii.

Olori Damilola Adeyemi:

Damilola Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Damilola Adeyemi

Olori Damilola ni iyawo kekere laarin awọn arẹwa Alaafin bayii, oun si ni oju baba ati afẹfẹ tuntun ti Alaafin n mi simu.

Osu keji ọdun 2020 si ni olori Damilola bi ọmọkunrin tuntun fun Alaafin Ọyọ.