Mi ò déèdé yan iṣẹ́ àgbẹ̀ lááyò, ó ní bó ṣe jẹ́ - Arabínrin K.Gold

Yoruba sọ pe, ori lo mọ iṣẹ aṣela. Gbogbo iṣẹ ti ẹda ba si ti n ṣe, adura ni pe ko jẹ aṣela.
Arabinrin Isah Ramat Kikelomo, ti ọpọ mọ si K. Gold niluu Ilorin, nipinlẹ Kwara, sọ pe ẹkọ nipa amojuto okoowo ni oun kọ nile ẹkọ giga, amọ iṣẹ agbẹ lo n ṣe.
Arabinrin naa nigba to n ba BBC sọrọ ṣalaye pe oun ko deede di agbẹ ọlọsin ẹja, adiyẹ ati irugbin.
O ni iṣẹ agbẹ ni baba oun ṣe, oun nikan si ni ọmọ baba naa to mu iṣẹ agbẹ naa ni ọkunkundun.
O to ọdun mẹtala ti Arabinrin K.Gold ti n ṣe iṣẹ agbẹ.
Nnkan to si mu ko yatọ si awọn agbẹ ọlọsin ẹja bii tiẹ ni pe, itansan oorun, ti wọn n pe ni Solar, lo fi n ṣe iṣẹ rẹ.
Arabinrin K. Gold ṣalaye pe ọwọn gogo epo bẹtiro ati gaasi, lo mu ki oun ronu kan lilo solar lati ma a fi ṣe iṣẹ.
“Lootọ ni owo ti mo na sori solar naa pọ, amọ ere to n mu wa fun mi jẹ ilọpo meji iye ti mo n ri nigba ti mo n lo ina ijọba.”
Lara ipenija to tun ma n ri ni pe gbogbo igba kọ ni awọn onibaara ma n ra ẹja, eyi to ma n mu ki wọn o na owo ti ko yẹ lati fi bọ awọn ẹja naa titi di ọjọ ti obibaara ba wa.
Ko ṣai gba awọn obinrin bi tiẹ, to le ni erongba lati ṣe ọsin ẹja, pe wọn gbọdọ lew ni suuru, nitori kii ṣe iṣẹ to ma n fun ni ni owo kiakia.
Bakan naa lo ni o jẹ iṣẹ to gba amojuto pupọ, eyi to tumọ si pe lilọ si ode ariya ni gbogbo igba ko le ṣe





