Agbébọn padà sí agbègbè Woro ní Kwara, gbẹ̀mí èèyàn, jí oúnjẹ, fóònù, àti nǹkan míì kó lọ

Agbebọn ti fi aṣọ bo oju rẹ

Oríṣun àwòrán, getty

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn agbebọn ti ṣe ikọlu si awọn ilu meji kan ni agbegbe Woro ni ijọba ibilẹ Kaiama ni ipinlẹ Kwara.

Lalẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji yii ni iṣẹlẹ to sọ awọn araalu si siba-sibo yii waye.

Ṣe ẹ ranti pe ilu Woro yii ni awọn agbebọn ya wọ lọjọ kẹta osu Keji ọdun yii, ti wọn si pa awọn araalu to lọ bii igba, ti wọn si tun ji ọpọ eeyan gbe lọ.

Awọn ilu meji ti wọn kọlu lọtẹ yii ni Gada Oli ati ilu kan lẹgbẹ Malale ni ijọba ibilẹ Borgu ni ipinlẹ Niger.

Iwadii BBC fihan pe bo tilẹ jẹ pe awọn ilu meji yii wa ni ipinlẹ to yatọ si ilu Woro, wọn o jina si rawọn rara, wọn si jọ maa n ni asepọ.

Bí ìkọlù sí àwọn ìlú náà ṣe wáyé

BBC News Yoruba kan si ọkan lara awọn ọdọ lu wọn ti a ko ni darukọ rẹ nitori aabo lori ago, o ni "Alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn agbebọn naa gun alupupu wọ inu ilu kan lẹba Malale, wọn si bẹrẹ si n yìnbọn.

"Mi o le sọ iye awọn agbebọn yii ni pato, amọ wọn pọ.

"Ohun to sẹlẹ ni pe, ara ti n kan awọn eniyan, wọn si ti mura silẹ fun nnkan ki nnkan to le sẹlẹ.

"Fun idi eyi, awọn eeyan ilu naa ti gbaradi, bi awọn agbebọn ṣe n yinbọ naa ni awọn ọdẹ ati fijilante ilu koju wọn, wọn si rọjo n yinbọ sira wọn.

"Awọn ọdẹ yii duro bi akọni pe kaka ti wọn o ji awọn eniyan wọn gbe lọ, awọn yoo ja pẹlu gbogbo agbara awọn.

"Igba ti oju ogun le, awọn agbebọn yii na papa bora, amọ, o ṣeni laanu pe awọn kan ku ninu awọn ọdẹ ilu naa.

"A o gbọ pe enikan ku lara awọn agbebọn ṣugbọn, wọn o le duro lati ṣe isẹ ọwọ wọn, ṣe ni wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ."

Àwọn agbébọn ya wọ Gada Oli nígbà ta kírun ásámú tan - Aráàlú

Ọkunrin naa tẹsiwaju pe, bi wọn ṣe kuro lẹba Malale tan ni wọn ya wọ ilu Gada Oli, wọn si n rọjo ibọn gẹgẹ bii iṣe wọn.

"Asiko yii jẹ bi ago mẹjọ abọ alẹ si mẹsan-an nitori a ṣẹ ki asamu tan ni.

"Bi awọn eeyan ṣe gbohun ibọ ni onikuluku fẹsẹ fẹ, lọrọ ba di ẹni ori yọ, o dile.

"Igba ti awọn araalu fi awọn ẹru wọn kalẹ ti wọn sa lọ tan, ni awọn agbebọn yii ba bẹrẹ si n ji wọn ko.

"Ni bi emi ṣe ro o, iṣesi awọn agbebọn yii jọ awọn ti wọn wa pa awọn eeyan ni Woro ti wọn si tun ji ọpọ eeyan gbe lọ.

"O ṣeeṣe ki ebi maa pa wọn, ki wọn si tun maa wa ounjẹ lati bọ awọn ti wọn ji ko.

"Nitori wọn ya wọ awọn sọọbu ounjẹ, ohun mimu wọn si di wọn lọ ni ọpọlọpọ.

"Wọn tun wọ sọọbu ẹrọ ibanisọrọ, wọn ko ọpọ awọn foonu ati awọn nnkan mii tí wọn nilo lọ.

"Ọkọ awọn soja meji lo kọja lọ sibẹ lati Wọrọ sugbọn awọn atilaawi yii ti palẹ awọn ẹru mọ, wọn si ti lọ ki wọn to de.

"Bi ọrọ ṣe ri niyi o, ki Ọlọrun saanu wa lagbegbe wa".