Ilé ẹjọ́ fún Naira Marley àti Sam Larry ní béèlì lórí ìgbẹ́jọ́ Mohbad

Naira Marley àti Sam Larry

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ilé ẹjọ́ Májísíréètì kan tó wà ní Yaba, ìpínlẹ̀ Eko ti fún gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé, Azeez Fashola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Naira Marley àti Sam Larry ní béèlì ogún mílíọ̀nù náírà.

Naira Marley, Sam Larry àtàwọn méjì mìíràn ni wọ́n wọ́ lọ sílé ẹjọ́ ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 tí ilé ẹjọ́ sì jù wọ́n sí àhámọ́.

Ikú gbajúmọ̀ olórin Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad ni wọ́n ń jẹ́jọ́ lé lórí.

Adájọ́ Adeola Olatunbosun sọ fún àwọn olùjẹ́jọ́ náà láti fi ìwé ìrìnnà wọn kalẹ̀ fún ilé ẹjọ́ kí wọ́n sì máa yọjú sí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn ní àgọ́ ọlọ́pàá Panti.

Ó ní Naira Marly àti Sam Larry pèsè onídùró mẹ́ta tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì gbọdọ̀ ní ogún mílíọ̀nù náírà nínú akoto owó wọn.

Olatunbosun tún ṣèkìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ kàn sí òun lórí ìgbẹ́jọ́ náà.

Ó ní òun máa gba ohùn ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ tí òun sì ma wá gbé sí etí ìgbọ́ gbogbo ènìyàn.

Ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni adájọ́ tún sún ìgbẹ́jọ́ mìíràn sí.

Naira Marly àti Sam Larry kò ní àǹfàní láti rìnrìnàjò lọ sí ibikíbi títí ìgbẹ́jọ́ máa fi parí gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ṣe sọ

Naira Marley ati Sam Laary wọ́ ọlọ́pàá àti Adájọ́ lọ kọ́ọ̀tù, bèèrè fún ogójì mílíọ̀nù

Aworan Naira Marley ati Sam Larry

Oríṣun àwòrán, Naira Marley ati Sam Larry/Instagram

Gbajugbaja olorin takasufee nni, Azeez Fashola ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Naira Marley ati ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ, Samson Eletu ti awọn eeyan tun n pe ni Sam Larry ni wọn ti jọ wọ ileeṣẹ ọlọpaa ati Onidajọ ile-ẹjọ Maijisireeti, Adeọla Ọlatunbọsun lọ sile-ẹjọ.

Naira Marley ati Sam Larry ni wọn n beere fun ogoji miliọnu naira gẹgẹ bi owo itanran lori bi wọn ṣe n tẹ ẹtọ wọn mọlẹ lọna ti ko ba ofin mu.

Gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ iroyin amohunmaworan ti Channels ṣe gbe e jade, wọn ni ile-ẹjọ giga apapọ, Federal High Court to wa niluu Ekoo ni awọn mejeeji gbe ẹjọ naa lọ.

Ẹsun ti Naira Marley ati Sam Larry fi kan ọlọpaa ati Onidajọ Ọlatunbọsun ni pe wọn ṣi tẹsiwaju lati ti wọn mọle lori ẹsun wi pe wọnmọ nipa iku Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrin oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni Onidajọ Ọlatunbọsun paṣẹ pe ki Naira Marley ati Sam Larry wa ni atimọle ọlọpaa fun ọjọ mọkanlelogun lati fi ṣe iwadii lori iku Mohbad, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Channels jẹ ko di mimọ pe agbẹjọro Naira Marley ati Sam Larry, Amofin agba Ọlalekan Ojo sọ pe ọjọ mọkanlelogun ti Onidajọ Ọlatunbọsun paṣẹ rẹ lati lo ni ahamọ ọlọpaa to wa ni Panti, Yaba nipinlẹ Ekoo ti pe, sibẹ wọn ko fi awọn mejeeji silẹ.

Ojo sọ pe eyi ko ba oju mu to labẹ ofin ẹtọ ẹni, to si ni bi ẹni pe niṣe ni wọn n fi ẹtọ awọn eeyan naa dun wọn.

Siwaju sii lo sọ pe awọn n pe fun aṣẹ lati fi awọn mejeeji silẹ, gẹgẹ aṣẹ ile-ẹjọ lọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.