"Ọgbọ́n tí mo fi móríbọ́ rèé láàrin akẹ́kọ̀ọ́ 280 táwọn agbébọn jí gbé"

Aworan okunrin to ko eyin kamera
Àkọlé àwòrán, Musa Garba wa lara akekoo 280 ti wọn jigbe ni ile ẹkọ girama to wa niluu Kuriga nipinlẹ Kaduna lọsẹ to lọ.
    • Author, Chris Ewokor
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Kuriga

Musa Garba to jẹ akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtadinlogun ti ṣalaye fun BBC bi ori ṣe ko o yọ lọwọ awọn ajinigbe to ji oun ati awọn akẹgbẹ rẹ lọ nile ẹkọ wọn ni apa ariwa orilẹede Naijiria.

Garba ni oun ni lati lẹ mọlẹ bi ejo ninu igbo ni oun fi ri aye bọ mawọn ajinigbe naa lọwọ.

O ni oun ni lati bọ si abẹ koriko kan ti wọn kojọ nigba t'awọn akẹgbẹ oun n sinmi lẹyin ti wọn ti rin fun igba diẹ.

Awọn akẹkọọ to le ni 280 ni wọn jigbe ni ile ẹkọ to wa niluu Kuriga nipinlẹ Kaduna lọsẹ to lọ.

"A n wo awọn ajinigbe bi wọn ti n ji awọn ọmọ wa gbe lọ, ti a ko si le ṣe nnkan kan si"

"Ṣadeedee ni a ri wọn lori ọkada, a tiẹ kọkọ ro pe sọja ni wọn ni.

Ki a to wi ki a to fọ, wọn ti bẹrẹ si ni yinbọn, wọn si ti yi ile ẹkọ wa ka," Musa ti a lo orukọ mii fun nitori aabo rẹ, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC.

Musa ni "a gbiyanju lati sa lọ, ṣugbọn wọn le wa mu, wọn si ko wa lọ sinu igbo bi ẹran maalu."

Awọn agbebọn ti n maa n yabo ilu Kuriga tẹlẹ lati ji awọn eeyan gbe gba owo.

Amọ, bi wọn ṣe ji awọn ọmọde akẹkọọ lasiko yii jẹ ohun to ya ọpọ eeyan lẹnu.

Arabinrin Hajiya Hauwa sọrọ pẹlu omije loju pe "a n wo wọn bi wọn ti n ji awọn ọmọ wa gbe lọ ti a ko si le ṣe nnkan kan.

A o ni awọn ologun tabi ọlọpaa to le gbija wa niluu yii."

Yara ikawe nile eko Kuriga

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ile eko Kuriga di korofo

"Ọpọ wa lo n subu lulẹ ninu oorun bi ajinigbe se ko wa rin ọpọ Maili , ti oungbẹ n gbẹ wa lai ri omi mu"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Musa jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ ti wọn jigbe lọ.

"Bi a ṣe n rin lọ ninu igbo, ongbẹ bẹrẹ si ni gbẹ wa, amọ, ko si omi ti a le mu.

Bayii ni awọn kan lara wa bẹrẹ si ni ṣubu tori o ti rẹ gbogbo wa.

Awọn ajinigbe ni lati gbe awọn kan ninu wa sori ọkada," Musa ṣalaye.

Awọn akẹkọọ yii pada ri omi mu nigba ti wọn rin debi odo kan ninu igbo lẹyin ti wọn ti rin lati aarọ ninu oorun lai tii jẹ ounjẹ aarọ.

Musa bẹrẹ sí ni wa ọna ti yoo gba sa lọ mọ awọn ajinigbe lọwọ bi wọn ti n rin lọ ninu igbo.

O gba awọn akẹgbẹ rẹ mii naa niyanju lati ṣe bẹẹ, amọ, ẹru n ba wọn.

Nigba ti oorun n wọ ni Musa wo ọtun, ti o wo osi, ti o si ri pe ko si ẹni to n wo oun.

Bayii ni Musa ko sabẹ koriko kan ti wọn kojọ silẹ.

Musa ni "lẹyin ti gbogbo agbegbe ti dakẹ tan ni mo bẹrẹ si ni ra nilẹ bi ejo."

Nigba ti ilẹ ṣu ni Musa dide ti o si bẹrẹ si ni rin lọ titi ti o fi rin de ilu kan ti wọn ti ran an lọwọ.

Musa gbe igbesẹ to le ṣokunfa iku rẹ t'awọn ajinigbe ba ri i.

Amọ, ọpọ lo n sọ pe Eleduwa lo ko o yọ.

Awọn obi rẹ fo fun ayọ nigba ti wọn ri i lọjọ keji.

Ṣugbọn o mu iroyin ibanujẹ bọ fawọn araalu pe awọn akẹgbẹ oun wa lakata awọn ajinigbe.

