Ilupeju Ekiti: Ìlú tí ọmọ bíbí rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣe oògùn owó
Ilupeju Ekiti to wa ni labẹ ijọba ibilẹ Oye, jẹ ọkan lara awọn ilu to ṣe pataki ni ipinlẹ Ekiti.
Ilu naa ni a gbọ pe ori oke nla kan wa to jẹ eyii to lagbara nibi ti ọpọ ọmọ ilu ọhun atawọn alejo mii ti maa n gbadura.
Orukọ apata naa ni wọn n pe ni Ewo.
Nigba ti BBC Yoruba ṣabẹwo si ilu naa, a ba awọn oloye rẹ sọrọ, wọn si ṣalaye bi itan okuta nla naa ṣe jẹ ati agbara to ni.
Lara nnkan ti wọn sọ fun wa ni pe ọmọ bibi Ilupeju Ekiti kii ṣe oogun owo, bẹẹ ni awọn ọmọ ilu ọhun kii toṣi.
Lara awọn oloye to ba wa sọrọ ni Ogunseyisi Ilesanmi ati Olaoye Oni, ti wọn sọ pe ẹni to ba n wa nnkan pataki yoo ri ti wọn ba le lọ gbadura lori oke ọhun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ati ọmọlẹyin Kristi, Musulumi atawọn ẹlẹsin mii lo n ṣabẹwo sibẹ fun adura, ti adura wọn si n gba.
Oloye Ilesanmi sọ pe "awọn ọmọ wa o ki n ṣe ogun owo nitori ti wọn ba ṣe oogun owo, wọn maa n ku ni.
"Ọmọ bibi Ilupeju ko gbọdọ ṣe oogun owo... ṣugbọn ọmọ bibi Ilupeju ko gbọdọ toṣi."
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti a ba bọ lati Ilupeju Ekiti.






