Ẹ wọ́gilé ìsìn ìṣọ́ òru nítorí ètò àbò tó mẹ́hẹ – Ọlọ́pàá Ondo kìlọ̀ fáráàlú

Oríṣun àwòrán, getty
Ileeṣẹ ọlọpaa ipijnlẹ Ondo ti rọ awọn adari ẹsin ki wọn wọgile isin iṣọ oru latari eto abo to mẹhẹ nipinlẹ naa.
Ọrọ yii ni wọn ni o kan awọn ṣọọṣi, mọṣalaṣi atawọn ẹlẹsin abalaye ti wọn maa n ṣe isin loru ọganjọ.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Adebowale Lawal lo fi imọran naa lede lọjọ Ẹti niluu Akure lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori awọn ọmọ ijọ CCC mẹfa ti awọn agbebọn ji gbe nibẹ.
Ọjọ karundinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025 yii lawọn agbebọn kan ji eeyan mẹfa gbe lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru ninu ile ijọsin wọn to wa loju ọna marosẹ ilu Uso si ilu Owo.
Ileeṣẹ iroyin NAN jabọ pe wọn doola awọn ti wọn ji gbe naa, ọwọ si tẹ afurasi kan lori iṣẹlẹ ọhun.
A gbọ pe awọn agbebọn naa sọ pe awọn yoo gba ọgọrun miliọnu naira fun itusilẹ awọn ọmọ ijọ naa.
Kọmiṣọna ọlọpaa sọ pe alaabo ara ati alaboyun kan wa lara awọn ti wọn ji gbe.
Ọlọpaa ni yoo rọrun fun awọn lati maa bojuto eto isin lọsan gangan ti awọn ile ijọsin naa ba pa isin iṣọ oru ti lasiko yii.
Lori ọrọ owo itusilẹ, o ni "Ko si ẹnikẹni to jade sita lati sọ ohunkohun nipa owo itusilẹ kankan.
"O ti pẹ ti a ti maa n sọ fun awọn adari ẹlẹsin ki wọn maa bun wa gbọ ti wọn ba fẹ ṣe isin pataki ki a le gba wọn niyanju boya ki wọn tẹsiwaju pẹlu isini naa tabi bẹẹ kọ.
"Eyii to ṣẹlẹ yii ko si ẹnikẹni to bun wa gbọ pe wọn fẹ ṣe isin kankan.
"Mi o mọ igba ti ile ijọsin di ibi ti wọn n bi ọmọ si tabi ile iwosan. Ti ẹnikẹni ba loyun, ile iwosan tabi ile agbẹbi lo yẹ ki wọn lọ.
"Amọ ṣa, a ti fi ọrọ ranṣẹ si awọn adair ẹlẹsin, yala Musulumi ni wọn tabi Ktistẹni tabi ẹlẹsin abalaye ki wọn wọgile isin oru lasiko yii latari bi eto abo ṣe ri.
























