"Mo ti ya Tinubu, Dapo Abiodun, mo sì fẹ́ ya èèyàn 1000 si ní àgbáyé"
Ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samusamu ni ọrọ ọmọdekunrin, Morenikeji Ebunoluwa Joshua.
Ọmọ ọdun mẹsan ni ọmọdekunrin yii amọ ẹbu ti Ọba Oke fi fun, agbalagba miran ko ni iru rẹ rara.
Idi ni pe lati ọmọ ọdun mẹrin ni Ebunoluwa ti n dabira nidi aworan yiya pẹlu Pẹ́ńsù lasan, eyi to n se ọpọ eeyan ni haa-hii.
Ọmọdekunrin naa, tii se akẹkọọ to wa ni kilaasi kẹrin nile ẹkọ alakọbẹrẹ ba BBC Yoruba sọrọ nipa bo ti n se amulo ẹbun naa.
Bakan naa ni awọn obi rẹ sọrọ lori bi inu wọn se dun to lati ri pe ẹbu nla yii jẹyọ lara ọmọ wọn.

"Ko si ẹni to kọ mi ni aworan yiya, ẹbun oluwa ni gẹgẹbii orukọ mi"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ebunoluwa Morenikeji salaye pe oun ti fi Pẹnsu ya aworan aarẹ orilẹede yii, Bola Ahmed Tinubu ati ti gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun.
Bakan naa lo ni oun tun ti ya aworan Igbakeji gomina, Naimot Salako ati ti Alagba Femi Aderibigbe, ti oun si ti lọ gbe fun wọn ni ọọfisi wọn.
“Ọmọ ọdun mẹrin pere ni mo wa, ti mo ti n fi Pẹnsu ya aworan, ti mo si ti ya aworan ọpọlọpọ awọn eeyan pataki lawujọ.
Ko si ẹni to kọ mi ni aworan yiya, ẹbun oluwa ni gẹgẹbii orukọ mi.
Erongba mi nile aye ni pe ki n le ya eeyan pataki to le ni ẹgbẹrun kan, ti wọn ti sisẹ takuntakun ni awọn agbegbe ti wọn wa.
Mo si fẹ ki wọn maa fun mi ni owo lati mọ riri mi, ti mo ba ti lọ gbe awọn aworan naa fun wọn.
Bakan naa ni mo fẹ ki awọn eeyan maa pe mi kaakiri agbaye lati ya aworan, ki n si ni Gallery temi, ti ọpọlọpọ aworan yoo wa.”

“Olongbo mi ti da ọpọ aworan ti mo ya nu, ko si ibi ti maa ko aworan mi si mọ”
Ebunoluwa Morenikeji wa n fi ika hanu pe ọpọ aworan ti oun ti ya sẹyin ni oun ko ri ibi ti oun yoo ko wọn si.
O ni idi ni pe olongbo oun ti da awọn aworan naa nu, ti oun si n wa ibi ti oun le ko awọn aworan ọhun si.
“Mo fẹ di ilumọọka ayaworan, ti gbogbo aye yoo mọ, amọ n ko ribi ko awọn aworan mi si.
Mo si fẹ ki gbogbo agbaye mọ mi bii ọmọde to n fi Pẹnsu dabira.”

Inu mi dun gan bi gomina Dapo Abiodun se ransẹ pe ọmọ mi tori aworan rẹ to ya – Bosun Morenikeji
Baba to bi Ebunoluwa, alagba Bosun Morenikeji naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa iha to kọ si ẹbun amutọrunwa ọmọdekunrin yii.
Alagba Morenikeji ni inu oun dun de ẹyin, bi eeyan ba si gun ẹsin ninu oun, ko le kọsẹ nitori ẹbun ti Ọlọrun fi jinki Ebunoluwa.
“Inu mi dun lọjọ ti Gomina Dapo Abiodun ni ki ọmọ mi gbe aworan rẹ wa.
O ku diẹ, ki Ebunoluwa pe ọmọ ọdun mẹrin lo ti n se afihan ẹbun aworan yiya.
O maa n fi ike to nnkan papọ, tabi ko lo igbalẹ to nnkan.
Bakan naa lo ya ẹnikan to gun kẹkẹ eyi to fi han pe o ni ẹbun yii.”







