Àwọn aráàlú ló ń kún àwọn agbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́ láti máa da ìlú láàmú - Mínísítà ààbò

Christopher Musa wọ aṣọ ológun, ó ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Mínísítà fétò ààbò Nàìjíríà, Christopher Musa ti sọ pé àwọn ohun èlò ìjà ogun tí Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ránṣẹ́ sí Nàìjíríà jẹ́ ojúná láti fòpin sí ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Musa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú BBC ṣàlàyé pé lára àwọn ohun èlò ìjà náà ló jẹ́ èyí tí ìjọba Nàìjíríà sanwó fún láti ọjọ́ pípẹ́, tí àwọn míì sì jẹ́ àjọṣepọ̀ orílẹ̀ èdè méjéèjì láti pọnkún ètò ààbò.

Ó ní àwọn ohun ìjà náà máa ṣe ìrànwọ́ gidi fáwọn ológun Nàìjíríà láti kojú ìgbéṣùmọ̀mí, ìjínigbé, àwọn agbébọn, àwọn ìwà kò tọ́ tó máa ń wáyé lẹ́nubodè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó fi kun pé ìjọba ń gbìyànjú láti mú àlékún bá akitiyan rẹ̀ nídìí ìgbógunti ìwà ọ̀daràn pẹ̀lú lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi kojú àwọn ìṣòro yìí.

Mínísítà ààbò náà wòye wí pé dídá ààbò bo àwọn ẹnubodè jẹ́ ohun kan tó ṣe pàtàkì púpọ̀ láti ṣe ìdádúró àwọn ọ̀daràn láti máa rí ààyè wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bó ṣe wù wọ́n.

"Ọ̀rọ̀ náà gba fífi ojú inú wò ó dáadáa, a nílò láti máa ṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ nítorí èèyàn nìkan kò lè ká ojú gbogbo ẹ̀.

"Ṣùgbọ́n lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ bíi sátẹ́láìtì, dúróònù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ yóò ṣe ìrànwọ́ púpọ̀. Owó ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìjà nítorí a kìí pèsè wọn níbí àmọ́ a ti ń gbìyànjú láti máa rà wọ́n."

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìbásẹpọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà pàápàá lórí ìkọlù tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ṣe sí Nàìjíríà láìpẹ́ yìí, Musa so pé ìbáṣepọ̀ tó dán ló wà láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì.

Bákan náà ló wòye pé ipa rere ni ìkọlù tí Amẹ́ríkà ṣe sí ikọ́ agbéṣùmọ̀mí Lakurawa ní ìpínlẹ̀ Sokoto ní ọjọ́ Kérésì.

"Ìkọlù náà jẹ́ kó yé àwọn agbébọn náà pé gbogbo ibi tí wọ́n wà ni à ń rí."

Ó wòye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkọlù náà kò ní ipa tó bẹ́ẹ̀, ó ní àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ti ń sá kúró ní agbègbè tí wọ́n wà, tí wọ́n sì ti ń sá padà lọ sí orílẹ̀ èdè Niger tí wọ́n ti yawọ ìpínlẹ̀ Sokoto padà.

"Díẹ̀ nínú àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ni wọ́n pa. Àwọn yòókù tí wọ́n móríbọ́ níbi ìkọlù ọ̀hún ni wọ́n ti ń sálọ padà sí orílẹ̀ èdè Niger tí wọ́n ti wá tẹ́lẹ̀."

Ó tẹ̀síwájú pé ààrẹ Nàìjíríà tún ti ń jíròrò pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè míì lágbàáyé láti ṣe àridájú rẹ̀ pé wọ́n ní àwọn ológun ní gbogbo ohun èlò tó yẹ kí ojú wọn le ká ilé àti oko pàápàá àwọn inú igbó táwọn agbébọn fi ń ṣe ibùgbé.

A ò ní dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí

Mínísítà fún ètò ààbò náà tún tẹmpẹlẹmọ pé ìjọba kò ní dúnàádùrà pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí tàbí àwọn agbébọn nítorí ìjọba kò fọwọ́ sí sínsan owó fáwọn èèyàn náà.

Ó ní gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ ni àwọn ń gbé láti ṣèkìlọ̀ fáwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìgbésẹ̀ náà yóò máa fún àwọn agbébọn náà ní àǹfàní láti túnbọ̀ máa ṣe iṣẹ́ ibi wọn lọ ni.

Ó fi kun pé àwọn ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti ri dájú pé ìgbáyégbádùn àwọn ológun ni awọn mú ní òkúnkúndùn àti pé kò sí ológun kan tó le sọ pé ìjọba ń fi owó oṣù tàbí àjẹmọ́nú dun àwọn mọ́ lásìkò yìí.

'Àwọn aráàlú ló ń kún àwọn agbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́ láti máa da ìlú láàmú'

Musa tún sọ pé lára ìpèníjà tó ń fa báwọn ajínigbé, agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí ṣe ń pọ̀ si kò ṣẹ̀yìn ìṣẹ́ àti òṣì tó ń bá àwọn èèyàn fínra, tó fi mọ́ àìní ìmọ̀ kíkún.

Ó ní inú ìdílé ni ọ̀pọ̀ ìpèníjà yìí ti ṣẹ̀ wá, tó sì rọ àwọn olórí ẹ̀sìn gbogbo, tó fi mọ́ àwọn orí adé ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ láti ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba lójúnà àti fòpin sí ìgbéṣùmọ̀mí.

Ó fẹ̀sùn kàn pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú ló ń ṣe agbódegbà fáwọn agbéṣùmọ̀mí àti ajínigbé nítorí àwọn ni wọ́n máa ń lò láti fi ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń fẹ́.

Ó ní yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n máa ń fún àwọn agbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́, àwọn ni wọ́n máa ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò bíi epo bẹntiróòlù, omi, oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

"Àwọn aráàlú ló lọ ń fún wọn ní epo tí wọ́n fi ń gun ọ̀kadà, wọn kìí lọ sílé epo. Àwọn èèyàn ló lọ ń ta omi, oúnjé àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń lò.

"Tí àwọn aráàlú bá kọ̀ láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn ó máa ṣòro fún wọn láti lè gbé ayé ìrọ̀rùn nínú igbó tí wọ́n wà."