Kí ló ń fa ìdàrúdàpọ̀ lórí ìwé ìfisùn tí Nàìjíríà kọ nípa kíkópa DR Congo nínú ìdíje 2026, àti kí gan ni àjọ FIFA ń sọ nípa rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, NGSUPEREAGLES
Ni ana ode yii ni ajọ to n ri si ere bọọlu lagbaye kede sita pe orilẹede DR Congo ni yoo lọ soju ilẹ Afrika nini idije Fifa inter-confederation play off ti yoo waye ṣaaju idije ife ẹyẹ agbaye.
Bẹẹ ba gbagbe, DR Congo fiya jẹ ikọ Super Eagles ninu irufẹ idije yii to waye ni ilẹ Afirika, ti Super Eagles si pe ẹjọ tako DR Congo pe ọpọ awọn agbabọọlu wọn lo jẹ pe wọn ṣoju orilẹede meji lẹẹkan naa, eyi to lodi si ofin FIFA.
Ninu atẹjade FIFA, wọn ṣalaye pe awọ orilẹede mẹfa ti yoo ma koju ara wọn ninu idije FIFA inter-confederation ni Bolivia, Congo DR, Iraq, Jamaica, New Caledonia ati Suriname.
Ẹsun wo ni Naijiria fi kan Congo DR?
Ajọ NFF ni awọn agbabọọlu meji ti DR Congo fa kalẹ, ti wọ gba ifẹsẹwọnsẹ, iyun, Aaron Wan-Bissaka ati Axel Tuanzebe lo jẹ pe wọn jẹ ọmọ orilẹede Gẹẹsi to sọda si DR Congo, ti igbesẹ naa si tako ofin FIFA ati ofin DR Congo gan an nitori wọn iwe ilu meji.
Akọwe agba fun Ajọ NFF, Mohammed Sanusi ṣalaye iha ti orilẹede Naijiria kọ si ofin yii.
"Ofin Congo ni o le jẹ ọmọ ilu meji ṣugbọn awọn agbabọọlu wọn jẹ ọmọ ilu meji, ti wọn si tu ni paali iwe irinajo awọn ilu yii.
"Ohun ti a n sọ ni pe ọgbọn ijapa ni DR Congo lo fun FIFA lati mu wọn."
Ajọ to n risi ere bọọlu ni DR Congo tako eyi, ti wọn si fẹsun kan Super Eagles pe wọn fẹ lo ọna ẹyin lati lọ si idije ife ẹyẹ agbaye.
Ki ni ajọ FIFA sọ?
Ajọ FIFA fidi rẹ mulẹ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹjọ ti orilẹede Naijiria pe ṣugbọn wọn ko igba ti wọn yoo gbe idajọ sita.
Onimọ nipa ere bọọlu, Mamadou Gaye rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ṣe suuru, to si ran wọn leti ohun to waye pẹlu orilẹede South Afirika.
"A ni lati ṣe suuru, a mọ ohun to waye pẹlu orilẹede South Afirika, ti wọn si yọ ninu ayo lẹyi ti wọn ri pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn", Gaye sọ fun Super Sports.
N jẹ Super Eagles Naijiria si le lọ fun idije World Cup?
Gẹgẹ bii ajọ NFF ṣe ṣalaye, wọn ni ajọ FIFA ko ti gbe idajọ rẹ sita, to si jẹ pe o ṣeeṣe ki ikọ Super Eagles si kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026.
Agbẹnusọ ajọ NFF, Ademola Olajire sọ fun ileeṣẹ iroyin The Punch pe ajọ naa si n reti idajọ lati ajọ FIFA.
"A ko ti gba esi kankan lati ẹnu ajọ FIFA. Ko si iroyin ti a le fun awọn akọroyin lai ṣe pe a ti gba esi lati ẹnu FIFA.
"A si n duro, ẹ jẹ ki awọn to n gbe iroyin sita tẹsiwaju, ti wa ni pe a ko ti gba idajọ lọwọ ajọ FIFA."


























