Mi ò gbìyànjú láti tàbùkù ẹnikẹ́ni, ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé - Olubadan

Oríṣun àwòrán, Others
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ti sọrọ lori iroyin kan to gba ori ayelujara lẹyin ti oun ati Alaafin ilu Oyo, Ọba Akeem Abimbola Owoade pade nibi eto kan.
Ṣaaju ni oniruuru ọrọ ti n lọ lori ayelujara lẹyin ti fidio kan ṣafihan bi Alaafin ṣe n nawọ si Olubadan nibi ayẹyẹ kan ti wọn ti pade amọ ti Olubadan ko wo ibẹ.
Ni ọjọ Aje ni fidio naa ṣafihan ibi ti Ọba Adewolu Ladoja ti jokoo si ẹgbẹ Alaafin ti ko si gba ọwọ́ ti Alaafin na si i lẹyin to jokoo tan, eyi to ti n mu ọpọlọpọ awuyewuye dani tawọn eeyan si n sọ pe Olubadan mọọmọ ni.
Amọ Olubadan ti wa sọrọ lori fidio naa to si sọ pe kii ṣe pe oun mọọmọ hu iwa naa.
Nigba ti o n sọrọ nibi ifọrọwerọ pẹlu ile iṣe iroyin kan niluu Ibadan, Ọba Adewolu Ladoja ṣalaye wi pe nisẹ ni awọn eeyan ko mọ oun to ṣẹlẹ ti wón si n fẹ ẹ loju ju bo ṣe yẹ lọ.
Ọba Ladoja ni eto ijọba ti awọn wa lo ṣokunfa iwa ti oun hu pee kii ṣe wi pe oun n ṣe afojudi si ẹnikẹni.
Olubadan ṣalaye wi pe ilana ti wọn gbe silẹ fun ijokoo ati aago ti ohun de sibi eto naa kopa ninu iṣẹlẹ ọhun nitori wi pe oun pẹ de eto adura naa ti oun si fẹ jókòó jẹ ki oun maa ba pin ipade naa si meji.
Olubadan ni "nigba ti mo de ibi ipade adura náà, aga ijokoo mi wa laarin Alafin ti ilu Oyo Ọba Akeem Abimbola ati Soun ti ilẹ Ogbomoso Ọba Ghandi Afolabi Olaoye.
Nigba ti ma a fi ki omina tan gbogbo awọn ori ade to wa nibi eto ọhun ni wọn ti jokoo, mo n gbiyanju lati jokoo jẹ nibi aga ti wọn pese fun mi ki wọn to dami duro nitori eto naa ti bẹrẹ.
O woye pe awọn fọnran to wa lori ayelujara ko ṣe afihan ootọ nipa ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa, nitori wi pe awọn to n pe lori ẹ̀rọ ayelujara gan lo fe da wahala silẹ.
"Mi o ro wi pe igbese mi lọjọ naa mu enikeni binu tabi tàbùkù ẹnikẹni, aafin Olubadan ti ṣalaye ni kikun bi iṣẹlẹ naa ṣe waye."
Ladoja ni "ohun to jẹ mi logun ju ni bi Ifọwọsowopo ati idagbasoke yoo ṣe wa laaarin awọn ọdọ ati bi igbelaruge lẹnu ẹkọ yoo ṣe gboro si ni ilu Ibadan."














