Akomolede Oyo round up: Àwọn Olúkọ ìpínlẹ̀ Oyo fakọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà púpọ̀

Eto Akomolede ati Aṣa lori BBC tun ti jo lọ si ipinlẹ Oyo.
Eto yii ni a fi n kọ awọn eniyan sii nipa ede ati aṣa Yoruba ki o ma baa parun.
- Wo awọn iroyin manigbagbe to waye ni ọsẹ yii
- Ìtàn Manigbagbe: Àwọn àjakalẹ-àrun to ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
Eto Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba jẹ eyi ti BBC n ṣe pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ onimọ Yoruba (YSAN) ati apapọ ẹgbẹ Akomolede ni Naijiria.
A ti lọ si ipinlẹ Eko Àwọn Olùkọ́ ìpínlẹ̀ Eko dárà lórí Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC nibi ti a ti kọ ẹkọ loriṣiriṣi ki a to wa si ọdọ awọn olukọ ipinlẹ Oyo yii.
Awọn olukọ to kọ wa ni ipinlẹ Oyo lọtẹ yii ni:
1) Arabinrin Olubunmi aya Femi Amao to kọ wa ni ọrọ ẹyan asapejuwe.
Aya Femi Amao n ṣiṣẹ nile ẹkọ Graceland Heights School ni Wọfun Olodo ni Iyana Church nilu Ibadan nipinlẹ Oyo.
2) Alagba Niyi Osunlolu ni olukọ miran to tun kọ wa nipa Silebu Ede Yoruba.
Ile ẹkọ The Vale College ni agbegbe Iyaganku ni Ibdan ni Alagba Niyi ti n fi ẹkọ Yoruba dara.
3) Arabinrin Funke aya Young to kọ wa ni Aṣa Yoruba,
Koko ti a gbe yẹwo ni Aṣa Iranraẹnilọwọ bii Ajọ, aaro, ọwẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ile ẹkọ Oluyole High School ni olukọ yii wa.
4) Oriṣi Igbeyawo meje to wa ni ilẹ Yoruba ni olukọ wa, Aya Adetunji fi ara balẹ kọ wa lọsẹ naa.
Igbeyawo Gbami o ra mi, igbeyawo ọkọ kaalẹ, igbeyawo Aṣante ati bẹẹ bẹẹ lọ ni a kọ ni kilaasi yii.
Ile ẹkọ Isabatudeen Girls Grammar School ni Baṣọrun ni olukọ wa ti n ṣiṣẹ bayii.
5) Agbeyẹwo iwe litireṣọ " Nitori Owo" ni a gbe yẹwo ni kilaasi yii ti Alagba Olanrewaju Akano lati ile ẹkọ Community Grammar School, Oke Ayo, Odo Ona Apata kọ wa.
Oloogbe Akinwumi Orojide Isọla lo kọ iwe litireṣọ " Nitori Owo" naa.
5) Ekun Iyawo ni aṣa Yoruba ti Alagba Tayọ Saanuade kọ wa ni kilaasi yii.
Ile ẹkọ Baptist Grammar School, Idi Ishin ni Ibadan ni olukọ yii ti n da bi ẹdun ti n wọn n rọ bi owe.
- Àlàyé rèé lóríi ìdí tí wọ́n fi ń pe aya ní ìyàwó
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Afọnja, ẹni tó finú wénú ní Ilọrin, àmọ́ tó jẹ iwọ
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin
- Ẹfunsetan Aniwura, ọmọ Ẹ̀gbá tó di akíkanjú obìnrin nílẹ̀ Ibadan
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa























