Violence against women: Ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní lù mí lẹ́yìn tí mo lòdì sí ibálọ̀pọ̀ láti ihò ìdí lẹ́yìn

obinrin

Oríṣun àwòrán, others

Sabira Haliu(kii ṣe orukọ rẹ gan an gan an) to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogoji ti n gbe ile ti wọn si n kọ lọwọ pẹlu ọmọ rẹ mẹrin niluu Kaduna lẹyin sa kuro mile ọkọ rẹ.

Sabira ṣalaye pe oun fi ile ọkọ oun silẹ lẹyin ti ọkunrin naa bẹrẹ si ni lu oun lalubami nitori oun lodi si ibalopọ lati iho idi lẹyin.

''Lati ọmọ ọdun mẹẹdogun ni awọn obi mi ti sin mi lọ si ile ọkọ, o si ti pe ọdun mẹwaa ti mo ti wa nile ọkọ bayii nibi ti mo ti bimọ mẹrin,'' Sabira lo sọ bẹẹ.

Sabira sọ pe wahala bẹrẹ ni ile ọkọ oun ni bi ọdun meji sẹyin nigba ti ọkọ oun to jẹ awakọ beere fun ibalopọ iho idi lati ẹyin eyi ti oun kọ jalẹ.

Sabira ni ''lati igba naa ni o ti bẹrẹ si ni lu mi bi bara, nigba kuu gba to ba ti sọ pe ibalopọ lati iho idi ya, mo maa kọ jalẹ.''

O ni oun gbẹjọ ọkọ oun lọ si agọ ọlọpaa, awọn ọlọpaa si ranṣẹ pe ọkọ oun.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Sabira ni: ''Ṣugbọn ohun ti ọkọ mi sọ fawọn ọlọpaa ni pe oun n beere fun ibalopọ lati ẹyin nitori oun ko fẹ ki n bimọ mọ ni,'' Sabira lo sọ bẹẹ.

O ni awọn ọlọpaa bii leere pe kilode ti ko fi ṣe ifito sọmọ bibi ti ko ko ba fẹ ki oun bimọ mọ, lẹyin naa ni wọn kilọ fun un lati maa dan iru rẹ wo mọ.

Àkọlé fídíò, Se lootọ?: Wo irú sítàílì tó yẹ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìbàlópọ̀ lẹ́yìn ìbímọ- Tola Ajayi

Amọ kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii, ọkọ Sabira ko dẹkun bibeere fun ibalopọ lati iho idi, bẹẹ ni ko si dẹkun lilu iyawo rẹ.

Mo tun lọ fi ẹjọ rẹ sun awọn ọlọpaa lẹẹkeji lẹyin ti mo ri pe ọkọ mi ko ṣetan lati yipada.

''Ṣugbọn ohun tawọn ọlọpaa sọ fun mi ni pe ki n fi ọrọ naa silẹ fun Ọlọrun, lẹyin igba naa ni mo palẹ ẹru mi mọ ti mo si kuro nile ọkọ mi pẹlu awọn ọmọ mẹrin.

Obinrin to da Hijabu bori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin yii to n tọrọ owo loju popo ni Kaduna ṣalaye pe ọkọ oun ti ko kuro nibi tawọn jọ n gbe, nọmba foonu ko tiẹ lọ mọ bi oun ba pe e.

Sabira ni oun ti oun sọ fun ọkọ oun ki awọn to pinya ni pe oun yoo fẹ ọkọ mii, o si sọ pe o tẹ oun lọrun.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí