Kí ló dé tí Iran fi ń ju àdó olóró sáwọn orílẹ́èdè mùsùlùmí tó wà ní àyíká rẹ̀? Ohun ti a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ija bẹ silẹ lẹyin ti orilẹede Amẹrika ati Israel ju ado oloro si Iran, eyi lo si jẹ ki Iran naa maa ju ado oloro sawọn orilẹede to wa layika rẹ.
Iran ti sọ ṣaaju pe awọn yoo gbẹsan ti Amẹrika ati Israel ba le ṣekọlu si orilẹede naa.
Amọ, dipo ki Iran maa ju ado oloro si Israel nikan, oniruuru ado oloro ni wọn ti ju si Doha, Abu Dhabi ati Dubai atawọn ilu mii to wa ni ayika wọn.
Bakan naa ni Iran tun ti na ọwọja ado oloro wọn de Kuwait City to fi de Manama ati Riyadh lorilẹede Saudi Arabia.
Orilẹede UAE ṣalaye pe eeyan kan padanu ẹmi rẹ nigba ti awọn ologun naa gbiyanju lati da ado oloro ti Iran yin pada.
Orilẹede Qatar naa sọ pe oun ti ja oriṣiiriṣii rọkẹẹti lulẹ loju ọrun.
Awọn orilẹede mii to wa ni ayika naa ti sọ pe oriṣiiriṣii ibugbamu lo ti ṣẹlẹ lọdọ awọn.
O kere tan, ibudo nnkan ijagun oloro mọkandinlogun ni orilẹede Amerika ni lẹkun Middle East.
Mẹjọ ninu awọn ibudo naa lawọn onwoye sọ pe yoo wa laelae lawọn orilẹede ti wọn wa bii Bahrain, Egypt, Iraq, Israel, Jordan, Kuwait, Qatar, Saudi Arabia, Syria, ati United Arab Emirates.
Ibudo nnkan ijagun oloro Al Udeid to wa ni Qatar ni ibudo nnkan ijagun Amẹrika to tobi julọ lẹkun Middle East.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmo Amẹrika lo wa nibẹ.
Bakan naa, ileeṣẹ ologun ori omi, US Navy's Fifth Fleet to maa n yika ọgbun, okun pupa ati okun Arabia wa ni Bharain.
Orilẹede UAE ti ṣapujuwe bi Iran ṣe n ju ado oloro sawọn orilẹede to wa ni ayika rẹ gẹgẹ bii nnkan to lewu gan an.
Tehran ti kilọ ni aimọye igba pe ti Amẹrika ba le tẹsiwaju pẹlu ikọlu wọn si Iran, wọn ni gbogbo ibudo nnkan ijagun Amẹrika to wa lagbegbe Middle East lawọn yoo ṣekọlu si.
UAE ni awọn mọ iru igbesẹ tawọn le gbe lori bi Iran ṣe n yin ado oloro kaakiri.
























