Àjọ NSCDC kẹ́dùn ikú òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ọkọ̀ tẹ̀ pa l'Abuja

Oríṣun àwòrán, ITV
Ajọ eleto abo NSCDC ti sọ pe oṣiṣẹ rẹ ti ọkọ gun ori rẹ kọja lasiko ti wọn n ṣe eto afihan agbara ni olu ọofisi ileeṣẹ naa niluu Abuja ti jade laye.
Agbẹnusọ ajọ naa, Babawale Afolabi sọ pe inu ajọ naa bajẹ gidigidi lori iku obinrin ọhun, ati pe iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣeto isinku to dara fun.
Afolabi fi kun pe ajọ naa ti ran awọn lọgalọga ninu ajọ naa si ile mọlẹbi oloogbe lati ba wọn kẹdun.
Bi iku obinrin naa ṣe aye
Ninu fidio to fi fa ori ayelujara ya lati ri bi iku obinrin ọhun ṣe waye lastiko ti wọn n ṣe afihan agbara.
Ninu fidio naa ni obinrin ọhun ti sun silẹ ti ọkan lara awọn ọkọ Hilux ajọ naa si ṣeṣi tẹ ori rẹ kọja loju gbogbo eeyan to wa nibẹ.
Fidio iṣẹlẹ naa ba ọpọ awọn to wo eto ọhun ninu jẹ, bẹẹ lo gba omi loju ọpọ awọn mii.
Agbẹnusọ NSCDC ni bo tilẹ jẹ pe oju ọpọ ero ni iṣẹlẹ naa ti waye, o ṣoro fun awọn lati sọ nnkankan nipa rẹ lai kọkọ bun awọn mọlẹbi ologbe gbọ.
Afolabi fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni iku oloogbe ọhun waye lasiko ti wọn n ṣe eto afihan agbara, kii si i ṣe igba akọkọ ti awọn yoo ṣe eto naa ree.
Bo tilẹ jẹ pe ko fi orukọ tabi iroyin mii nipa oloogbe ọhun lede, o ni eto naa ni awọn obinrin to wa ni ẹka Female Strike Force ajọ NSCDC maa n ṣe fun igbaradi ati idanilẹkọọ.
A gbọ pe lẹyin ti wọn yọ obinrin naa jade labẹ ọkọ to ṣeṣi gun ori rẹ lo han gbangba pe ko ni le ye iṣẹlẹ naa.
Wayi o, NSCDC ti ni oun yoo sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun lẹkunrẹrẹ laipẹ amọ awọn ti n mura eto isinku to jọju oloogbe naa.


























