Wọ́n ṣa mi ní àdá lọ́pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n kò wọlé sí mi lára nítorí "Science" - Oyinkansola Elebuibon

Oyinkansola Elebuibon wọ aṣọ funfun ati dudu, o si jokoo

Oríṣun àwòrán, Oyinkansola Elebuibon/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oyinkansola Elebuibon, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ Araba awo ilu Oṣogbo, Ifayemi Elebuibon, ti sọ pe oun ko ba ti jẹ Ọlọrun nipe bi kii ba ṣe ọpẹlọpẹ ajẹsara.

Oyinkansola lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan to ti ṣe sẹyin pẹlu BBC Yoruba.

Gẹgẹ bo ṣe ṣọ, awọn janduku kan ṣa a ni ada lọpọ igba, ṣugbọn ada naa ko wọle si i lara.

Ṣaaju ni Oyinkansola ti kọkọ sọ ninu ifọrọwerọ naa pe ilẹ Amẹrika ni oun fi ṣebugbe bayii nitori awọn iṣẹlẹ to kan ṣẹlẹ si i nilu u Ibadan lọdun 2019.

Iṣẹlẹ naa jẹ eyii to gbomi loju Oyinkansọla, koda, bintin bayii lo ku ki omi bọ loju rẹ lasikọ to n ṣalaye ọrọ naa fun BBC Yoruba.

Oyinkansola ni "Alẹ ọjọ kan lẹyin ti mo ti ode ere de ni awọn kan wa da emi atawọn ọmọ to n gbe pẹlu mi mọle, wọn gba owo ati awọn nnkan miran lọwọ wa."

"Ṣugbọn nigba to ya, wọn ni ki n wọle sinu yara, mo si ṣe bẹẹ, lẹyin ti wọn ko awọn ẹgba ọrun tan ni wọn ba ni ki n dubulẹ sori ibusun ti mo si kọ."

Ninu alaye rẹ, o sọ siwaju si pe "Lẹyin ti mo bọ lọwọ wọn tan ninu ile ni mo ba ni ki n jade lẹnu ilẹkun nla to wọ inu ile ni mo to ranti pe mo ti ti ilẹkun naa pa."

"Bi awọn eeyan yii ṣe jade simi niyẹn ti wọn si bẹrẹ si n ṣa mi ladaa, ṣugbọn ko wọle, o kan fi apa diẹ simi lara ni."

O ṣalaye pe "ọpẹlọpẹ 'science' ni ko jẹ ki ada naa wọle simi lara, n o ba ti gba ibẹ lọ."

Ṣugbọn nigba ti atọkun BBC Yoruba bere pe ki lo n jẹ "science" ti Oyinkansola n sọ, lo ṣi aṣọ loju eegun pe oogun abẹnu gọngọ ni oun n pe ni 'science.'

Yatọ si eyii, Oyinkansola tun sọrọ nipa bi ere ori itage ṣe jẹ ajogun ba fun oun, ati bi ko ṣe ti oun loju lati jẹ onigabgbọ ninu ẹsin adayeba ilẹ Yoruba, paapaa Ifa Olokun asọrọ dayọ.