Kìí ṣe torí mo lówó ni Ooni ṣe fún mi ní oyè, wọ́n mọ rírì àwọn iṣẹ́ tí mo ti ṣe sẹ́yìn ni – Olayinka Latinwo
Yeye Bobagunwa Oodua, Olayinka Latinwo ti sọ pe ko si ohun to jọ pe oun joye latari pe oun jẹ olowo tabi ọlọrọ lawujọ.
Latinwo lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lẹyin ti Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, fi jẹ oye.
O ni "Kii ṣe tori ọla abi owo ti mo ni lo jẹ ki baba Ooni Ife fi mi jẹ oye Yeye.
"Iṣẹ riran eeyan lọwọ, iṣẹ ti Ẹlẹda ran mi ni."
Oloye ọhun sọ pe oun fẹran lati maa ran awọn alaini lọwọ, yala wọn jẹ opo ni o tabi ọmọ alaini tabi awọn arugbo.

Oríṣun àwòrán, Olayinka Latinwo
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn iṣẹ rere ti oun maa n ṣe lawujọ naa ni Ooni ri to si fi oun jẹ oye naa.
Yatọ si awọn ohun to maa n ṣe fun awọn alaini, o ni oun tun maa n tọju awọn lọbalọba naa pẹlu.
Ẹkunrẹrẹ oun ti Yeye Bobagunwa Oodua sọ wa ninu fidio oke yii.






