Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé obìnrin mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Oyo

Ayanlade Olayinka , alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Ayanlade Olayinka

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọwọ ti tẹ afurasi ajinigbe obinrin mẹta ni ilu Ikoyi Ile, to wa ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.

Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade ti alukoro wọn, CSP Ayanlade Olayinka fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Awọn afurasi yii ti orukọ wọn n jẹ Nurudeen Fathia, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, Fatai Taiwo, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati Munirat Saliu, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni ọwọ tẹ lẹyin akitiyan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.

Alukoro Ayanlade ninu atẹjade ọhun ṣalaye wi pe ọlọpaa ipinle Oyo gbe igbesẹ lẹyin ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Islamiat Omowunmi fi to awọn leti pe awọn afurasi yii n dunkoko mọ ohun.

Omowunmi to n ṣiṣẹ alapata tunbọ ṣalaye wi pe awọn afurasi wọnyii beere fun ẹya ara eniyan ati millionu mẹwaa naira lọwọ oun.

Nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn afurasi ajinigbe yii jẹwọ pe otitọ lawọn beere fawọn nnkan naa, amọ ere lawọn n ṣe.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Femi Haruna dupẹ lọwọ ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlopaa Naijiria IGP Kayode Egbetokun fun atilẹyin rẹ lati pese eto aabo to peye ni ipinlẹ naa.

O tun ṣalaye wi pe awọn yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Lẹyin naa ni ọlọpaa rọ awọn ara ilu lati maa fi ọrọ eto aabo agbegbe wọn to ileeṣẹ ọlọpaa leti paapaa julọ ti wọn ba fura si ẹnikẹni.

Mo máa ṣàbẹ̀wò sí mọ̀lẹ́bí àwọn aṣọ́gbó tí agbésùnmọ̀mí pa – Makinde

Ayajọ awọn ologun niluu Ibadan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti kẹdun pẹlu mọlebi awọn ẹṣọ asọgbo marun-un ti wọn padanu ẹmi wọn ninu igbo ijọba Ọyọ atijọ.

Gomina tun ṣe ileri lati ṣe abẹwo si igbo ijọba ti ipaniyan naa ti ṣẹlẹ ati agbegbe rẹ ni ọla Ọjọ-Ẹti.

Ọrọ yii lo jẹyọ nibi ayẹyẹ iranti awọn ologun Naijiria to waye ni papa iṣere Adamasingba, niluu Ibadan, lonii Ọjọbọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, alẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja lawọn agbebọn ya bo ọọfiisi awọn aṣọgbo ọhun to wa ni agbegbe Ọlọka, ni ijọba-ibilẹ Oriire, ti wọn si pa ẹṣọ asọgbo marun-un nibẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Makinde ṣalaye pe asiko yii ki ṣe asiko lati maa ti ẹbi si ara ẹni.

O salaye ni ijọba ipinlẹ ti gbe igbeṣẹ to yaranti lori eto aabo to munadoko lati ri wi pe ipinle Ọyọ wa ni alaafia.

Makinde to lu awọn ẹṣọ ologun Naijiria ni ọgọ ẹnu fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe, ṣalaye pe Naijiria n koju oriṣiriṣi ipenija lẹka eto aabo ni asiko yii.

O ṣe afikun pe ohun ti gba ijọba apapọ ni imọran lati fi kun igbiyanju wọn pe wọn si ti n gbiyanju agbara wọn nipa awọn igbesẹ to se koko.

O rọ awọn ologun lati ma tẹti lẹnu iṣẹ wọn, ati pe ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin fun awọn ẹṣọ naa.

Nigba to n ki awọn eniyan kaabọ sibi ayẹyẹ ọhun, alaga ẹgbẹ awọn ajagunfẹyinti ẹka ti ipinlẹ Oyo, Oloye Julius Alabi rọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ lati maa ran awọn opo, ati ọmọ ti awọn ẹṣọ ologun to padanu ẹmi wọn fi silẹ, paapaa julọ ni ẹka eto ẹkọ ati igbe aye to rọrun.

Oloye Alabi se afikun wipe ipinlẹ Oyo, ti gomina Makinde n se akoso rẹ n gbiyanju fun mọlẹbi awọn ẹṣọ ologun to ti papoda, ati awọn to ti fẹyinti nidi iṣẹ ọhun.

Orilẹede Naijiria ya ọjọ kẹẹdogun, Oṣu Kinni ọdọdun sọtọ lati maa ṣe iranti awọn ologun to ti fi ẹmi wọn jin fun orilẹede wọn.

Ayẹyẹ ìrántí àwọn ológun tó ṣubú lójú ìjà yóò wáyé káàkiri Nàìjíríà

Àwọn ológun méjì tó dúró wámú, tí fìlà àti bàtà àwọn ológun wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn. Àwọn ológun púpọ̀ wà lẹ́yìn wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni ayéyé ìrántí àwọn ológun tó ṣubú lójú ogun yóò tún wáyé káàkiri Nàìjíríà.

Ayẹyẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí ìjọba Nàìjíríà ṣe ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ jẹ́ láti máa ṣe ìrántí àwọn akọni tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn sójú ogun lásìkò tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin orílẹ̀ èdè wọn.

Onírúurú ọ̀nà sì ni àwọn ológun náà fi máa ń ṣe ìrántí àwọn akẹgbẹ́ wọn tó ṣubú lójú ogun.

Ní àyájọ́ yìí ni ààrẹ orílẹ̀ èdè àtàwọn gómìnà káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ tó so Nàìjíríà ró máa ń fi òdódó yẹ́ àwọn ológun náà sí.