'Bíi dìndìnrìn ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Bẹ́skẹ́ tó yọ mi kúrò nínú ìyà àti àìní'

Àkọlé fídíò,
'Bíi dìndìnrìn ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Bẹ́skẹ́ tó yọ mi kúrò nínú ìyà àti àìní'
Sidikat Abdulrasaq

To ba jẹ pe Sidikat Abdulrasaq mọ pe iṣẹ wara soya dindin, ti awọn kan tun n pe Bẹskẹ, ni yoo la oun l’aye, boya ko ba ti gbe igba rẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ aye rẹ.

Eyi ni ohun ti arabinrin Abdulrasaq, ti ọpọ eeyan tun mọ si Iya Bẹskẹ ni agbegbe Osere, niluu Ilorin, sọ fun BBC.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu rẹ lo ti sọ pe aini ati

O ni gbogbo ibi ti oun ti nilo aṣiri bibo, ni iṣẹ bẹskẹ ti n bo aṣiri oun.

Arabinrin Abdurasaq ti n ṣiṣẹ bẹskẹ tita fun bi ọdun marun-un, ninu eyi to sọ pe oun ti jẹ ere to pọ.

Ki lo gbe e de idi iṣẹ yii?

Iya Beske ṣalaye pe aini ati aitoṣẹku, lo gbe oun de idi iṣẹ naa.

Lọjọ ti yoo bẹrẹ iṣẹ aṣela yii, ọmọ rẹ kan ni wọn le wa sile lati ile ẹkọ, nitori airo san.

O ni ko si ọna abayọ fun oun lati san owo ile ẹkọ ọmọ naa.

O ni ko si ọna abayọ fun oun lati san owo ile ẹkọ ọmọ naa.

Iṣẹlẹ naa mu ki Sidikat ronu kan bẹskẹ to ma n ri ti ẹnikan n ṣe nigba to wa ni ọmọde, ni agboole wọn.

Nigba naa, bi ere, bi awada lo jọ loju rẹ, paapaa bi ẹni naa ṣe ma n ran an niṣẹ lati ba a ṣe awọn nkankan lasiko to ba n ṣe bẹskẹ.

“Mo pinnu lati ma a ṣe. Bii dindinrin ni mo kọkọ ṣe alakọkọ, ṣugbọn mo ṣe e daadaa.”

O ni lootọ ni oun ko ri owo kankan kojọ bi ere, yatọ si aadọrun Naira to fi ra ẹwa soya.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe itọwo ni gbogbo ara adugbo fi ṣe.

Aadọrun Naira ọhun lo tun fi ṣe bẹskẹ miran. Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹta, owo naa ti di aadọjọ Naira lọwọ rẹ.

Ko pẹ si asiko naa lo di pe o n ṣe wara bẹskẹ pẹlu ilaji garawa ẹwa soya.

O di pe o tun gba oṣiṣẹ mọra.

Ni bayii, oṣiṣẹ bii mẹtala lo n ba Arabinrin Sidikat Abdulrasaq ṣiṣẹ bẹskẹ ṣiṣe, to si n san ẹgbẹẹgbẹrun owo fun wọn ni oṣooṣu.

O ni igbesẹ ti oun n gbe bayii ni pe oun ma n gba awọn obinrin ti oun ba mọ pe o ni okun, lati ma a ṣe iṣẹ bẹskẹ.

Igbesẹ rẹ yii ti yọ ọpọlọpọ obinrin kuro ninu airijẹ ati airowo na.

Bakan naa lo ni oun ti fi iṣẹ bẹskẹ ṣiṣe le gbogbo awọn ọmọ iya oun lọwọ, ti oun si n gbadura pe ki awọn ọmọ oun naa ṣe e.

Yatọ si eyi, o ni owo oṣu ti oun n gba nidi iṣẹ bẹskẹ ṣiṣe, ju ti oṣiṣẹ ijọba mii lọ.