Wo ohun tó mú ayẹyẹ ‘Palm Sunday’ ní Ilorin yàtọ̀ sí ti àgbàyé yòókù

Awọn oluwọde

Oni ni ayajọ ‘Palm Sunday’ eyi ti awọn Yoruba maa n pe ni imọ ọpẹ.

Ayajọ yii jẹ ọjọ ti awọn ọmọ lẹyin Kristi fi maa n ṣe ami bi Jesu Kristi ṣe gungun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalem nigba aye rẹ.

Lasiko igba naa , gẹgẹ bi iwe mimọ Bibeli ṣe fi ye ni, niṣe ni awọn eeyan fi ijo ati ayọ pade rẹ pẹlu imọ ọpẹ lọwọ.

Lati ara imọ ọpẹ yii naa ni ayẹyẹ naa si ti gba orukọ.

Ti ayẹyẹ ọdun ajinde ba ku ọsẹ kan ni ayẹyẹ yii maa n waye ni ọjọ Aiku to ba ṣaaju ọdun ajinde.

Kaakiri agbaye si ni wọn ti maa n ṣe ayẹyẹ yii to si maa n waye nigba ti awẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ba ku ọsẹ kan to maa pari.

Lasiko ayẹyẹ yii ni awọn ọmọlẹyin Kristi maa n fi imọ ọpẹ dara oriṣiriṣi to ba wu wọn. Awọn mii maa n fi ṣami agbelebu eyi to tumọ si bi wọn ṣe kan Jesu mọ agbelebu.

Awọn oluwọde

Awọn mii maa n lo o lati fi ṣe ẹgba ọrun, awọn mii maa n so mọ ọwọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọlọtọ ni toun ọtọ ni bi awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe maa n ṣayẹyẹ ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.

Niṣe ni awọn ọmọlẹyin Kristi ni ilu Ilorin maa n ko ara wọn jọ lati ṣe iwọde kaakiri awọn agbegbe kọọkan lati ṣami ayajọ yii.

Gbogbo awọn ọmọlẹyin Kristi ni ilu Ilorin lai fi ti ijọ tabi ile ijọsin ti wọn n lọ ṣe ni wọn maa n fi orin ati ilu ṣe iwọde.

Bakan naa ni wọn tun ṣe ni ọdun yii nigba ti wọn fijo ati ayọ yide lati ṣayẹyẹ ọdun imọn ọpẹ .

Eto iwọde naa lo bẹrẹ ni ile ijọsin St Barnabas to wa ni agbegbe Sabo oke, Ilorin nibi ti wọn kora jọpọ si lati nnkan bii ago meje owurọ.

Iwọde naa to bẹrẹ lati Sabo Oke lọ Aminlẹgbẹ, Opomalu, Taiwo Isalẹ, Chalenge, post-office ti wọn si pari si Sabo Oke ti wọn ti bẹrẹ rẹ.

Lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ, igbakeji alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi (CAN), tẹka ipinlẹ Kwara, Pastor Moses Ademola Popoola ṣalaye pe pataki ayajọ imọn ọpẹ ni lati ṣami bi Jesu Kristi ṣe gun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalẹmu.

Awọn oluwọde
Ọkọ ti imọ ọpẹ wa ninu rẹ

O rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati ni ẹmi irẹlẹ bi ti Jesu Kristi ki wọn si maa jẹ ki ipa rẹ lapa ninu igbe aye wọn.

O ṣalaye pe pataki iwọde naa ni lati mu ki iṣọkan wa laaarin awọn ọmọlẹyin Kristi ipinlẹ Kwara, ati lati fi gbadura si Ọlọrun lori eto ọrọ aje ilẹ Naijiria.

O ni eto iwọde naa maa n waye lati so gbogbo onigbagbọ ipinlẹ Kwara papọ lai fi ti ìjọ tabi ẹya ti wọn jẹ ṣe.

Ninu ọrọ rẹ sawọn oluwọde naa, akọwe ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ipinlẹ Kwara, Sina Ibiyemi ke si wọn lati maa gbadura fun ilẹ Naijiria ki Ọlọhun dasi ọrọ eto abo ati tọrọ aje to dẹnu kọlẹ ni Naijiria.

Awọn oluwọde naa ko naa ni oorun to mu, wọn kọrin, wọn jo, wọn sin yin Ọlọrun logo to da wọn si lati ri ọdun imọn ọpẹ tọdun yii.

Ọpọ awọn eekan ilu ati awọn ojiṣẹ Ọlọrun lọkan-o-jọkan lo peju si ibi eto iwọde naa.

Eto iwọde naa ni ikọ eleto abo mojuto lati ri pe ohun gbogbo lọ ni alafia.