Qdot: Ọ̀rẹ́ mi ni Funmi Awelewa, kò sí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin wa - Fakoya Qudus Oluwadamilare

qdot

Oríṣun àwòrán, Instagram/qdot

Olorin taka sufee, Fakoya Oluwadamilare Qudus ti ọpọ mọ si Qdot ja gudugbẹ ọrọ lulẹ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba l'Ọjọru, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2020.

Qdot sọ ninu ifọrọwerọ naa pe lati ilẹ loun ti fẹran orin ijọ Kerubu, o ni iyẹn gan an lo jẹ ki oun ṣe awo orin to da bi orin ṣọọṣi ijọ C & S.

Olorin takasufee naa ṣalaye pe mama mama oun ti oun gbọdọ rẹ lo jẹ ẹleṣin kristẹni lẹyin ti mama baba oun to n tọju oun papoda.

Àkọlé fídíò, 'FUJI níkan ni ‘beat’ tó jẹ́ àṣà wa, ‘Highlife’ kìí ṣe tiwa, kò sóhun tó jọ pé àwọn ọmọ Sàtání ló ń kọ Fuji Gospel'

O ni iya baba oun ati baba oun, ẹlẹsin musulumi ni wọn.

Qdot sọ pe ẹlẹsin kristẹni ati musulumi ni oun, amọ oun faramọ ẹsin kristẹni ju musulumi lọ.

''Mo mọ nipa ilana ẹsin kristẹni ju musulumi lọ,'' Qdot lo sọ bẹẹ.

Qdot

Oríṣun àwòrán, Instagram/qdot

Nigba to n sọ nipa awọn awo to ti ṣe jade, o ni eyi ti oun pe akọle rẹ ni 'Alọmọ Mẹta' lo gbe oun jade gẹgẹ bi olorin.

''Orin yẹn ya mi lẹnu gan an, orin naa lo gbe mi lọ si ilu London to pe okiki mi kaakiri, lati ibẹ ni mo ti n ri ode 20000, 30000 gba,'' Qdot lo ṣalaye bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola
Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Qudus Fakoya ni orin yẹn yi ọpọ nkan pada ninu igbe aye oun.

''Ẹnikan ra odidi ọkọ fun mi tori orin 'Apala ti mo kọ,'' Qudus lo sọ bẹẹ.

Olorin Qdot tun tan imọlẹ si ọrọ kan tawọn kan n gbe kiri lori ayelujara pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ọrọ ifẹ wa laarin rẹ ati oṣere ori itage, Funmi Awelewa.

Qdot

Oríṣun àwòrán, Instagram/qdot

Qdot ni ''ọrẹ mi ni Funmi Awelewa, a kii ṣe afẹsọna ara wa rara.''

Bakan naa lo tun sọ pe oun o ra G Wagon fun osẹrebinrin miiran, Sotayo.

O ni ''nigba ti n ko ti ra G Wagon fun iya Kudus. Orin lasan nio.''

qdot

Oríṣun àwòrán, Instagram/qdot

Lori ọrọ igbeyawo, Qdot ni oun ko ti ṣetan bayii, amọ laipẹ lai jina oun naa yoo ṣe igbeyawo.

Qdot ṣalaye pe yatọ si pe oun gbe ọdọ awọn agba dagba, oun tun maa ka iwe Yoruba daadaa bakan naa loun tun gbe niluu Ibadan.

Ko ṣai gboṣuba fun olorin takasufee mii 9ice fun awokọṣe rere to jẹ fun oun ninu fifi ede Yoruba kọ orin takasufee.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi