D O Fagunwa: Diipọ Fagunwa ní a le è pe bàbá òun ní ‘osó’ ìtàn àkọsílẹ̀

Bi ina ba ku, a fi eeru boju, bi ọgẹdẹ ba ku, yoo fi ọmọ rẹ rọpo, bi oloye ba ku, yoo fi oloye silẹ ni, bi eeyan ba si ku, ọmọ ẹni ni selede ni.
Ọmọ Oloogbe D.O Fagunwa, eyiun Dipo Fagunwa ti n selede lẹyin baba rẹ, to si n sọ awọn ohun meremere ti agba onkọwe naa ti gbe ile aye se lasiko to wa loke eepẹ.
Ọjọ Keje, osu Kejila, ọdun 1963 ni Daniel Ọlọrunfẹmi Fagunwa, ti gbogbo eeyan mọ si D.O Fagunwa, ẹni to jẹ ilumọọka onkọwe, silẹ bora nilu Bida nipinlẹ Niger lẹni ọgọta ọdun.
Lara awọn iwe arokọ manigbagbe ti Fagunwa kọ ni Ogboju Ọdẹ ninu igbo Irunmọlẹ eyi to gbe jade lọdun 1938 nigba ti Igbo Olodumare to tẹle jade lọdun 1949.
Bakan naa ni Adiitu Olodumare ati Ireke Onibudo jade lọdun1949 ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Orowọle Jaaniini Fagunwa ni orukọ akọni onpitan yii, amọ orukọ ti ọpọ eeyan mọ si ni Daniel Olorunfemi (D.O) Fagunwa.
Gẹgẹ bii Dipo ti se alaye, awọn ohun ti awọn eeyan ko mọ̀ nipa oloogbe naa ree:
Bi Fagunwa ba sọrọ ifẹ fun obinrin, ko si obinrin to lee kọ lati se tiẹ:
- Jaaniini dantọ ninu ọrọ sisọ, to ba si kọ ẹnu ifẹ kọ obinrin, ori obinrin naa yoo wu, ti ko si ni le e kọ jalẹ pe oun ko se, bi eyi ko ba ye yin, ẹ wa bi iya to bi mi
- Bi o ba si foju sun obinrin kan fun ifẹ, ẹ ro pe oun gan an wa pẹlu ọba Solomoni ni, lasiko to kọ awọn orin ifẹ rẹ ninu bibeli, ti Fagunwa si maa n waasu ifẹ bii ẹni pe inu aye miran lo n gbe.
- Obinrin kan to lo ẹda lẹta ifẹ ti Iyunade kọ si Ireke Onibudo, to si fi ransẹ si ololufẹ rẹ ni ọkunrin naa fi mọto ayọkẹlẹ ta lọrẹ nitori bi ori rẹ se wu to, isẹ ọwọ Jaaniini naa leyi.
- Ko tan sibẹ o, ọkunrin kan to tun lo ọrọ ifẹ ti Irinkerindo sọ fun Ifẹpataki, lọjọ idana rẹ, ni baba iyawo rẹ tun fun ni obinrin mẹta miran si i lati mu ki igbeyawo rẹ tọ suna pẹlu iyawo mẹrin ni ọọdẹ rẹ.
- Bi Fagunwa se se apejuwe ẹwa Ifẹ pataki, ko si aniani pe iru obinrin bẹẹ ko si lode aye yii, bẹẹ si ni nigba ti ọkunrin kan ka bi Ifẹpade ti ri ninu iwe Ireke Onibudo, se ni ọkunrin naa yi orukọ rẹ pada si Ireke Onibudo, ki afẹsọna rẹ le e gbagbọ pe oun naa dun ju oyin lọ.
- "To ba jẹ pe D.O Fagunwa si wa laye ni, to si ba ọkunrin naa du afẹsọna rẹ ọhun, yoo dara ki onitọhun tete fi ada le danu, ko to da isoro nla silẹ nitori ko si obinrin ti Orowọle ko le e fi gege rẹ sọ nipa ẹwa rẹ, ti onitọhun yoo si ma a ba lọ".
Awọn itan adiitu ti Fagunwa kọ yoo jẹ ki eeyan ro pe Iwin, ti eeyan n sa fun ni:
- Ọpọ awọn itan adiitu ti Orowọle kọ silẹ, lo n mu ki ọpọ eeyan maa ro pe Iwin tabi ẹmi airi kan ni, nitori se ni awọn ajẹ gan n sẹju pako-pako nigba ti Orowọle kọ itan nipa awọn ajẹ
- Koda, awọn ọdẹ gan an pe e sibi ayẹyẹ Ijala wọn fun ọsẹ meji nigba ti Fagunwa tun sọ nipa bi awọn ọdẹ se n lo egbe lati poora kuro ninu ewu, pada sile
- Tun wẹ, ọpọ awọn eeyan lo n duro si awọn opopona to da lọna oko, to si wa ninu igbo lati pade Egbere ti yoo gbe ọrọ ojiji wa fun wọn nigba ti wọn ka itan ti Jaaniini kọ lori Iwin kan to pe ni Omi-loju-Egbere, ẹni to maa n gbe ẹni kiri pẹlu omije loju, amọ̀ to le e sọ eeyan di olowo lojiji.
