Alaafin: Kabiyesi ẹ má bínú, àìmọ̀ lo fa ìgbésẹ̀ mi, n kò takò yín - Makinde bẹ Alaafin

Gomina Makinde n ki alaafin ọyọ

Oríṣun àwòrán, others

Bi wọn ba n sọ nipa awọn ọba alade ti ko ṣee maa fi ọwọ rọ sẹyin nilẹ Yoruba, orilẹede Naijiria ati agbaye, ọkan gboogi ni alaafin ilu Ọyọ jẹ ko si si ijọba kan to n ko iyan rẹ kere.

Eyi gan lo faa ti ahesọ iroyin nipa aawọ laarin oun ati gomina ipinlẹ Ọyọ lori idasilẹ ọwọ ẹka ọlọpaa kogberegbe Police Mobile Squadron si ilu Agọ Arẹ fi jẹ eyi ti ọpọ ko lee fi oju fo da.

Amọṣa Ọbalaye naa, iyẹn Kabiyesi Iku baba yeye, Ọba Adeyẹmi Alaafin ti ṣalaye ọrọ pe ko si ija laarin oun ati gomina Makinde lori iṣẹlẹ naa.

Alaafin sọ ọrọ yii nigba ti gomina Makinde bẹẹ wo laafin Ọyọ lasiko irinajo rẹ si ilu Iṣẹmbaye naa lati ṣi awọn akanṣe iṣẹ ti wọn fi n sọri ọdun kan iṣejọba Makinde gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọyọ.

Alaafin Ọyọ ni imulẹ nla lo n bẹ laarin oun ati Gomina Seyi Makinde, nitori naa ko si ohun to lee fa ikunsinu laarin oun ati gomina naa.

O fi kun un pe oun kuro lara awọn ọba ti yoo maa ba awọn to ba wa nipo iṣejọba ta kangbọn nitoripe oun ko si lati maa tabuku tabi fi ẹrẹ yi awọn to ba wa nipo aṣẹ lara.

Gomina Makinde ati alaafin ọyọ n fọrọjomitoro ọrọ

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

"Ko si aawọ laarin emi ati gomina. Bi eeyan ba ni ọgbọn ti o si kawe, iru eeyan bẹẹ yoo ms bi a ti n ba awọn to ba wa nipo alaṣẹ ṣe pọ"

Iku Baba yeye, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta ṣalaye lori ohun to ṣẹlẹ nipa ti ọrọ idasilẹ ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa kogberegbe naa. O ni oun ko ni ikunsinu kankan si gomina Makinde lori bi o ṣe ni ki ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria o gbe ọwọ naa lọ si Agọ arẹ dipo ilu Ọyọ ti alaafin n ja fun.

Saaju si ni Alaafin ti kọ orisirisi lẹta bii mẹta si ọga agba patapata fun Ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, to si n beere pe oun n fẹ ẹka ibudo ọlọpaa kogberegbe (MOP 73) nilu Oyo, eyi ti aarẹ Muhammad Buhari ti fi ontẹ lu.

Lẹta ti Alaafin Ọyọ kọ nipa agbekalẹ ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa kogberegbe si ilu Ọyọ

Oríṣun àwòrán, oyo insight

Esi lẹta fun agbekalẹ Ileesẹ ọlọpaa kogberegbe naa silu Oyo lo de ni ọjọ kẹtala osu kinni ọdun 2020 pe ijọba ti fọwọsi pe ki wọn gbe Ileesẹ ọlọpaa kogberegbe naa silu Oyo ati ilu mẹfa miran ni Naijiria.

Alaafin si tun kọ lẹta miran ni ọjọ kẹrinla osu keji ọdun 2020 lati dupẹ lọwọ ijọba, ni pe o seun lori bibuwọlu agbekalẹ Ileesẹ ọlọpaa naa.

Amọ lasiko ayẹyẹ ọdun kan rẹ lori aleefa ni Gomina Makinde lọ si Ileesẹ ọlọpaa kogberegbe naa nilu Agọ Arẹ to wa ni agbegbe Oke Ogun, eyi to bi awọn ọmọ Oyo, Alaafin ati Oyomesi ninu.

Àkọlé fídíò, Ki lo fa Ija lọbalọba ni ilu Iwo

Nigba to fi atẹjade sita lori ọrọ yii, akọwe eto iroyin si gomina, Taiwo Adisa ni irọ gbuu ni pe ilu Oyo lo yẹ ki Ileesẹ ọlọpaa naa wa nitori Makinde lo kọ lẹta lati beere fun Ileesẹ ọlọpaa naa, ti ọga agba ọlọpaa si fi ontẹ lu u pe ko wa nilu Agọ Arẹ, ti wọn si lo Ileesẹ asesiga ìjọun lati bẹrẹ Ileesẹ ọlọpaa naa.

Yoruba ni bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ ni ẹbi kii pẹ lori ikunlẹ, idi ree ti gomina Seyi Makinde fi n rawọ ẹbẹ si Alaafin pe ko ma binu, ko fi ọwọ wọnu.

Lẹta ti Alaafin Ọyọ kọ nipa agbekalẹ ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa kogberegbe si ilu Ọyọ

Oríṣun àwòrán, oyoinsight

Gomina Seyi Makinde rawọ ẹbẹ naa lasiko to lọ silu Oyo lati si ibudo ilera alabọde kan nilu Oyo, ti Alaafin tilu Oyo, ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta si gbalejo rẹ .

Ninu ọrọ rẹ si ni Gomina Makinde ti rawọ ẹbẹ si Alaafin pe ko jẹ eburẹ lori bi oun ṣe gbe ibudo Ọlọpa kan lọ si agbegbe Oke Ogun dipo ko wa nilu Oyo gẹgẹ bi Alaafin ti n fẹ.

Lẹta ti Alaafin Ọyọ kọ nipa agbekalẹ ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa kogberegbe si ilu Ọyọ

Oríṣun àwòrán, oyo insight

Gomina Makinde sọ fun Alaafin pe ko ma binu nipa ọrọ naa, oun ko mọ rara pe ọba naa ti gbe igbesẹ saaju nípa kíkọ lẹta lori ọrọ yii.

"Kabiyesi, n ko mọ pe ẹ ti kọ lẹta kankan nitori lati oṣù kẹsan-an ọdun 2019 ni ọga agba olopaa ti pàṣẹ pe ki wọn gbe Ileesẹ ọlọpaa kogberegbe ọhun wa si agbegbe Oke Ogun lati pinwọ iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran miran.