Awọn obi Sadiq Usman Abdullahi sí n reti ọmọkunrin wọn.

Igba to kẹyin t'awọn obi rẹ ri i ni aarọ Ọjọbọ nigba to wa ile pe, oun gbagbe gege ikọwe oun ṣaaju akoko tawon ajinigbe ya wọ ilu wọn.

Aworan owo obinrin
Àkọlé àwòrán, Arabinrin Rahmatu Usman Abdullahi ti ọmọkunrin rẹ wa lara awọn ti wọn jigbe ni oun ko tii le sun lati ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

"N ko le sun ni gbogbo igba ti mo ba ti ranti ọmọ mi to wa ni akata awọn ajinigbe"

Arabinrin Rahmatu Usman Abdullahi ti ọmọkunrin rẹ wa lara awọn ti wọn jigbe ni oun ko tii le sun lati ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

"Ni gbogbo igba ti mo ba ti ranti rẹ, mi o le sun.

Ba wo ni mo ṣe fẹ sun?

Ki Ọlọrun ran wa lọwọ ni," Rahmatu lo sọ bẹẹ.

Amọ, Musa ati Sadiq jẹ meji lara awọn ẹgbẹrun mẹrin eeyan t'awọn ajinigbe ti gbe lọ ni Naijiria ni bii oṣu mẹjọ sẹyin, gẹgẹ bi akọsilẹ kan ṣe sọ.

Awọn agbebọn ajinigbe ti n ṣọṣẹ lapa ariwa Naijiria fun bi ọdun mẹẹdogun sẹyin bayii.

Awọn ipinlẹ Borno, Adamawa ati Yobe ni ọpọ ikọlu yii ti waye julọ, lagbegbe ti ẹgbẹ Boko Haram to lodi si lilọ ile ẹkọ ti n ṣọṣẹ.

Ẹgbẹ agbesunmomi alakatakiti ẹsin musulumi ni ẹgbẹ keji to ti n ṣọṣẹ fun ọpọ ọdun bayii.

Ile ẹkọ ni wọn n doju kọ, tori awọn oyinbo lo mu un wa.

Ijinigbe awọn akẹkọọ ni Chibok ni ọdun mẹwàá sẹyin ni wọn fi bẹrẹ.

Ni ọpọ igba, ti wọn ba ti ji awọn eeyan gbe ti wọn si gba owo, wọn maa n saba fi owo naa ra ohun ija oloro ti wọn n lo ni.

Ọpọ awọn ọdaran mii lẹkun ariwa Naijiria ni wọn ti n lo ọgbọn yii kan naa lati ji awọn akẹkọọ gbe tori ìyẹn lo maa n jẹ ki ọpọ eeyan sọrọ.

Sẹnẹtọ Shehu Sanni sọ pe owo itusilẹ ti wọn n gba ti wọn ba ti ji eeyan gbe lo jẹ ki ijinigbe maa pọ si.

O ni ko si nnkan mii ti wọn fi n ji eeyan gbe ju owo to wa nibẹ lọ.

Oloye Jibril Gwadabe
Àkọlé àwòrán, Jubril Gwadabe to jẹ oloye niluu kan sọ pe loorekoore l'awọn agbebọn maa n ya wọ ilu awọn tori ko si ẹṣọ eleto abo.

"Mo wọ iya ija pẹlu awọn ajinigbe, wọn yinbọn fun mi ni ikun, ọta ibọn jade lẹyin mi"

Ijọba ti gbiyanju láti dẹkun iwa ọdaran yii, amọ, ọpọ ilu si ni eto abo ti mẹhẹ titi di akoko yii.

Ilu Kuriga jẹ ọkan lara iru awọn ilu yii.

Jubril Gwadabe to jẹ oloye niluu Kuriga sọ pe loorekoore l'awọn agbebọn maa n ya wọ ilu awọn tori ko si awon ẹṣọ eleto abo.

'O ti ṣẹlẹ si emi fun ra mi ri.

Mo n lọ si oko ni bii ọdun meji sẹyin nigba ti wọn da mi duro.

Mo bẹrẹ si ni wọ iya ija pẹlu wọn.

Bayii ni wọn ṣe yinbọn fun mi ni ikun ti ọta ibọn si jade lẹyin mi.

Oṣu kan ni mo lo ni ile iwosan, amọ, mi o ku," Oloye ẹni ọdun mẹrinlelọgọta lo sọ bẹẹ.

Ijọba ti ṣeleri lati doola awọn akẹkọọ ti wọn jigbe yii, amọ, awọn eeyan ilu Kuriga ṣi n kọminu.

Oloye Gwadabe ni "a o mọ ipo t'awọn ọmọ wa wa bayii, a o si mọ ibi ti wọn wa."