- Ọpọ eeyan lo tun yan ile Fagunwa lodi, ti wọn ko si debẹ wa kii mọ, nigba ti wọn ka bo se se apejuwe igbe aye awọn ara ọrun, ati ibugbe awọn eeyan mimọ, to fi mọ Esu ati oritamẹta tawọn orisa maa n gba kọja ati ile Iku, ti ọpọ eeyan si ro pe Orowọle gan an ni ọrẹ iku
- Koda, awọn mọlẹbi Jaaniini pa a ti, lai ba se pọ mọ fun ọpọ ọjọ nitori ohun to kọ nipa ọna to de ibode Arun, ti abule kan ko si na ọja fun ọpọ osu nitori eyi pẹlu
- Iyawo rẹ gan an fẹ sa kuro nile, ti mọlẹbi rẹ kankan ko si ba a sọrọ fun odidi ọdun kan nitori ohun ti Jaaniini kọ pe oun de ọrun Apaadi.
A lee pe Fagunwa ni 'Oso' nipa itan akọsilẹ:
- Fagunwa jẹ 'oso' ninu ka sọ itan ati ka kọ ọ silẹ, to si maa n kọ itan nipa irinajo sawọn ilu aimọ̀ ati airi pẹlu ọna to ya ni lẹnu
- Fagunwa nikan lo mọ ibi ta n pe ni Igbo Irunmọlẹ, Oke Langbodo to fi mọ awọn akọni meje
- Oun naa lo mọ baba Onirungbọn yẹukẹ to n gbe nibi gegele okuta, to si tun jẹ ọrẹ Akara Oogun, tii se ogboju ọdẹ ninu Igbo Irunmọlẹ
- Bakan naa ni Jaaniini se apejuwe Aramọnda ọkunrin bii ajeji ọkunrin ti otutu maa n mu lasiko ti oorun mu, ti ooru si maa n mu lasiko ti otutu ba mu gbogbo eeyan.
"Itan nipa Arọgidigba jẹ ki n ro pe baba mi n yan Yemọja ni ale ni"
- Awọn itan ti Fagunwa kọ nipa awọn orisa yoo mu kii eeyan ro pe oun gan an ni olulaja wọn ninu igbo. Ẹru yoo si ba eeyan ti a ba ka bi Orowọle ti se apejuwe ija Esu Kekere Ode ati Olowo aye, to fi mọ̀ ija Igbo Elegbeje to waye laarin awọn eeyan ati awọn Iwin, tẹ sai ro pe ẹyin gan an wa nibi ija naa, tẹ ba ka akọsilẹ rẹ
- Ọpọ si lo n kaanu nipa bi Kumọdiran se jade laye, ti Pasitọ kan si n waasu nipa ọjọ idajọ nigba to gbọ nipa bi awọn arinrinajo se n lọ si oke Ironu titi de Odo Ẹjẹ nibi ti Ayederu ti ku
- "Igbakuugba ti mo ba si ka nipa Igbagbọ Ounjẹ ni ebi maa n pa mi, ti ọpọ eeyan si n sọ ahesọ ọrọ ladugbo pe Fagunwa n ba awọn ẹmi airi sọrọ nigba ti wọn ka itan Jaaniini nipa Arọgidigba
- Koda, emi gan an sin iya mi ni gbẹrẹ ipakọ pe mo ro pe baba mi n yan Yemọja kan ni ale ninu okun, nigba ti mo ka itan Arọgidigba.
Ọpọ Itan Fagunwa lo kọ wa lati maa se aye rere:
Ọlọrunfẹmi Fagunwa maa n kọ itan bii ẹni pe o n waasu ni, awọn iwe rẹ lo kun fun ọgbọn, oye ati ẹkọ nipa bi a ti lee se aye rere.
'Fagunwa Mimọ' si lo yẹ ka maa pe nitori awọn itan ti awọn iwe rẹ kọ wa da bii ti awọn iwe mimọ mi, to si yẹ ka fi se iwe ipari awọn iwe mimọ wa fun awọn ẹlẹsin.
- Fídíò, ‘Gbèsè bí i N20million ni ìṣubú Naira kó mi sí, kódà mo ta ilé àti dúkía’Duration, 5,23
- Fídíò, 'Bíi dìndìnrìn ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Bẹ́skẹ́ tó yọ mi kúrò nínú ìyà àti àìní'Duration, 5,17
- Fídíò, Mi ò déèdé yan iṣẹ́ àgbẹ̀ lááyò, ó ní bó ṣe jẹ́ - Arabínrin K.GoldDuration, 3,29
- Fídíò, 'Mo di akọ̀wé àgbà lẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn òbí kò fi mí sílẹ̀ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí mo ní'Duration, 6,54




















