Mò ń wá ọkọ, mo ti ṣetán láti fàyè gba ìfẹ́ nínu ọkàn mi – Princess Damilola

Oríṣun àwòrán, Princess Damilola
Oṣere ati adẹrinpoṣonu, Damilola Adekoya, ti ọpọ mọ si Princess ti kede pe oun n wa ọkọ, oun si ti ṣẹtan lati ni ololufẹ.
Princess lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ nibi to ti rawọ ẹbẹ si awọn gbajumọ pasitọ ni Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ lati mu afojusun ọhun ṣẹ.
Lara awọn pasitọ ti Princess rawọ ẹbẹ si ni Bolaji Idowu, Philip Olubakin, Jerry Eze, Joshua Selman, ati Femi Lazarus.

Oríṣun àwòrán, Princess Damilola
O ni ki awọn iranṣẹ Ọlọrun naa ran oun lọwọ lati wa ọkọ ninu awọn ṣọọṣi wọn.
Princess sọ pe oun ko ni ololufẹ kankan lọwọ yii, bẹẹ si ni oun ati ọkọ oun atijọ ti kọ ara wọn silẹ, nitori naa oun n fẹ ọkunrin tuntun mii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ti pẹ toun ti n gbadura ati aawẹ lati fọ ara oun mọ lati di eeyan ọtun.
O ni asiko adura ati aawẹ ti wa o si ti lọ, asiko lati ni ọkọ lo kan bayii.
Nigba to n darukọ awọn pasitọ naa, o ni wọn maa n gba awọn ọmọ ijọ wọn lamoran lati maa gbadura ki wọn si jẹ eeyan gidi, oun si ti ṣe bẹẹ.
Princess sọ pe oku ni igbagbọ lai si iṣẹ, oun ti ni igbagbọ fun ọkọ rere, amọ asiko ti to fun oun lati gbe igbesẹ wiwa ọkọ naa bayii.
Adẹrinpoṣonu naa rọ awọn pasitọ to darukọ ki wọn ran oun lọwọ lati pade awọn ọkunrin gidi ninu ijọ wọn ti ọjọ ori wọn le ni ogoji ọdun si nnkan bii aadọta ọdun ti wọn ti ṣẹtan lati gbe iyawo.
Nigba to n sọrọ lori ohun ti awọn eeyan yoo sọ, o ni ko yẹ ki awọn ti ko ni okọ tabi awọn to ti kọ ọkọ wọn silẹ maa tiju lati sọrọ soke pe wọn nilo ololufẹ.
O ṣalaye pe oun ko sọrọ soke nitori oun ti leelẹ, amọ oun sọrọ ohun to n dun oun lọkan to si mọmu laya oun.
Princess fi kun pe ko yẹ ki awọn eeyan maa tiju lati sọrọ ifẹ tabi igbeyawo nile ijọsin wọn.
O juwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni ti ọgbẹ ọkan rẹ ti san to si ti ṣetan lati tẹsiwaju ninu igbeaye rẹ lai wo ohun to si ṣẹlẹ sẹyin.
Gbajumọ ni Princess Damilola lagbo oṣere amọ ọpọ eeyan tunbọ mọ ọ si lasiko igbẹjọ Lanre 'Baba Ijesa' Omiyinka lẹyin ti Ijesa fọwọ kan ọmọ rẹ lọna aitọ.
Ọpọ eeyan lo fẹran rẹ lọdun naa lọhun fun bi ko ṣe ṣe ọrọ naa loku oru amọ awọn mii korira rẹ latari igbagbọ wọn pe ni ṣe lo fẹ mọọmọ ba aye Baba Ijesa jẹ.













