Ìjọba Kaduna fa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kuriga lé àwọn òbí wọn lọ́wọ́

Awọn akẹkọọ naa pẹlu awọn obi wọn

Oríṣun àwòrán, Kaduna state government

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede sita pe awọn ti fa awọn akẹkọọ Kuriga to gba ominira wọn lọwọ awọn ajinigbe le awọn obi wọn lọwọ lẹyin itọju.

Ijọba kede eyi ninu atẹjade kan ti Gomina Uba Sani buwọlu pẹlu alaye pe, ijọba ni lati ṣe ayẹwo to peye fun awọn akẹkọọ naa ki wọn to le fa wọn le awọn obi wọn lọwọ, ti wọn yoo si tun ri daju pe awọn akẹkọọ naa pada si ile ẹkọ wọn.

Gomina Sani salaye pe ọpọ awọn akẹkọọ lo ti da oun mọ, ti wọn si mu oun gẹgẹ bii Baba.

O ni wọn ti ṣe ileri pe ohun to waye yii ko ṣe okunfa idaduro fun wọn ni ile ẹkọ.

“Ajọ to n pese iranlọwọ Uba Sani yoo tẹsiwaju lati ma ṣe agbatẹru ile ẹkọ awọn akẹkọọ, titi wọn yoo fi pari ile ẹkọ girama,” atẹjade naa kede.

Atẹjade naa fikun pe ijọba ipinlẹ Kaduna yoo fun idilẹ mọlẹbi olukọ awọn akẹkọọ naa to padanu ẹmi rẹ ni akata awọn ajinigbe ni milọnu mẹwaa naira.

Bakan naa ni ijọba tun ṣe ileri pe awọn yoo ṣe atunṣe ile ẹkọ Kuriga, ti wọn yoo si se ferese yika ile ẹkọ naa lati pe abo fun awọn akẹkọọ.

Bẹẹ ba gba awọn akẹkọọ lawọn agbebọn ti ji gbe niluu Kuriga, agbegbe Chikun, to wa ni ipinlẹ Kaduna.

Isẹlẹ naa lo waye lowurọ Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2024, lasiko ti awọn akẹkọọ naa pejọ ni ago mẹjọ abọ owurọ fun adura, ki awọn agbebọn ọhun to yabo ile ẹkọ naa lori alupupu, ti wọn si ji wọn gbe.

A gbọ pe ọjọ ori awọn akẹkọọ ọhun ko ju ọdun mẹjọ si marundinlogun lọ.

Awọn akẹkọọ naa, pẹlu awọn olukọ wọn ni awọn agbebọn ọhun ji gbe.

Iroyin ijinigbe ni iha Ariwa Naijiria kii ṣe iroyin tuntun amọ ijinigbe ọlọgọọrọ eeyan ti din ku laarin ọdun diẹ sẹyin titi di ọsẹ to kọja.

A pàdánù olùkọ́ tí wọ́n jí gbé pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kuriga - Gómìnà Sani

Gomina ipinlẹ Kaduna, Sen Uba Sani ti sọ pe inu awọn dun pe awọn ri awọn akẹkọọ Kuriga gba pada lọwọ awọn ajinigbe sugbọn o ṣe ni laanu pe olukọ ti wọn ji gbe pẹlu wọn padanu ẹmi rẹ.

Gomina Sani salaye pe olukọ naa bẹrẹ aisan lasiko to wa ninu igbekun awọn ajinigbe naa.

O ni oun ba awọn mọlẹbi oloogbe kẹdun lori isẹlẹ naa.

“Ẹni kan pere ni ko ba awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe pada, oun si ni olukọ wọn.

'Gumi ko mọ ohunkohun nipa itusilẹ awọn akẹkọọ Kuriga'

Gomina Sani tun fidi rẹ mulẹ pe Agba Alfa to fi ipinlẹ Kaduna ṣe ibugbe, Sheikh Ahmad Gumi ko lọwọ ninu bi awọn akẹkọọ Kuriga ṣe gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Sani salaye pe otitọ ni pe Gumi kan si ijọba pe ki wọn jẹ ki oun ba awọn ajinigbe naa sọrọ.

“Gbogbo awọn nnkan ti ẹ n gbọ lo jẹ irọ. Mo n sọ yi fun yin lai bẹru. Ko si nnkan to jọmọ pe Gumi mọ nipa bi awọn akẹkọọ ṣe gba itusilẹ.”

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kuriga tí agbébọn jí gbé nípìnlẹ̀ Kaduna ti gba òmìnira

Awọn akẹkọọ Kuriga

Oríṣun àwòrán, Reuters

Gomina Ipinlẹ Kaduna, Sen Uba Sani ti kéde pe awọn akẹkọọ ile ẹkọ ti Kuriga ti gba òmìnira lọwọ awọn ajinigbe.

Ọsẹ diẹ sẹyin ni wọn ji awọn akekọọ naa to le ni igba gbe, nile ẹkọ wọn.

Alẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta, ni Gomina Sani fìdí iroyin naa mulẹ fun awọn akorọyin.

"Ni orúkọ Ọlọrun Allah, mo ni ayọ lati kede pe awọn akẹkọọ Kuriga ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

"Idupẹ pataki sì Aarẹ Bola Ahmed Tinubu fun bi o ṣe jẹ ki eyi wa si imusẹ, ati pe alaafia ni awọn akẹkọọ naa pada sọdọ mọlẹbi wọn.

"Nigba ti awọn akẹkọọ naa wa ni ahamọ, mo ba Aarẹ sọrọ ni ọpọ igba. O ba wa kẹdun, o si se ileri pe ijọba yoo ri pe awọn akẹkọọ naa pada ni alaafia.

Ọjọ keje oṣu kẹta 2024 yii ni wọn ji awọn akẹkọọ ati awọn oṣiṣẹ ileewe LEA Primary School ati Government Secondary School, Kuriga, ni Kaduna, gbe. Lati ọjọ naa ni wọn si ti n ka gbedeke ti wọn fun wọn lati sanwo itusilẹ yii.

Ṣaaju ni awọn ajinigbe ti wọn ji akẹkọọ 287 ati awọn olukọ naa gbe ni Kaduna beere fun biliọnu kan naira owo itusilẹ ki wọn too le yọnda wọn.

Wọn ni bi owo naa ko ba tẹ wọn lọwọ laarin asiko yii sí ọjọ kẹrìndinlọgbọn, oṣu kẹta ọdun 2024, awọn ajinigbe naa ni awọn yoo pa awọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ̀ọ́ to wa nigbekun wọ́n danu ni.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe gbe e jade, Jubril Aminu to n ṣoju awọn ti wọn ji eeyan wọn gbe ni awọn ajinigbe naa pe lorii foonu.