Ìkọlù Amẹ́ríkà àti Israel sí Iran ti gbẹ̀mì Ayatollah Khamenei lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún lórí oyè; kí ni ipa rẹ̀ nínú ohun tó fa ogun náà?

Ayatollah Ali Khamenei lọdun 2024

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ayatollah Ali Khamenei lọdun 2024
    • Author, Sam Woodhouse
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ayatollah Ali Khamenei ku lọjọ kinni ti ijọba ilẹ Amẹrika ati Israel bẹrẹ ikọlu si Iran.

Iku ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun to ti lo ọgbọn ọdun lori alefa naa ni ileeṣẹ iroyin ijọba Iran fidi rẹ mulẹ.

Lati ọdun 1979 ti awọn Musulumi Iran ti gba ijọba, adari meji pere ni wọn si ti ni.

Lasiko ijọba Khamenei, oun ni gbogbo agbara ileeṣẹ ọmọ ogun ilu wa lọwọ rẹ.

Lootọ ni kii ṣe Baṣorun Gaa, amọ o ni awọn agbara to pọ jọjọ fun ẹnikan ṣoso.

Pupọ ninu awọn ọdọ ni Iran ni ko mọ adari mii yatọ si oun.

Ayatollah Ali Khamenei ati obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ayatollah Ali Khamenei nikan lawọn ọmọ Iran mọ ni adari lati ọgbọn ọdun sẹyin

Ilu Mashhad ni wọn bi Ali Khamenei si lọdun 1939.

Oun ni ọmọ keji ninu ọmọ mẹjọ awọn obi rẹ ti wọn jẹ ogbontarigi ninu ẹsin Islam ti baba rẹ si jẹ alfaa Shia.

Pupọ ninu iwe to ka lojẹ keu ati imọ ẹsin Islam, o si di alfaa lọmọ ọdun mọkanla.

O jẹ ẹni to mọ ọrọ sọ gidi, o si darapọ mọ awọn to maa n tako Shah ti Iran – to jẹ ọba ti awọn Musulumi gba agbara lọwọ rẹ.

Fun ọpọ ọdun lo fi gbe ninu aja ilẹ ati ọgba ẹwọn. Igba mẹfa ọtọtọ ni ọlọpaa mu ti wọn si fi iya jẹ.

Khamenei nibi eto adura kan lọdun 1979

Oríṣun àwòrán, Gamma-Rapho via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Khamenei nibi eto adura kan lọdun 1979

Lẹyin ti awọn Musulumi gbajọba ni Iran, adari wọn nigba naa, Ayatollah Ruhollah Khomeini yan an lati maa dari irun ọjọ Jimọh.

Lọsẹ-ọsẹ ni waasi rẹ maa n kari gbogbo orilẹede Iran, eyii to sọ ọ di ọkan lara awọn alẹnulọrọ nibẹ.

Lẹyin oṣu diẹ, awọn janduku kan ti wọn jẹ akẹkọọ fasiti ya bo ọọfisi ijọba ilẹ Amẹrika nibi ti wọn ti di ọpọ eeayan ni igbekun fun ojilerin ati mẹrin ọjọ.

Iṣẹlẹ naa wa lara ohun to bẹrẹ aawọ laarin Iran ati ijọba Amẹrika ati bi awọn orilẹede mii lagbaye ṣe pa Iran ti.

Awọn ọmọ Amẹrika ti wọn di ni igbekun fun ọjọ 444 ni Iran lọpọ ọdun sẹyin

Oríṣun àwòrán, Bettmann via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ Amẹrika ti wọn di ni igbekun fun ọjọ 444 ni Iran lọpọ ọdun sẹyin

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awon kan gbiyanju lati gbẹmi Khamenei amọ o moribọ.

Igbiyanju naa mu ko lo ọpọ ọjọ nile iwosan, koda ọwọ ọtun rẹ ko ṣiṣẹ mọ titi di oni yii.

Ọdun kan naa ni wọn gbẹmi Mohammad-Ali Rajai ti Khamenei si gori alefa lẹyin rẹ.

Khamenei nile iwosan lẹyin ti wọn gbiyanju lati gbẹmi rẹ lọ 1981

Oríṣun àwòrán, Ayatollah Khamenei

Àkọlé àwòrán, Khamenei nile iwosan lẹyin ti wọn gbiyanju lati gbẹmi rẹ lọdun 1981

Lẹyin to gori alefa, o ja ọpọlọpọ ogun.

Ṣaaju ko to gori alefa ni Iraq ti kọkọ kogun ja Iran.

Ogun naa waye fun odidi ọdun mẹjọ, ọpọ awọn eeyan ilẹ naa lo si ba ogun ọhun lọ.

Ogun Iraqi ati Iran lọdun1980

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ogun Iraqi ati Iran lọdun1980

Ọmọ ogun Iraq lo ohun ija oloro kẹmika lati kọlu awọn abule Iran, bẹẹ lo ju ọpọ ado oloro si aarin ilu Tehran.

Ogun naa mu ki Khamenei tunbọ korira Amẹrika latari pe wọn ṣatilẹyin fun Saddam Hussein lati kogun ja orilẹede oun.

