Ìfìyàjẹni látọ̀dọ̀ àwọn òbí mi ni mo ka ètò ẹ̀kọ́ sí nígbà èwe mi, àmọ́ nísisìyí, mo ń k'àbámọ̀ pé mi ò kàwé – Sanyeri

Olaniyi Afonja

Oríṣun àwòrán, Olaniyi Afonja Sanyeri

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Olaniyi Afonja, ti ọpọ mọ si Sanyeri ti sọrọ lori ipele to ka iwe de ati iriri rẹ lasiko to bẹrẹ iṣẹ tiata.

Sanyeri, lasiko to n sọrọ lori eto "Behind The Fame", sọ pe lasiko ti oun wa ni kekere, oun ko mọ pe fun anfanin ara oun ni iwe kika jẹ, oun gbagbọ lasiko naa pe fun anfani awọn obi oun ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o gbagbọ pe ifiyajẹni lati ọwọ awọn obi ni iwe kika jẹ lasiko naa.

Sanyeri fidi rẹ mulẹ pe oun kabamọ pe oun ko kawe nigba ti oun ṣi kere amọ oun ti bẹrẹ igbesẹ lati pada kawe bayii.

O fi kun pe iwe kika ko ni gbedeke ke ọjọ ori, bẹẹ ni ẹnikeni lo le kawe lai wo ti ọjọ ori wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "Ti awọn ọmọde ba wa nile ẹkọ, wọn a maa ro pe awọn obi wọn ni iwe kika wa fun lai mọ pe fun ọjọ ọla wọn ni. Lasiko naa, mo ri bii ifiyajẹni lati ọwọ awọn obi mi.

"Mo kabamọ pe mi o tẹsiwaju ninu ẹkọ mi. Mo ti bẹrẹ igbesẹ lati kawe si, mo si maa fi esi rẹ han ti asiko ba ti to.

"Laye ode oni, ko si ọjọ ori ti eeyan ko le kawe."

Mi o bẹrẹ iṣẹ tiata pẹlu awada

Nigba to n sọrọ nipa isẹ tiata, Sanyeri sọ pe oun ko bẹrẹ ere pẹlu awada.

O ni oun ko oniruru ipa ninu ere ki oun to gbajumọ fun awada.

Oṣere naa ni awọn ọga meji ọtọtọ lo kọ oun niṣẹ ti wọn kii ṣe alawada amọ akitiyan wọn lori oun so eso rere.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, oloogbe Oluseyi Adeoye ati Hakeem Alimi Ajala Jalingo lo kọ oun niṣẹ titi ti oun fi di agba ọjẹ nidi iṣẹ tiata ni lonii.

Ki ni itumọ Sanyeri?

Nigba to n sọrọ lori bo ṣe bẹrẹ si n jẹ orukọ Sanyeri, o ni kii ṣe oun gan lo ni orukọ naa lati ibẹrẹ pẹpẹ, bi ko ṣe oṣere mii.

O ṣalaye pe oun ba ẹni naa ṣiṣẹ, o ṣi ṣe oun lanfan titi ti orukọ rẹ fi di ti oun.

Sanyeri sọ pe orukọ naa ni ipinlẹ to ṣe koko, o si kọja orukọ ori itage nikan ṣoṣo.

Orukọ naa ni itumọ to jinlẹ amọ ọpọ eeyan lo ti so oun ati orukọ naa pọ bayii, gẹgé bii ọrọ rẹ.