Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún 6 àti 9 dáná sun ilé ẹ̀kọ́ wọn ní ìpínlẹ̀ Ogun, wọ́n dèrò àgọ́ ọlọ́pàá

Omolola Odutola

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Kayeefi ni ọrọ awọn ọmọdekunrin meji kan tọjọ ori wọn ko ju mẹfa ati mẹsan-an lọ lẹyin ti wọn sọ ina sinu ọgba ile ẹkọ wọn.

Akẹkọọ ile ẹkọ Community Primary School, Iṣẹri Ọlọfin, nipinlẹ Ogun, lawọn ọmọde naa n lọ tẹlẹ ki wọn to jo ile ẹkọ naa kanlẹ pẹlu awọn iwe.

Alukoro ilesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Omolola Odutola lo fidi iṣelẹ naa mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn akoroyin.

Odutola sọ pe ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni Wahis, ọmọ ọdun mẹfa ati Malik, ọmọ ọdun mẹsan-an wu iwa aburu yii.

Nigba to n gbẹnu awọn eeyan ni agbegbe naa sọrọ, ọkan lara awọn olugeb agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, aladugbo kan, Oloye Odutola sọ pe ohun ni ẹni to fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

Oloye naa lo ṣalaye, pe ọkan ninu awọn yara ikawe ti wọn ko ti paa lawọn afurasi naa gba wọle, ti wọn si lọ ko awọn iwe tawọn olukọ atawon akẹkọọ yooku ni nibẹ, ti wọn si sọna si i.

Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe wi, wọn lawọn ko ti i le sọ pe iye bayii ni owo awọn nnkan to bajẹ latara ina ojiji tawọn ọmọ naa sọ sile ẹkọ wọn, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa fi kun pe awọn ti ko awọn ọmọde meji naa sọdọ awọn fun iwadii lati mọ boya funra wọn ni wọn da iṣẹ aburu jẹ, abi boya awọn agbalagba kan lo kọ wọn lohun ti wọn ṣe.

SP Odutola pari ọrọ rẹ pe ọlọpaa ti bẹrẹ igbese lori ati kan si awọn obi awọn ọmọde wọnyi, nitori ọran nla lawọn ọmọ ọhun kora wọn si, awọn obi wọn si gbọdọ mọ si.