Lọdun 1989, igbimọ ilu buwọlu Khamenei gẹgẹ bii adari orilẹede naa tuntun.

Khamenei di adari Iran lẹyin iku Ayatollah Khomeini lọdun 1989

Oríṣun àwòrán, Hulton Archive via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Khamenei di adari Iran lẹyin iku Ayatollah Khomeini lọdun 1989

Laarin ọgbọn ọdun to fi wa lori oye, o ko ọpọ eeyan mọra ti wọn si n se tirẹ lai yẹsẹ.

Lọpọ igba lo maa n fi ọlọpaa mu awọn alatako rẹ to si maa n fi iya jẹ wọn lọna to lodi si ofin.

Kii rinrinajo lọ ilẹ okere, o yan lati maa gbe niluu Tehran pẹlu iyawo rẹ, ọmọ mẹfa ti wọn bi atawọn ọmọ-ọmọ rẹ.

Ayatollah Khamenei lori patako ajuwe

Oríṣun àwòrán, Hulton Archive via Getty Images

Ni Iran, o pa gbogbo awọn alatako lẹnumọ.

Lọdun 1999, awọn akẹkọọ fẹhonuhan, amọ o pana ifẹhonuhan ọhun.

Ọdun mẹwaa lẹyin naa ti awọn araalu ṣewọde lori esi ibo ti ko tẹ wọn lọrun, awọn agbofinro lu awọn oluwọde naa, bẹẹ ni wọn tẹ gaasi tajutaju si wọn.

Ni 2019, awọn araalu ṣewọde nitori owo epo gbowo lori, Khamenei pana iwọde naa ki kiakia.

Ni 2022, ọdọbinrin kan, Mahsa Amini, ẹni ọdun mejilelogun ku si ahamọ ọlọaa lẹyin ti wọn mu pe ko wọ ijaabu rẹ daada.

Ọrọ naa fa ifẹhonuhan laarin ilu, ifẹhonuhan ọhun le to bẹẹ ti agbofinro fi ṣekupa eeyan 550, ti awọn 20,000 mii si farapa, gẹgẹ bi awọn ajafẹtọ ọmọniyan ṣe sọ.

Ayatollah Khamenei lọdun 2024

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ayatollah Khamenei lọdun 2024

Nilẹ okere, wọn fẹsun kan an pe o n dari orilẹde ti ko ba awọn akẹgbẹ rẹ ṣe lagbaye.

Iran lo ẹgbẹ ọmọ ogun Hezbollah ni Lebanon lati maa kogun ja Israel.

Ohun kan gboogi to n fa ede aiyede laarin rẹ ati ijọba Amẹrika ni ohun ija oloro nuclear.

Ni ogun ọdun sẹyin, ọkunrin naa sọ pe ohun ija oloro nuclear lodi si Islam, amọ ogun ọdun lẹyin naa loun funra bẹrẹ si n ṣagbekalẹ ohun ija naa ni idakọnkọ.

Eyii lo mu ki awọn orilẹede to lagbara lagbaye bẹrẹ si n yẹra fun ti wọn si n fofin de e lori awọn nnkankan.

Ofin ti wọn fi de orilẹede naa mu ki nnkan nira fun ọpọ ọmọ orilẹede ọhun fun ọpọ ọdun.

Awọn alatilẹyin Iran ṣe iwọde lodi si Trump lọdun 2026

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn alatilẹyin Iran ṣe iwọde lodi si Trump lọdun 2026
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni Amẹrika ati Iran ti kọkọ buwọlu adehun kan lori ohun ija naa amọ Khamenei sọ pe Amẹrika le ma mu adehun naa ṣe.

Ni 2018, Trump yẹ adehun ti wọn ni, o si fofin de Iran lọna ati mu ki wọn ṣagbekalẹ adehun tuntun mii.

Ọdun meji naa ni Trump paṣẹ ki wọn gbẹmi Qase Soleimani, to jẹ ọgagun kan to sunmọ Khamenei bi iṣan ọrun.

Ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2025, ọmọ ogun Amẹrika kọlu ohun ija nuclear Iran, Iran si gbẹsan pada nipa sisọ ado oloro si Israel.

Bi Amẹrika ṣe n kọlu Iran yii, Khamenei sọ pe oun ko ni ju ọwọ silẹ.

Ninu oṣu Kinni ọdun 2026 awọn ọmọ Iran ṣewọde lori ọrọ aje ti ko ṣe dede, ijọba Khamenei fesi pẹlu ipa.

Awọn ajafẹtọ sọ pe olufẹhonuhan 6,488 lo ku nigba ti wọn ti oluwọde 53,700 mọle.

Lawọn ọsẹ diẹ si, Trump ni ki Khamenei jọwọ awọn ohun elo nuclear rẹ ko si tọwọ bọ adehun tuntun tabi ki oun kọlu u.

Amọ o kọ lati jọwọ awọn eroja uranium rẹ.

O sọ lasiko naa pe "Ki awọn ara Amẹrika mọ pe ti wọn ba bẹrẹ ogun, ogun naa yo jẹ ogun agbegbe."