Nítorí mi ò fẹ́ kí àwọn ọmọ òrukàn ya ìpátá sílùú ni mo ṣe ń fi ijó kó wọn jọ
Arabinrin Seyi Oluyole ni bi iwa ipata se wọpọ lawujọ ati bi oun si nifẹ si ti tọju ọmọde lo jẹ ki oun kọwe fipo silẹ nibi isẹ kan to n se tẹlẹ lati gba jumọ titi tọju awọn ọmọ alaniya ati baba, ti oun si n fi iji ko n wọn jọ
Saaju ni okiki awọn ọmọ kan lori ayelujare, ti ọpọ si fẹran wọn bi wọn n se fi ijo jijo dabira lori ayelujara fun awọn ololufẹ wọn
Ileeṣẹ BBC News Yoruba sabẹwo si Oludari Ileeṣẹ Dream Catcher Academy lati mọ idi to fi yan fifi ijo jijo laayo lati fi ko awọn ọmọdebinrin ti wọn ko ni Iya tabi Baba mọ.
Ninu alaye rẹ, Oluyole ni lati kekere ni oun ti fẹrẹ lati ma ko awọn ọmọde jọ, ti ọpọ si ma n pe oun ni Seyi Ọlọmọwẹwẹ.
O ni ibanujẹ lo ma jẹ fun oun ti oun ba ri awọn ọmọde loju popo ti wọn n fi ẹsẹ rin kiri ilu.
"Lati bi ọmọ ọdun mẹrinla ni mo ti bẹrẹ si ni ma kọ awọn ọmọde ni ijo ni sọọsi tu mo n lọ ni igba naa.
"Nitori sọọsi ti a n lọ lasiko naa dabi 'Slum', awọn ọmọ ti wọn ko ni nnkankan lo wa nibẹ ti mo si maa n kọ awọn ọmọ yii ni ijo.
"Nigba yẹn, ti wọn ba fun mi ni owo ounjẹ lọ ile ẹkọ, mo ma fi n ra nnkan fun awọn ọmọde ni."
"Bi mo se ma ri awọn ọmọ ti mo n koju"
Oluyole tẹsiwaju pupọ awọn ọmọde ti oun n kojọ ni o jẹ pe oun ni oun maa ri wọn tabi ki awọn ọmọ, fun arawọn ri oun ki wọn si wa ba oun.
O ni oun gbagbọ pe ọmọ ti oun ba ri loju titi lasiko to yẹ ko wa ni ile ẹkọ, nilo itọju.
"Ti mo ba ri awọn ọmọ yii, mo duro maa duro lati bere idi ti irufẹ ọmọ naa fi wa loju titi.
"Igba mii, o maa n di ija, ti awọn eeyan ma ro pe ijọba ni mi, pe ko fẹ ko ọmọ.
"Awọn mii si wa to jẹ pe ti mo ba ti ri ọmọ yii, mo ba awọn eeyan to wa layika sọrọ pe ki lo de, wọn dẹ ma salaye pe ọmọ naa nilo iranlọwọ, boya ko ni Baba tabi Mama mọ."
Ọpọ igba ni o maa sumi sugbọn nibo ni mo fẹ fi awọn ọmọ yii si
Seyi Oluyole ni ọpọ igba ni oun ti pinnu pe oun ko nifẹ lati se itọju awọn ọmọ yii mọ sugnọn ti oun ba tun ti ro pe nibo ni oun fẹ ko awọn naa si, oun ma n yii pinnu oun pada, ti oun yoo si tun duro ti awọn ọmọ naa.
"Kii se ọjọ kan tabi meji ti mo ti ni n ko se mọ, pe iru wahala wo mo ko ara mi si bayii.
"Sugbọn ti mo ba tun ro ti awọn ọmọ yii pe nibo ni mo fẹ da wọn si ati pe emi gan ni nnkan ti mo si nifẹ si to si jẹ awọn ọmọ yii.